settings icon
share icon
Ibeere

Àwọn wo ni Ajẹ́rìí Jèhófa àti kínni wọ́n gbágbọ̀?

Idahun


Àwọn ẹgbẹ́ tí a mọ̀ lóde òní gẹ́gẹ́ bíi àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní Pẹnisilifáníà ní 1870 bíi kílàsì Bíbélì tí a ńdarí láti ọwọ́ Charles Taze Russel. Russell pe orúkó ẹgbẹ́ rẹ̀ nì "Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ Kíkọ́ Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti Ẹlẹ́gbẹ̀ẹ́rún ọdún," ti a sì ǹpé àwọn tí ó ńtẹ̀le ní "Àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ Bíbélì." Charles T. Russell bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ àwọn onírúurú àwọn ìwé tí ó pè ní "Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ti Ẹgbẹ̀rún ọdún," èyí tí o gùn dé àwọn abala mẹ́fà ṣáájú ìkú rẹ̀ tí ó sì kún fún púpọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ti Ajẹ́rìí Jèhófà ńdìmú. Ilé-ìṣọ́ Bíbélì àtì Ẹgbẹ́ Tí ó ńṣe ìwé pélébé ni a dá sílẹ̀ ní 1886 ti ó sì yára di ọkọ̀ nípasẹ̀ èyí "Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún ọdún," ẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní pín àwọn ojú ìwòye wọn. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ nìgbà míìrán a máa ńfi ẹnu àtẹ́ pè wọn nì "Rusẹliti." Lẹ́hìn ikù Rùselì nì 1916, Judge J. F. Rutherford, Ọ̀rẹ́ Rutherford, àti ẹni tì ó wá lẹ́hìn rẹ̀, kọ abala kéje àti ìparí "Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ti Ẹgbẹ̀rún ọdún," àwọn àkójọpọ̀ rẹ̀, "Àdìtú Àṣeparí," ní 1917. Ìyẹ́n jẹ́ ọdún tí ilé iṣẹ́ náà pín. Àwọn tí ó tẹ̀lé Rutherford bẹ̀ẹ́rẹ̀ sí ni pe ara wọn ní "Ajẹ́rìí Jèhófà."

Ǹjẹ́ kínni àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà gbàgbọ́? Àwò fínífíní ti ipò àwọn ẹ̀kọ́ wọn lórí àwọn kókó bíi jíjẹ́ Ọlọ́run ti Kristi, ìgbàlà, Mẹ́talọ̀kan, Ẹ̀mí Mìmọ̀, àti ìwẹ̀nùmọ́ ńfihàn tayọ iyèméjì kan tí wọn kò dì mú, sí ìdúró àwọn Kristiẹni àtijọ́ lórí àwọn kókó wọ̀nyìí. Àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà gbàgbọ́ wípé Jésù jẹ́ Máíkẹ̀lì, olórí ańgẹ́lì, ìṣẹ̀dá tí ó ga jùlọ. Èyì tako púpọ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ tí ó kéde kedere Jésù bìí Ọlọ́run (Johannu 1:1, 14, 8:58, 10:30). Àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà gbàgbọ́ wípé ìgbàlà ni a ma ńrì gbà nípa àkójọpọ̀ ìgbàgbọ́, àwọn ìṣẹ́ rere, àti ìgbọ́ràn. Èyí tako àìníye àwọn ìwé mímọ́ tí ó kéde ìgbàlà láti jẹ́ èyí tí a rí gbà nípa ore-ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (Johannu 3:16; Efesu 2: 8-9; Titu 3:5). Àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà kọ mẹ́talọ̀kan, gbígbàgbọ́ wípé Jésù jẹ́ ìṣẹ̀dá ènìyàn àti Ẹ̀mí Mímọ́ làti jẹ́ agbára ti Ọlọ́run tí kò ní iyè nínú tí o ṣe kókó. Àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà kọ àgbékalẹ̀ ti ètùtù arọ́pò tí Kristi dípò rẹ̀ wọn dì ìlànà ìdíyelé, wípé ikú ti Jésù jẹ́ ti sísan ìdíyelé kan fún ẹ̀ṣẹ̀ ti Ádámù mú.

Báwo ni àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà ṣe fẹ́ sọ di ìtẹ́wọ́gbà àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyìí tí kò bá bíbélì mu? Ní àkọ́kọ́ wọ́n wípé ìjọ ti ba Bíbélì jẹ́ fún bíi ọgọ́ọ̀rún ọdún sẹ́yìn; nítorí náà, wọ́n ti tún Bíbélì túmọ̀ sí èyí tí wọ́n pè ní Ìtumọ̀ ti Àgbáyé Titun (New World Translation). Ilé-ìṣọ́ Bíbélì àti Ẹgbẹ́ Tí ó ńṣe ìwé pélébé, ṣe àyípadà sí ọ̀rọ̀ akọsílẹ̀ ti Bíbélì kí ó lè wà ní ìbámu rẹ́gí sí ẹ̀kọ́ èké wọn, dípo kí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ awọn ẹ̀kọ́ wọn lé orí ohun ti bibélì ńkọ́ ni ní pàtó. Ìtúmọ̀ ti Àgbáyé Titun, ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtúnyẹ̀wò kọjá, bí àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà ti ńṣe àwárí síwájú síi àwọn ẹsẹ̀ bíbélì tí ó ńtako àwọn ẹ̀kọ́ wọn.

Ilé-ìṣọ̀ ńṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ lé orí ojúlówó àti àwọn ìkọ́ni tí a fẹ̀ lójú ti Charles Taze, Russell, Judge Joseph Franklin Rutherford, àti àwọn tí ò wá lẹ́hìn wọn. Àjọ tí ó ńṣe àkóso ti ti Ilé-ìṣọ́ Bíbélì àti Ẹgbẹ́ Tí ó ńṣe ìwé pélébé jẹ́ àjọ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tí ó ńjẹ́wọ́ wípé àwọn nìkan ni ó ní àṣẹ láti ṣe ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́. Ní èdè míìrán, ohun tí àjọ tí ó ńṣè jọ̀ba ńsọ nípa èyíkéyì ẹsẹ ìwé mímọ́ ni a ńwò gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́hìn, àti níní ìrònú ara ẹni ni à kò ṣe kóríyá fún. Èyí wá ní àtakò tààrà sí àmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sí Tímóteù (àti sí àwa náà pẹ̀lú), láti kọ́ ẹ̀kọ́ sí jíjẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má ba di ẹni tí ojú tì bí a ti ńdi Ọrọ̀ Ọlọ́run mú. Àmọ̀ràn yìí tí a rí nínú 2 Timoteu 2:15 jẹ́ ìtọ́ni kedere láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí olúkulùkù àwọn ọmọ rẹ̀ láti rí bíi àwọn Kristiẹni ti Bèríà, tí ó wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ l'ójojúmọ́ láti ríi bí àwọn ohun tí à ńkọ́ wọn bá wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ náà.

Ó fẹ́ẹ̀ lè má sí ẹgbẹ́ ẹ̀sìn kankan tí ó jẹ́ olótìtọ́ ju àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà lọ nípa mímú ìfiránṣẹ́ wọn jáde. Ó ṣe ní láànú, ìfiránṣẹ́ náà kún fún àyídáyidà, ìtànjẹ, àti ẹ̀kọ́ èké. Kí Ọlọ́run sí ojú àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà sí òtítọ́ ti ìhìnrere àti òtítọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Àwọn wo ni Ajẹ́rìí Jèhófa àti kínni wọ́n gbágbọ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries