settings icon
share icon
Ibeere

Njẹ́ a kan Jésù mọ́ àgbélèbú ni Ọjọ́ Ẹtì? Bí ó bá ríbẹ̀, báwo l'óṣe lo ọjọ́ mẹ́ta nínú ibojì tí Òun bá jíǹde ni Ọjọ́ Àìkú?

Idahun


Bíbélì kò fi ọjọ́ ọ̀sẹ̀ tí a kan Jésù mọ́ àgbélèbú hàn kedere. Àwọn ìwòye méjì tí ó gbòòrò ni Ọjọ́ Ẹtì àti Ọjọ́'rú. Àwọn míràn, ẹ̀wẹ̀, jiyàn fún Ọjọ́ 'bọ̀ gẹ́gẹ́bí ọjọ́ naa, nípa lílo àjọṣepọ̀ àríyànjiyàn Ọjọ́ Ẹtì àti Ọjọ́'bọ̀.

Jésù sọ nínú Matteu 12:40, "Nítorí bí Jónà ti gbé ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta nínú ẹja, bẹ́ẹ́ní ọmọ ènìyàn yíò gbé ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta nínú ilẹ̀." Àwọn tí ó jiyàn fún ìkànmọ́ àgbélèbú Ọjọ́ Ẹtì sọ pé ọ̀nà tí ó gbà kàn wà ni, láti kàá wípé ò wà nínú ibojì fún ọjó mẹ́ta. Ní ọkàn àwọn Júù ti ọgọ́rùn-ún ọdun àkọ́kọ́, apá ọjọ́ kan ni a kà sí odidi ọjọ́. Níwọ̀n tí Jésù wà nínú ibojì fún ìgbà díẹ̀ nínú Ọjọ́ Ẹtì, gbogbo Ọjọ́ Àbámẹ́ta, àti ìgbà díẹ̀ nínú Ọjọ́ Àìkú — a lè kàá sí wípé Ó wà nínú ibojì fún ọjó mẹ́ta. Ọ̀kan nínú àwọn olórí àríyànjiyàn fún Ọjọ́ Ẹtì wà nínú Marku 15:42, èyítí ó tọ́ka si wípé a kan Jésù mọ́ àgbélèbú ni "ọjọ́ tí ó síwájú ọjọ́ ìsinmi." Bí ìyẹn bá jẹ́ ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí ni, Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ó wá dájú wípé ó ńtọ́ka sí ìkànmọ́ àgbélèbú Ọjọ́ Ẹtì. Àríyànjiyàn Ọjọ́ Ẹtì míràn sọ wípé àwọn ẹsẹ bíi Matteu 16:21 àti Luku 9:22 ńkọ́ni wípé Jésù yóò jí dìde ní ọjọ́ kẹ̀ta; nítorínà, kò ní nílò láti wà nínú ibojì fún odidi ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. Ṣùgbọ́n bí àwọn ìtumọ̀ kan ṣe lo "ní ọjọ́ kẹ̀ta" fún àwọn ẹsẹ yìí, kìí ṣe gbogbo wọn ló ṣe bẹ́ẹ̀, kìí sí ṣe gbogbo ènìyàn ló f'aramọ́ wípé "ní ọjọ́ kẹ̀ta" ni ọ̀nà tí ó dárajù láti túmọ̀ ẹsẹ wọ̀nyìí. Síwájú síi, Marku 8:31 sọ wípé Jésù yóò jíǹde "lẹ́yìn" ọjọ́ mẹ́ta.

Àríyànjiyàn Ọjọ́'bọ̀ náà gùnlé ìwòye Ọjọ́ Ẹtì tí ó sì ńjiyàn gidigidi wípé àwọn ohun púpọ̀ (àwọn míìrán pọ tó ogún) tí ó ńṣẹlẹ̀ láàrin ìsìnkú Jésù àti òwúrọ̀ Ọjọ́ Àìkú ti pọ̀jù láti wáyé láti ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Ẹtì sí òwúrọ̀ Ọjọ́ Àìkú. Àwọn olùfaramọ́ ìwòye Ọjọ́'bọ̀ tọ́kàsi wípé èyí jẹ́ ìṣòro pàápàá nígbàtí ó jẹ́ wípé Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ ìsinmi àwọn Júù nìkan ni ọjọ́ kíkún tí ó wà láàrin Ọjọ́ Ẹtì àti Ọjọ́ Àìkú. Àfikún ọjọ́ kan tàbí méjì mú ìṣòro náà kúrò. Àwọn alágbàwí Ọjọ́bọ̀ le ronú báyìí: kí a ní o kò tíì rí ọ̀rẹ́ rẹ kan láti ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Ajé. Òwúrọ̀ Ọjọ́'bọ̀ ni ìgbà míìrán tí o ríi ìwọ́ sì wípé, "Èmi kò tíì rí ọ fún ọjọ́ mẹ́ta" bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó jẹ́ wákàtí ọgọ́ta 60 (ọjọ́ méjì àbọ̀). Bí a bá kan Jésù mọ́ àgbélèbú ní Ọjọ́'bọ̀, àpẹẹrẹ yìí fihàn bí a ṣe le kàásí ọjọ́ mẹ́ta.

Àwọn onígbàgbọ́ Ọjọ́'rú sọ wípé ọjọ́ ìsinmi méjì l'ówà ní ọ̀sẹ̀ yẹn. Lẹ́yìn àkọ́kọ́ (èyí tí ó wáyé ni ìrọ̀lẹ̀ ìkàn mọ́ àgbélèbú (Marku 15:42; Luku 23:52-54]), àwọn obìnrin ra tùràrí- kíyèsi wípé wọ́n ràá lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi (Marku 16:1). Àwọn awòye Ọjọ́'rú gbàgbọ́ wípé "Ọjọ́ ìsinmi" yìí jẹ́ Ọjọ́ ìrékọjá (wo Lefitiku 16:29-31, 23:24-32, 39, níbití àwọn ọjọ́ mímọ́ ńlá tí kìí ṣe ọjọ́ ìsinmi ọ̀sẹ̀ ti jẹ́ ọjọ́ ìsinmi). Ọjọ́ ìsinmi kejì l'ọ́sẹ̀ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lásán. Ṣ'àkíyèsi wípé nínú Luku 23:56, àwọn obìnrin tí ó ti ra tùràrí lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi padà wọ́n sì pèse àwọn tùràrí náà, lẹ́yìn náà "wọ́n sinmi ní ọjọ́ ìsinmi." Àríyànjiyàn náà sọ wípé wọn kò lè ra àwọn tùràrí náà lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, síbẹ̀ pèsè àwọn tùràrí náà ṣáájú ọjọ́ ìsinmi-àyààfi tí ọjọ́ ìsinmi méjì bá wà. Pẹ̀lú ìwòye ọjọ́ ìsinmi méjéèjì, ti a bá kan Krístì mọ́ àgbélèbú ni Ọjọ́'bọ̀, ọjọ́ ìsinmi ńlá (Ìrékọjá) ò bá ti bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́'bọ̀ tí yóò sì parí ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Ẹtì-ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí Ọjọ́ Àbámẹ́ta. Ríra àwọn tùràrí náà lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi (Ìrékọjá) àkọ́kọ́ yóò túmọ̀ sí wípé wọ́n ti rà wọ́n ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta tí wọ́n sì ńṣẹ́ Ọjọ́ ìsinmi.

Nítorínà, gẹ́gẹ́bí ìwòye Ọjọ́'rú, àlàyé kanṣoṣo tí kò takò àkọsílẹ̀ bíbélì nípa àwọn obìnrin náà àti tùràrí èyítí ó sì mú ìtumọ̀ Matteu 12:40 tí ó yẹ dání, ni wípé a kan Kristi mọ́ àgbélèbú ní Ọjọ́'rú. Ọjọ́ ìsinmi tí ó jẹ́ ọjọ́ mímọ́ ńlá (Ìrékọjá) wáyé ni Ọjọ́'bọ̀, àwọn obìnrin náà ra tùràrí (lẹ́yìn náà) ni ọjọ́ Ẹtì, wọ́n sì padà, wọ́n sì pèse àwọn tùràrí náà l'ọ́jọ́ kannáà, wọ́n sinmi ní ọjọ́ Àbámẹ́ta èyí tíí ṣe Ọjọ́ ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n mú àwọn tùràrí náà lọ sí ibojì ni kùtùkùtù Ọjọ́ ìsinmi. A sin Jésù ní ìrọ̀lẹ̀ Ọjọ́'rú, èyítí ó bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ bọ̀ nínú kàlẹ̀ńdà àwọn Júù. Ní lílo kàlẹ̀ńdà àwọn Júù, o ní alẹ́ Ọjọ́ bọ̀ (alẹ́ àkọ́kọ́), ọ̀sán Ọjọ́ bọ̀ (ọjọ́ àkọ́kọ́), alẹ́ Ọjọ́ Ẹtì (alẹ́ kejì), ọ̀sán Ọjọ́ Ẹtì (ọjọ́ kejì), Ọjọ́ Àbámẹ́ta (alẹ́ kẹ̀ta),Ọjọ́ Àbámẹ́ta (ọjọ́ kẹ̀ta). A kò mọ̀ àkókò tí Òun jíǹde ní pàtó, ṣùgbọ́n a mọ̀ wípé kí òòrùn tó yọ ní Ọjọ́ Àìkú ni. Ó ṣeé ṣe kí Òun ti tètè jí dìde ní kété lẹ́yìn ìwọ̀-òrùn Ọjọ́ àbámẹ́ta, èyìtí ó bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀ àwọn Júù. Wọ́n ṣe àwárí ibojì tí ó ṣófo kí òòrùn tó yọ (Marku 16:2), kí ìmọ́lẹ̀ tó wa dáradára (Johannu 20:1).

Ìṣòro kan tí ó ṣeé ṣe pẹ̀lú ìwòye Ọjọ́'rú ni wípé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bá Jésù rìn l'ójú ọ̀nà Emmaus báa rìn ní ọjọ́ kannáà tí ó jíǹde (Luku 24:13). Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí kò dá Jésù mọ̀, sọ fún-un nípa kíkàn Jésù mọ́ àgbélèbú (24:21) tí wọ́n sì sọ wípé "òní ni ọjọ́ kẹ̀ta láti ìgbà tí ǹkan wọ̀nyìí tí ṣẹlẹ̀" (24:22) Ọjọ́'rú sí Ọjọ́ Àìkú jẹ́ ọjọ́ mẹrin. Àlàyé tó ṣeé ṣe ni wípé wọ́n lè máa ka ọjọ́ láti ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́'rú níbi ìsìnkú Kristi, èyítí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ọjọ́'bọ̀ àwọn Júù, àti wípé a lè ka Ọjọ́'bọ̀ sí Ọjọ́ Àìkú sí ọjọ́ mẹ́ta.

Nínú àwọn ẹ̀tọ̀ ńlá àwọn nǹkan, kò ṣe pátákí láti mọ ọjọ́ náà nínú ọ̀sẹ̀ tí a kan Jésù mọ́ àgbélèbú. Tí ó bá ṣe pátákí gan-an ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò bá ti sọ ọjọ́ àti ìgbà náà kedere. Ohun tí o ṣe pátákí ni wípé Óun sáà kú àti wípé Óun jí dìde l'ára kúrò nínú òkú. Ohun tí o ṣe pátákí bákannáà ni ìdí tí ó fi kú—láti mú ìjìyà tó yẹ gbogbo àwọn ẹlẹ́sẹ̀ kúrò. Johannu 3:16 àti 3:36 jùmọ̀ kéde wípé fífi ìgbàgbọ́ rẹ sínú Rẹ̀ yóò yọrí sí ìyè ayérayé! Èyí jẹ́ òtítọ́ bákannáà, bóyá a kan Jésù mọ́ àgbélèbú ní ọjọ́'rú, ọjọ́'bọ̀, tàbí ọjọ́ Ẹtì.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Njẹ́ a kan Jésù mọ́ àgbélèbú ni Ọjọ́ Ẹtì? Bí ó bá ríbẹ̀, báwo l'óṣe lo ọjọ́ mẹ́ta nínú ibojì tí Òun bá jíǹde ni Ọjọ́ Àìkú?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries