Ibeere
Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì tako ara wọn bí?
Idahun
Sáyẹ̀nsì ni a túmọ̀ sí "wíwo, ìdánimọ̀, àpèjúwe, ìwádí tuntun, àti àlàyé lórí ohun tí á rò nípa ìṣẹ̀lẹ̀." Sáyẹ̀nsì ni ọ̀nà ti irúfẹ́ ènìyàn le lò láti ní òye tí ó gbilẹ̀ si nípa ìṣẹ̀dá ayé. Ó jẹ́ wíwá ìmọ̀ nípa wíwò. Ìtẹ̀síwájù lórí sáyẹ̀nsì ṣe àpèjúwe ibi tí ìrònú àti èrò ènìyàn gbe dé. Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ Kristiẹni nínú sáyẹ̀nsì kò gbọ́dọ̀ dàbí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run. Kristiẹni lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, kí ó sì bọ̀wọ̀ fún sáyẹ̀nsì, ní wọ̀n ìgbà tí a bá rántí èyí tí ó pé àti èyí tí kò pé.
Ìgbẹkẹ̀lé wa nínú Ọlọ́run jẹ́ ìgbẹkẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́. A ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Rẹ̀ fún ìgbàlà, ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fún ìtọ́ni àti ìgbàgbọ́ nínú Ẹ̀mí Mímọ́ fún ìdarí. Ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ odidi, níwọ̀n ìgbàtí a bá fi ìgbàgbọ́ wa sínú Ọlọ́run, a gbẹ́kẹ̀lé Ẹlẹ̀dá tí ó pé, tí ó lè ṣe ohun gbogbo, tí ó mọ ohun gbogbo. Ìgbàgbọ́ wa nínú sáyẹ̀nsì kò gbọ́dọ̀ ju ti ìmọ̀ lọ, kò sí nǹkan míìrán lẹ́yìn èyí. A lè gba sáyẹ̀nsì gbọ́ láti ṣe ọ̀pọ̀ ohun ńlá, bẹ́ẹ̀ sì ni, a lè gbàá gbọ́ láti ṣe àṣìṣe. Bí a bá gbàgbọ́ nínú sáyẹ̀nsì, a gbẹ́kẹ̀lé ẹlẹ̀ran ara tí kò pé, tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ní gbèdéke. Nípa ìtàn, sáyẹ̀nsì ti ṣe àṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà lórí àwọn nǹkan, bíi ipò tí ayé ní, fífòlójú òfuruufú tí a ró lágbára, àjẹsára, ìfà ẹ̀jẹ̀ sára, àtí bíbí si. Ọlọ́run kò lè ṣe àṣìṣe láíláì.
Kò sí ohunkóhun láti bẹ̀rù nípa òtítọ́, kò sí ìdí fún Kristiẹni láti bẹ̀rù sáyẹ̀nsì tí ó dára. Kíkọ́ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ayé si yóò ran ènìyàn lọ́wọ́ láti mọrírì ìṣẹ̀dá. Mímú ìmọ̀ wa gbòrò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti bá àìsàn, àìmọ̀, àti àìgbọ́raẹniyé jà. Ṣùgbọ́n, ó léwu nígbàtí àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì bá rọ̀mọ́ ìgbàgbọ́ nínú èrò ènìyàn ju ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ̀dá lọ. Àwọn ènìyàn yìí kò yàtọ̀ sí ẹnikẹ́ni tí ó farajìn fún ẹ̀ṣìn; wọ́n tí yan ìgbàgbọ́ nínú ènìyàn, wọ́n ó sì wá ẹ̀rí láti gbe ìgbàgbọ́ náà ró.
Síbẹ́, onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì tí ó suwọ̀n jù, kó dà àwọn tí ó kọ̀ láti gba Ọlọ́run gbọ́, gbà wípé a kò ní ìmọ̀ tí ó péye nípa àgbáyé. Wọ́n gbà wípé a kò lè faramọ́ tàbí ṣe àtakò Ọlọ́run tàbí Bíbélì nípa sáyẹ́nsì, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àṣàyàn ẹ̀kọ́ wọn kó ṣé faramọ́ tàbí takò. Sáyẹ́nsì yẹ kò jẹ́ ẹ̀kọ́ tí kò ní ojú ìṣáájú ní tòótọ́, kìí ṣe ìtẹ̀síwájú ètò kan.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú sáyẹ́nsì faramọ́ ìwàláàyè àti iṣẹ́ Ọlọ́run. Orin Dafidi 19:1 sọ wípé,"Àwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọ́run, àti òfurufú ńfi iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ hàn." Bí sáyẹ́nsì ìgbàlódé ṣe ńmọ̀ si nípa ayé, a ńríí ẹ̀rí si nípa ìṣẹ̀dá. Ìyàlẹ́nu nípa bí DNA ṣe jinlẹ̀ sí àtí bí ó ṣe ńpọ̀si, ìlọ́júpọ̀ àti ìwọnúara àwọn òfin ẹ̀kọ́ ohun ti a lè fójú rí (physics), àti ìbáramu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtí ipo nǹkan ní ayé ńṣisẹ́ pọ̀ láti faramọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Kristiẹni gbọ́dọ̀ gbé sáyẹ́nsì tí ó wá òtítọ́ lárugẹ, ṣùgbọ́n kí wọ́n kọ "àwọn àlùfá sáyẹ́nsì" tí wọ́n gbé ìmọ̀ ènìyàn gaju Ọlọ́run lọ.
English
Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì tako ara wọn bí?