settings icon
share icon
Ibeere

Njẹ́ Ọlọ́run ṣì ńbáwa sọ̀rọ̀ lónìí?

Idahun


Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ bi Ọlọ́run ṣe ńbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ kedere l'ọ́nà t'ópọ̀ (Ẹksodu 3:14; Joṣua 1:1; Awọn Onidajọ 6:18; 1 Samuẹli 2:1; Jobu 40:1; Isaiah 7:3; Jeremiah 1:7; Iṣe àwọn Apọstelì 8:26; 9:15 — èyí jẹ́ àpẹẹrẹ kékeré). Kò sí ìfììdímúlẹ̀ bíbélì kankan wípé Ọlọ́run kò lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ lóhùn kedere lónìí. Pẹ̀lú ọgọgọ́rùn-ún ọ̀nà ti bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ wípé Ọlọ́run ńsọ̀rọ̀, a gbọ́dọ̀ rántí wípé wọ́n sẹlẹ̀ ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin ìtàn ọmọ ẹ̀nìyàn. Ọlọ́run ńsọ̀rọ̀ lóhùn kedere dá yàtọ̀, kìí ṣe òfin náà. Kódà nínú àwọn àkọsílẹ̀ bíbélì wípé Ọlọ́run ńsọ̀rọ̀, kò hàn kedere nígbàgbogbo bóyá ohùn kedere ni, ohùn inú, tàbí èrò ọpọlọ.

Ọlọ́run ńbáwa sọ̀rọ̀ lónìí. Akọ́kọ́, Ọlọ́run ńbáwa sọ̀rọ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (2 Timoteu 3:16-17). Isaiah 55:11 sọ fún wa, "'Bẹ́ẹ̀ni ọ̀rọ̀ mí tí ó ti ẹnu mi jáde yíò rí: kì yíò pàdà sọ́dọ̀ mi l'ófo, ṣùgbọ́n yíò si ma ṣe rere ninu ohun ti mo rán-an." Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbogbo ohun tí a nílò láti mọ̀ kí a le dì ẹni ìgbàlà àti gbé ìgbé-ayé Onígbàgbọ́. Peteru Kejì 1:3 sọ wípé, "Bi agbára rẹ̀ Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí ṣe ti ìyè àti ìwà-bí-Ọlọ́run nípa ìmọ̀ ẹnití ò pè wá nípa ògo àti ọláńlá Rẹ̀."

Ọlọ́run tún lè báwa "sọ̀rọ̀" nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ — à ní, Ó lè tọ́ wa nípa ṣíṣètò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wa. Àti wípé Ọlọ́run ńràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì nípa ẹ̀ri ọkàn wa (1 Tímoteu 1:5; 1 Peteru 3:16). Ọlọ́run wà l'ójú iṣẹ́ láti jẹ́ kí ọkàn wa máa ro àwọn èrò Rẹ̀ (Romu 12:2). Ọlọ́run ńgba àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láàyè nínú ayé wa láti darí wa, yí wa padà, àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà l'ẹ̀mí (Jakọbu 1:2-5; Heberu 12:5-11). Peteru kìnní 1:6-7 rán wa l'étí, "Nínú èyítí ẹ̀yin ńyọ̀ púpọ̀, bí ó tilẹ̀ ṣe wípé nísisìyí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀nbí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdàńwò bà yìn nínú jẹ́. Kí ìdàńwò ìgbàgbọ́ yín, tí ó ní iye lórí ju wúrà tí íṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ ṣe wípé iná li à fí ńdán-an wò kí á le ríi fún ìyìn, àti ọlá, àti nínú ògo ní ìgbà ìfarahàn Jésù Kristi."

Ọlọ́run nígbà míìrán le sọ̀rọ̀ kedere sí àwọn ènìyàn. Ó jẹ́ iyèméjì ńlá, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé èyí ńṣẹlẹ̀ l'óòrèkóórè bí àwọn ènìyàn kan ṣe ní ó ńṣẹlẹ̀. L'ẹ́ẹ̀kansí, kódà nínú Bíbélì, Ọlọ́run ńsọ̀rọ̀ kedere dá yàtọ̀, kìíṣe l'ásán. Bí ẹnìkan bá sọ wípé Ọlọ́run ti bá òun sọ̀rọ̀, ríi dájú wípé o ṣe àfiwé ohun tó sọ pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ nígbàgbogbo. Bí Ọlọ́run bà fẹ́ sọ̀rọ̀ lóòní, ọ̀rọ̀ Rẹ̀ yóó wà ní ìbámu ní kíkún pẹ̀lú ohun tí Óun ti sọ nínú Bíbélì (2 Timoteu 3:16-17). Ọlọ́run kìí tako ara Rẹ̀.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Njẹ́ Ọlọ́run ṣì ńbáwa sọ̀rọ̀ lónìí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries