settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìdí tí Ọlọ́run Májẹ̀mú Láíláí ṣe yàtọ̀ sí Òun nínú Májẹ̀mú Titun?

Idahun


Ní àringbùngbùn ìbéèrè yìí ni àílòye ohun tí Àwọn Májẹ̀mú Láíláí àti Titun fihàn nípa àbùdá Ọlọ́run. Ọ̀nà míìrán láti fi ìpilẹ̀ṣẹ̀ èrò kannáà yíì hàn ni nígbàtí àwọn ènìyàn bá sọ wípé, "Ọlọ́run Májẹ̀mú Láíláí jẹ́ Ọlọ́run ìbínú nígbàtí Ọlọ́run Májẹ̀mú Titun jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́." Bí o ti jẹ́ òtítọ́ wípé Bíbélì jẹ́ ìfihàn Ọlọ́run nípa ara Rẹ̀ èyítí ó ńtẹ̀síwájú nípasẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn àti nípa àjọṣepọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní gbogbo ìran lè ṣe okùnfà àṣìtúmọ̀ nípa Ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ ní Májẹ̀mú Láíláí bí a bá fiwé Májẹ̀mú Titun. Ṣùgbọ́n, nígbàtí ènìyàn bá ka Àwọn Májẹ̀mú Láíláí àti Titun, yóò hàn wípé Ọlọ́run kò yàtọ̀ ní májẹ̀mú kan sí èkejì àti wípé àti ìbínú Ọlọ́run àti Ìfẹ́ Rẹ̀ ni o farahàn nínú májẹ́mú méjèèjì.

Fún àpẹẹrẹ, ni gbogbo Májẹ̀mú Láíláí, Ọlọ́run ni a pè ní "aláànu àti olóore-ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti Ẹni tí ó pọ̀ li oore àti òtítọ́," (Eksodu 34:6; Numeri 14:18; Deuterọnọmi 4:31; Nehemiah 9:17; Orin Dafidi 86:5, 15; 108:4; 145:8; Joẹli 2:13). Síbẹ̀ nínú Májẹ̀mú Titun, ìṣehun-ìfẹ́ Ọlọ́run àti àánú Rẹ̀ ni o farahàn síwájú si l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ nípaṣẹ̀ òtítọ́ wípé "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kansoso fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó ba gbàá gbọ́ má bà a ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àínìpẹkun (1 Johannu 3:16). Ní gbogbo Májẹ̀mú Láíláí, àwa tún rí Ọlọ́run tí ó ńba àwọn ọmọ Isrẹli ṣe ní ọ̀nà kan náà bí baba ṣeé ṣe pẹ̀lú ọmọ. Nígbàtí wọn bá mọ̀ọ́mọ̀ọ̀ d'ẹ́ṣẹ̀ lòdì sí Òun tí wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní sin òrìṣà, Ọlọ́run yóò ba wọn wí. Síbẹ̀, lọ́gan ní àkókò tí wọn ba ronúpìwàdà ìbọ̀rìṣà wọn Òun yóò gbà wọn. Èyí báramu pẹ̀lú ọ̀nà tí Ọlọ́run ńgbà ṣe pẹ̀lú àwọn Kristiẹni nínú Májẹ̀mú Titun. Fún àpẹẹrẹ, Heberu 12:6 sọ fún wa wípé "ẹnití Olúwa fẹ́, òun níi báwí: a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí ó gbà."

Ní ọ̀nà kan náà, ní gbogbo Májẹ̀mú Láíláí àwa rí ìdájọ́ Ọlọ́run àti ìbínú Rẹ̀ tú jáde sí ẹ̀ṣẹ̀. Ní ọ̀nà kan náà, nínú Májẹ̀mú Titun àwa ríi wípé ìbínú Ọlọ́run ni a fihàn "nítorí a fi ìbínú Ọlọ́run hàn si gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti àìsòdodo ènìyàn, àwọn ẹnití o fi àìṣòdodo tẹ òtítọ́ mọ́lẹ̀" (Romu 1:18). Nítorí náà, ó hàn kedere wípé Ọlọ́run kò yàtọ̀ nínú Májẹ̀mú Láíláí sí Májẹ̀mú Titun. Ọlọ́run nípa àbùdá Rẹ̀ jẹ́ àìyípadà (kìí yípadà). Bí o tilẹ̀ ṣe wípé àwa lè rí ihà kan lára àbùdá Rẹ̀ kí ó farahàn ní awọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ju àwọn míìrán lọ, Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ kìí yípadà.

Bí a ti ṣe ńka Bíbélì tí a ńkẹ́kọ̀ọ́, ó hàn kedere wípé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan náà nínú àwọn Májẹ̀mú Láíláí àti Titun. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wípé Bíbélì jẹ́ ìwé mẹ́rindìnláàdọ́rin (66) èyítí a kọ ní ìpín ayé méjì (tàbí ó ṣeé ṣe mẹ́ta) ní èdè mẹ́ta, ní bíi ọdún ẹgbẹ̀rún-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́-dẹ́gbẹ̀ta (1500) nípasẹ̀ oǹkọ̀wè ogójì (40), o jẹ́ ìwé tí ó ní àsopọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin láìsí àtakò. Nínú rẹ àwa rí bí Ọlọ́run tí ó nífẹ̀ẹ́, láànú, tí ó si tọ́ ṣe kojú ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀. Ní òtítọ́, Bíbélì jẹ́ lẹ́tà ìfẹ́ Ọlọ́run sí ìran ènìyàn. Ìfẹ́ Ọlọ́run fún ìṣẹ̀dá Rẹ̀, pàápàa fún ìran ènìyàn, ni o farahàn ní gbogbo Ìwé Mímọ́. Ni gbogbo Bíbélì àwa rí Ọlọ́run tìfẹ́tìfẹ́ àti tàánútàánú tí Òun ńpe àwọn ènìyàn sí àkànṣe ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, kìí ṣe torí wípé wọn yẹ, ṣùgbọ́n nítorí wípé Ọlọ́run pọ̀ ní àánú, ti Òun lọ́ra láti bínú tí Òun si pọ̀ ní ìfẹ́-inú rere àti òtítọ́. Síbẹ̀ àwa tún rí Ọlọ́run mímọ́ àti olódodo tí ó jẹ́ Onídàjọ gbogbo àwọn tí kò gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tàbí kọ̀ láti jọ́sìn fún-Un, tí wọn yípadà sí àwọn òrìṣà tí wọn ṣẹ̀dá fún ra wọn (Romu orí 1).

Nítorí ìjẹ́ olódodo àti ìwà mímọ́ ti Ọlọ́run, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀—àtijọ́, lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ọjọ́ iwájú—ni a gbọ́dọ̀ dá lẹ́jọ́. Síbẹ̀ Ọlọ́run nínú ìfẹ́ Rẹ̀ tí kò l'ópin ti pèsè owó fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀nà ìbálàjà kí ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ bà á lè sa àsálà fún ìbínú Rẹ̀. Àwa rí òtítọ́ ìyanu yìí nínú ẹsẹ̀ 1 Johannu 4:10: "Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kìí ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Òun fẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ Rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa." Nínú Májẹ̀mú Láíláí, Ọlọ́run pèsè ètò ìrúbọ nípasẹ̀ èyí tí a lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n, ètò ìrúbọ yìí wà fún ìgbà díẹ̀ tí ó kàn ńwo bíbọ̀ Jésù Kristi tí yóò kú lórí àgbéléèbú láti parí ètùtù gbígba ipò ẹni ní ọjọ́ iwájú. Olùgbàlà tí a ṣe ìlérí ní Májẹ̀mú Láíláí fi ara hàn l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ ni Májẹ̀mú Titun. Èyí tí a kò fi ìran rẹ̀ hàn ní Májẹ̀mú Láíláí, gbèdéke ìfarahàn ìfẹ́ Ọlọ́run, fífi Ọmọ Rẹ̀ Jésù Kristi ráńṣẹ́, ní a fihàn ní gbogbo ògo Rẹ̀ ní Májẹ̀mú Titun. A fún wa ní Májẹ̀mú Láíláí àti Titun "láti sọ wá di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà" (2 Timoteu 3:15). Nígbàtí a kẹ́kọ̀ọ́ àwọn Májẹ̀mú náà fínnífínní, o hàn wípé Ọlọ́run "kìí yípadà bíi òjìjì" (Jakọbu 1:17).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìdí tí Ọlọ́run Májẹ̀mú Láíláí ṣe yàtọ̀ sí Òun nínú Májẹ̀mú Titun?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries