settings icon
share icon
Ibeere

Ti iwo ba ti ni igbala, nje igbala ayeraye ni?

Idahun


Nje ti enia ba ti ni igbala, se ayeraye ni? Nigbati awon enia b amo Kristi gege bi olugbala won, won yio si wa pelu ibatan pelu Olorun ti o si fun won ni ireti nipa igbala won. Ori iwe Mimo orisirisi ni o so fun wa nipa eyi. (a) Romu 8:30 wipe, “Awon ti o si ti yan awon li o si ti pe: awon eniti o si ti pe, awon li o si ti dalare: awon eniti o si ti dalare, awon li o si ti se logo.” Eyi so fun wa wipe nigbati Olorun yan wa, o si da bi eni wipe a gbe gan ninu orun. Ko si si ohun kan ti yio di wa lowo ni ojo kan lati ma gbe ga nitori Olorunsi ti so lati orun wa. Igba ti enia ba si ti di olododo, igbala re si ti wa- ko si ni dababo nitoripe o da bi pe won ti gbe ga ni orun.

(b) Paulu bere ibere meji ni Romu 8:33-34 “Tani yio ha ka ohunkohun si orun awon ayanfe Olorun? Ihase Olorun ti ndare. Tani eniti ndebi? Ihase Kristi Jesu ti o ku, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu oku, eniti o si wa li owo otun Olorun, ti o si mbebe fun wa? Ko si eniti yio se, nitoripe Kristi, eni ti o ku fun wa, ohun naa yio da wa lebi. A ni alagbawi ati onidajo gege bi olugbala wa.

(c) Awon ti o gbagbo je atunbi (irapada) nigbati a gbagbo (Johannu 3:3; Titu 3:5). Fun Kristiani lati padanu igbala, o ni lati je laitunbi. Bibeli ko so fun wa wipe won le mu atunbi kuro ni ile aye wa. (d) Emi Mimo ni o n dari gbogbo wa (Johannu 14:17; Romu 8:9) yio si se iribomi si inu ara Kristi (1 Korinti 12:13). Ki omo leyin Kristi le ma ni igbala, o ni lati kuro ninu ara Kristi.

(e) Johannu 3:15 wipe eni ti o ba gbagbo ninu Jesu Kristi “yio ni igbala ayeraye.” Ti iwo ba gbagbo ninu Kristi ni oni ti o si ni igbala ayeraye, sugbon o padanu re ni ola, nigbanaa eyi ki se “ayeraye” rara. Ti iwo ba si ti so igbala re un, ireti ninu Bibeli nipa igbala ayeraye yio si je isina. (f) ki aba le ni ipari lori oro yi, iwe Mimo so daradara nipa re, “ Nitoripe o da mi loju pe, ki se iku, tabi iye, tabi awon angeli, tabi awon ijoye, tabi awon alagbara, tabi ohun igba isisiyi, tabi ohun igba ti mbo, tabi oke, tabi ogbun, tabi eda miran kan ni yio le ya wa kuro ninu ife Olorun, ti o wa ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 8: 38-39).” Ranti Olorun kan naa ti o gba o la naa ni Olorun ti yio toju re. Ti aba si ti ni igbala, igbala ayeraye ni. Igbala wa naa si ni ti ni idaniloju titi ayeraye.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ti iwo ba ti ni igbala, nje igbala ayeraye ni?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries