Ibeere
Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà mi?
Idahun
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ wípé ìdáhùn sí àdúrà ni kí Ọlọ́run dáhùn ẹ̀bẹ̀ àdúrà ti wọn ba bẹ Òun. Bí a kò bá dáhùn ẹ̀bẹ̀ àdúrà kan, a kàa sí àdúrà "tí a kò dáhùn". Ṣùgbọ́n, èyí jẹ́ òye àdúrà tí kò tọ́. Gbogbo àdúrà tí a bá darí si ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Òun ńdàhùn. Nígbàmíi Ọlọ́run ńdáhùn pẹ̀lú "rárá"tàbí "dúró." Ọlọ́run ṣe ìlérí láti dáhùn àwọn àdúrà wa nígbàtí a bá bèèrè gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ Rẹ̀ nìkan. "Eyi si ni igboya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa. Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ ti wa, ohunkohun ti awa ba bere, awa mọ̀ pe awa ri ibere ti awa ti bere lọdọ rẹ̀ gbà" (1 Johannu 5:14-15).
Kínni o túmọ̀ sí láti gbàdúrà gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ Ọlọ́run? Gbígbàdúrà gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ gbígbàdúrà fún àwọn nǹkan tí ó bu ọlá àti ògo fún Ọlọ́run àti/tàbi gbígbàdúrà fún ohun tí Bíbélì fihàn kedere wípé ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́. Bí àwa bá gbàdúrà fún nǹkankan tí kò fi ọlá fún Ọlọ́run tàbí tí kìí ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé wa, Ọlọ́run kò ní fún wa ni ohun tí a béèrè fún. Báwo ni a ṣe lè mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́? Ọlọ́run ṣe ilérí láti fún wa ní ọgbọ́n nígbàtí a bá béèrè fún-un. Jakọbu 1:5 sọ wípé, "Bi o ba ku ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bere lọwọ Ọlọ́run, ẹniti ifi fun gbogbo èniyàn ni ọpọlọpọ, ti kì isi baniwi, a o si fifun u." Ibi tí ó dára láti bẹ̀rẹ̀ ni 1 Tẹssalonika 5:12-24, tí ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa. Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ṣe yé wa sí, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò ṣe mọ ohun tí ó yẹ láti gbàdúrà fún (Johannu 15:7). Bí a bá ṣe mọ ohun tí ó yẹ láti gbàdúrà fún, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run yóò dáhùn "bẹ́ẹ̀ni" fún àwọn ìbéèrè wa.
English
Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà mi?