settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àdúrà ìgbàlà?

Idahun


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bèèrè, "Ṣé àdúrà kan tí mo le gbà wà tí yóò fún mi ní ìdánilójú ìgbàlà?" Ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé a kò gba ìgbàlà nípa àdúrà gbígbà tàbi kíka ọ̀rọ̀ kan síta. Kò sí ibi tí Bíbélì ti ṣe àkọsílẹ̀ ènìyàn tí ó ńfi àdúrà gbígbà gba ìgbàlà. Àdúrà gbígbà kò bá àkọsílẹ̀ Bíbélì mu nípa ìgbàlà.

Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìgbàlà ni ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Johannu 3:16 sọ fún wa wípé "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kansọsọ fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó ba gbàá gbọ́ má ba ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àínìpẹkun." A gba ìgbàlà nípa ìgbàgbọ́ (Efesu 2:8), nípa gbígba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà (Johannu 1:12), àti nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Jésù nìkan (Johannu 14:6; Iṣe àwọn Apọsteli 4:12), kìí ṣe nípa àdúrà gbígbà.

Ọ̀rọ̀ bíbélì nípa ìgbàgbọ́ rọrùn, hàn kedere, ó sì dùn bákànnáà. Gbogbo wa ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run (Romu 3:23). Yàtọ̀ sí Jésù Kristi, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ti gbé gbogbo ìgbé-ayé rẹ̀ láì ṣẹ̀ (Oniwaasu 7:20). Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ti j'èrè ìdájọ́ láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run—ikú (Romu 6:23). Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìjìyà tí ó yẹ fún, kò sí ohun tí a lè dá ṣe láti mú kí á wà ní ìbáamu pẹ̀lú Ọlọ́run. Ní àyọrísí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa, Ọlọ́run di ènìyàn Ẹni tíí ṣe Jésù Kristi. Jésù gbé ìgbé-ayé pípé tí ó sì ńkọ́ òtítọ́ nígbàgbogbo. Ṣùgbọ́n, ìran ènìyàn kọ Jésù wọ́n sì páá nípa kíkàn Án mọ́ àgbélèbú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìṣe búburú yẹn pa ọkùnrin aláìṣẹ̀ nì, a gba ìgbàlà wa. Jésù kú dípò wa. Òun gbé ẹrù àti ìdájọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa ru ara Rẹ̀ (2 Kọrinti 5:21). Jésù wá jíǹde (1 Kọrinti 15), èyí fihàn wípé sísan gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ tó àti wípé Òun ti ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Gẹ́gẹ́ bíi àyọrísí ètùtù Jésù, Ọlọ́run fún wa ní ìgbàlà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ọlọ́run pe gbogbo wa láti ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa (Iṣe àwọn Apọsteli 17:30) kí á sì ní ìgbàgbọ́ nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí sísan gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa ní kíkún (1 Johannu 2:2). A rí ìgbàlà gbà nípa gbígba ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa, kìí ṣe nípa gbígba àdúrà kan.

Ní bàyìí, ìyẹn kìí ṣe wípé a kò lè gba àdúrà pẹ̀lú láti gba ìgbàlà. Bí ìwọ bá ní òye ìhìnrere, gbàá gbọ́ wípé ó jẹ́ òtíítọ́, tí o sì ti gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi olùgbàlà rẹ, ó dára ó sì yẹ láti fi ìgbàgbọ́ yẹn hàn sí Ọlọ́run nínú àdúrà. Bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa àdúrà lè jẹ́ ọ̀nà kan láti dàgbà kúrò nínú gbígba àwọn ọ̀rọ̀ nípa Jésù sí gbígbàgbọ́ nínú Rẹ̀ l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùgbàlà. Àdúrà le so pọ̀ mọ́ fífi ìgbàgbọ́ sínú Jésù nìkan fún ìgbàlà.

Lẹ́ẹ̀kan síi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, ó ṣe pàtàkì gidigidi wípé kí o má gbé ìgbàlà rẹ sí orí àdúrà gbígbà. Àdúrà gbígbà kò lè gbà ọ̀ là! Bí o bá fẹ́ gba ìgbàlà tí ó wà nípasẹ̀ Jésù, fi ìgbàgbọ́ rẹ sínú Rẹ̀. Gbàgbọ́ nínú ikú Rẹ̀ l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ètùtù kíkún fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Gbẹ́kẹ̀le Òun pátápáta gẹ́gẹ́ bíi olùgbàlà rẹ. Ìyẹn ni àgbékalẹ̀ Bíbélì fún ìgbàlà. Bí o bá ti gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi olùgbàlà rẹ, ní gbogbo ọ́nà, gba àdúrà sí Ọlọ́run. Sọ fún Ọlọ́run bí o ṣe moore Jésù sí. Fi ìyìn fún Ọlọ́run fún ìfẹ́ àti ètùtù Rẹ̀. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù fún kíkú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti pípèsè ìgbàlà fún ọ. Èyí ni àsopọ̀ tí ó wà láàrin ìgbàlà àti àdúrà tí ó ba Bíbélì mu.

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.



English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni àdúrà ìgbàlà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries