settings icon
share icon
Ibeere

Kini igbala ona awon ara Romu?

Idahun


Igbala ona awon ara Romu je gege bi ikede iroyin ayo igbala lati inu bibeli ninu Romu. Eyi je ona soki ti o si lagbara lati le fi han, idi ti igbala fi se pataki, eyi ti Oluwa fi pese igbala, bi awa se le ni igbala, ati kini ere igbala.

Ese kini igbala ona awon ara romu fun igbala wa ni Romu 3; 23. “Gbogbo enia li o sa ti se, tinwon si kuna ogo Olorun. “Gbogbo wa li elese. A se ohun ibanuje si Olorun. Ko si eni ti o mo. Romu 3;10-18 fihan ni gidigidi gan bi ese se ri ninu aye wa. Ori keji ti igbala ona awon ara Romu fun igbala, Romu 6;23 ko wa ni ere ese- “Iku ni ere ese, sugbon ebu Oluwa ni iye ainipekun lati odo Jesu Kristi Olorun wa.” Iya ti o ye wa fun ese wa ni iku. Sugbon ki se iku ara sugbon iku ayeraye!

Ese keta igbala ona awon ara Romu fun igbala fihan ni ibi ti Romu 6;23 pari si, “Sugbon ebun Oluwa si ni iye ainipekun ninu Jesu Kristi Oluwa wa. “Romu 5;8 wipe,“ sugbon Oluwa fi ife re han si wa! Iku Jesu san gbese ese wa. Ajinde Jesu fi han wipe Oluwa gba Iku Jesu gege bi sisan gbese ese wa.

Ona kerin igbala ona awon ara Romu fun igbala wa si ni Romu 10:9, “wipe ti iwo ba toro idariji ese pelu enu re wipe Jesu ni Oluwa, ki iwo si gbagbo ninu okan re pe oluwa mu Jesu kuro ninu isa oku, iwo yi o ri igbala.” “Nitori iku Jesu fun wa, ohun ti o ye ka se ni ki aw ni igbagbo ninu re, ni ireti ninu iku re gege bi irapada fun ese wa- awa yi ni igbala! Romu 10;13 so wipe, enikeni ti o ba ke pe oruko oluwa yi o si ri igbala. “Jesu ku lati san gbese ese wa, o si gba wa la lowo iku ayeraye. Igbala, idariji ese, wa fun gbogbo eniyan ti o ba ni irreti ninu Jesu Kristi gege bi Olorun ati onigbala.

Akotan igbala ona awon ara Romu jasi igbala. Romu 5;1 ni imoran to dara yi. “nje bi a si ti nda wa lare nipa igbagbo, aw ni alafia lodo olorun nipa Oluwa wa Jesu Kristi; a le ni ibasepo pelu Jesu Kristi ti yi o si ja si ifokan ba le ninu Oluwa. Romu 8;1 ko wa wipe, “Nje ebi ko si nisisiyi fun awon ti o wa ninu Kristi Jesu.”Nitori iku Jesu nipa wa, awa ko ni ebi fun ese. Lakotan, awa ni ileri ninu Oluwa ni Romu 8;38-39, “Nitori o da mi loju pe, ki i se iku tabi iye, tabi awon angeli, tabi awon ijoye, tabi awon alagbara, tabi ohun igba isisiyi, tabi ohun igba ti mbo, tabi oke, tabi ogbun, tabi eda, miran kan ni yio le yaw a kuro ninu ife Olorun, ti o wa ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

Se iwo fe te le igbala awon ara Romu? To ba je be, eyi ni adura ni soki ti o ye ki o gba si Olorun. Gbigba adura yi je ona ti o fi le so fun Jesu Kristi pe iwo fi gbogbo igbesi aye re fun, fun igbala. Oro naa ko le fun o ni igbala sugbon igbagbo ninu Jesu Kristi nikan ni. “Oluwa, mo mo wipe mo ti dese si o, iya ni o si to si mi. Sugbon Jesu Kristi gbe gbogbo ese mi ru nitori ki emi le ni igbagbo ninu re fun idariji ese. Pelu iranlowo re, mo ko ese mi sile, mo si ireti mi sinu re fun igbala. E se fun ore-ofe yin ati idariji ese- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kini igbala ona awon ara Romu?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries