Ibeere
Ǹjẹ́ Jésù lọ sí ọ̀run-àpáàdì láàrin ikú àti àjíǹde Rẹ̀?
Idahun
Ìrújú ńlá kan wà nípa ìbéèrè yìí. Èròngbà wípé Jésù lọ sí ọ̀run-àpáàdì lẹ́yìn ikú Rẹ̀ lórí àgbélèbú wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn Ìjẹ́wọ́ Àpọ́stélì, èyí tí ó sọ wípé, "Ó lọ sínú ọ̀run-àpáàdì." Àwọn ìwé mímọ́ péréte ló wà, lórí bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀, tí ó ṣ'àpèjúwe Jésù tó lọ sí "ọ̀run-àpáàdì." Nínú kíkọ́ ẹ̀kọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣe pàtàkì láti kọ́kọ́ l'óye ohun tí Bíbélì ńkọ́ nípa ibùgbé àwọ́n òkú.
Nínú Ìwé Mímọ́ ti àwọ́n Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ṣ'àpèjúwe ibùgbé àwọ́n òkú ni sheol. Ó túmọ̀ sí "ibùgbé àwọ́n òkú" tàbí "ibùgbé àwọ́n ọkàn/ẹ̀mí t'óti lọ." Ìtumọ̀ sheol nínú Màjẹ̀mú Titun Gíríkì ni hades, èyí tí ó sì ńtọ́kasí "ibùgbé àwọ́n òkú." Àwọn Ìwé Mímọ́ mììrán nínú Màjẹ̀mú Titun fihàn wípé sheol/hades jẹ́ ibùgbé fún ìgbà díẹ̀, níbití a fi àwọn ọkàn pamọ́ sí bí wọ́n ṣé ńretí àjíǹde àti ìdájọ́ ìkẹhìn. Ifihan 20:11-15 fi ìyàtọ̀ kedere hàn láàrin hades àti adágún iná. Adágún iná ni ibi láíláí àti ìdájọ́ ìkẹhìn fún àwọn tó ti sọnù. Hades, wá jẹ́, ibi ìgbà díẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tọ́kasí hades àti adágún iná gẹ́gẹ́bí "ọ̀run-àpáàdì," èyí sí ńfa ipòruúru. Jésù ò lọ sí ibi ìpayínkeke lẹ́yìn ikú Rẹ̀, ṣùgbọ́n Òun lọ si hades.
Sheol/hades jẹ́ ibùgbé pẹ̀lú ìpín méjì — ibi ìbùkún àti ibi ìdájọ́ (Matteu 11:23; 16:18; Luku 10:15; 16:23; Iṣe awọn Apọsteli 2:27-31). Ibùgbé àwọn táa gbàlà àti àwọn tí ó sọnù ni à ńpè ní "hades" nínú Bíbélì. Ibùgbé àwọn táa gbàlà tún ńjẹ́ "àyà Abrahamu" (KJV) tàbí "ihà Abrahamu" (NIV) nínú Luku 16:22 àti "párádísè" nínú Luku 23:43. Ibùgbé àwọn tí kò gbàlà ni "ọ̀run-àpáàdì" (KJV) tàbi "Hades" (NIV) nínú Luku 16:23. Ibùgbé àwọn táa gbàlà àti àwọn tí ó sọnù ni a pín níyà pẹ̀lú "ọ̀gbun ńlá" (Luku 16:26). Nígbà tí Jésù kú, Ó lọ bùkun apákan sheol Ó sì mú àwọn onígbàgbọ́ láti ibẹ̀ lọ sí ọ̀run pẹ̀lú Rẹ̀ (Efesu 4:8-10). Ibi ìdájọ́ sheol/hades kò yàtọ̀. Gbogbo àwọn òkú aláìgbàgbọ́ lọ síbẹ̀ ní ìretí ìdájọ́ ìkẹhìn ní ọjọ́ iwájú. Ṣé Jésù lọ sí sheol àbí hades? Bẹ́ẹ̀ni, ní ìbámu pẹ̀lú Efesu 4:8-10 àti Peteru kínní 3:18-20.
Àwọn ipòruúru kọ̀ọ̀kan tí ó jẹyọ láti inú ẹsẹ̀ bíbélì bíi Orin Dáfídì 16:10-11 gẹ́gẹ́bí ìtumọ̀ inú ẹ̀ya King James: "Nítorí ìwọ kì yíò fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ipò-òkú; bẹ́ẹ̀ni ìwọ kì yíò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ kí o rí ìdibàjẹ́. . . . Ìwọ ó fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí." "Ọ̀run-àpáàdì" kìí ṣe ìtumọ̀ tí ó yẹ fún ẹsẹ yìí. Kíkàá lọ́nà t'ótọ́ yóò jẹ́ "isà òkú" tàbí "sheol." Jésù sọ fún olè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Rẹ̀, "Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè" (Luku 23:43); Kò sọ wípé, "Mà á rí ọ ní ọ̀run-àpáàdì." Ara Jésù wà nínú ibojì; ọkàn/ẹ̀mí Rẹ̀ lọ wà pẹ̀lú àwọn alábùkún fún ní sheol/hades. Óṣeniláànúú wípé, nínú ẹ̀dà Bíbélì púpọ̀, àwọn atúmọ̀ ò ṣe déédé, tàbi yege, nínú bí wọ́n ṣé ńtúmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríkì fún "sheol," "hades," ati ọ̀run-àpáàdì."
Àwọn kan ní ìwòye wípé Jésù lọ si "ọ̀run-àpáàdì" tàbí sí ibi ìjìyà sheol tàbí hades láti jìyà sii fún ẹ̀sẹ̀ wa. Èròńgbà yìí kò bá bíbélì mú rárá. Ikú Jésù l'órí igi àgbélèbú ló pèsè fún ìyè wa l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́. Ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ ló ran ìwẹ̀nù ẹ̀sẹ̀ wa (1 Johannu 1:7-9). Bí Òun ṣe wà l'órí igi àgbélèbú, Òun gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ènìyàn rù ara Rẹ̀. Òun di ẹ̀ṣẹ̀ fún wa: "Ọlọ́run ti fii se ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, kí àwa le di òdodo Ọlọ́run nínú Rẹ̀" (2 Kọrinti 5:21). Ìgbéyẹ̀wò ẹ̀sẹ̀ yìí ńràn wá lọ́wọ́ láti l'óye ìlàkàkà Kristi nínú ọgbà Gẹstímánì pẹ̀lú ife ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó dà lé E lórí igi àgbélèbú.
Bí Jésù ṣe súnmọ́ bèbè ikú, Òun ní, "Ó parí" (Johannu. 19:30). Òun parí ìyà tí ó yẹ ká jẹ. Ọkàn tàbí ẹ̀mí lọ sí hades (ibugbe awọn òkú). Jésù kò lọ sí "ọ̀run-àpáàdì" tàbí ibi ìjìyà hades; Òun lọ sí "ẹ̀gbẹ́ Abrahamu" tàbí apá hades tí ó ní ìbùkún. Ìjìyà Jésù parí ní kété tí ó kú. Òun san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀. Òun wá ńretí àjíǹde ara Rẹ̀ àti ìpadà sí ògó Rẹ̀ nínú ìpadàgòkè Rẹ̀. Ṣé Jésù lọ sí ọ̀run-àpáàdì? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ṣé Jésù lọ sí sheol àbí hades? Bẹẹni.
English
Ǹjẹ́ Jésù lọ sí ọ̀run-àpáàdì láàrin ikú àti àjíǹde Rẹ̀?