settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ẹ̀kọ́ àkókò tí ó ṣíwájú ẹgbẹ̀rún ọdún?

Idahun


Ẹ̀kọ́ àkókò tí ó ṣíwájú ẹgbẹ̀rún ọdún ni ìwò wípé ìpadàbọ́ Jésù Kristi kejì yóo ṣẹlẹ̀ ṣíwájú ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún rẹ̀, àti wípé ẹgbẹ̀rún ọdún jẹ́ ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún ní pàtó ti Kristi nínú ayé. Láti mọ àti láti túmọ̀ àwọn àyọkà inú Ìwé Mímọ́ tí ó sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òpin ayé, a ní láti ní ìmọ̀ yékéyéké nípa nǹkan méjì yìí: ọ̀nà tí ó tọ́ láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ àti iyàtọ̀ tí ó wà láàrin Isrẹli (àwọn Júù) àti ìjọ (àpapọ̀ gbogbo onígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi).

Àkọ́kọ́, ọ̀nà tí ó tọ́ láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ nílò wípé kí á túmọ̀ ìwé Mímọ́ ní ọ̀nà tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú èròǹgbà rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí wípé a gbọ́dọ̀ túmọ̀ àyọkà ní ọ̀nà tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí a kọọ́ sí, àwọn ẹni tí a kọọ́ nípa, ẹni tí a ti ipasẹ̀ rẹ̀ kọọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣe pàtàkì láti mọ olùkọ̀wé náà, èró tí a ni l'ọ́kàn àti ìtàn ìpìlẹ̀ ti àyọkà kọ̀ọ̀kan tí à ńtúmọ̀. Ìtàn ìpìlẹ̀ àti àṣà ní ọ̀pọ̀ ìgbà yóò fi ìtumọ̀ ti àyọkà ní hàn nítòótọ́. Ó tún ṣe pàtàkì kí á ráńtí wípé Ìwé Mímọ́ máa ńtúmọ̀ Ìwé Mímọ́. Bí a ṣe wípé, àyọkà yóò nìí orí ọ̀rọ̀ àti kókó ọ̀rọ̀ tí ati ṣàlàyé níbòmíràn nínú Bíbélì. Ó ṣe pàtàkì kí á túmọ̀ gbogbo àwọn àyọkà wọ̀nyìí ní ìlànà kańnáà pẹ̀lú ara wọn.

Lákòótán, àti ní pàtàkì jùlọ, a gbọ́dọ̀ mú àyọkà ní ìtumọ̀ tí o dára, ṣe déédé, mọ́, tọ́, àti gẹ́gẹ́ bíi wọn ṣe kọọ́ sílẹ̀, à fi tí èròǹgbà náà bá túmọ̀ sí wípé o ní àbùdà àkànlò èdè. Ìtumọ̀ gẹ́gẹ́ bíi wọn ṣe kọ́ kò yọ àǹfàní láti lo àkànlò èdè kúrò. Dípò, kì yóò gba olùtumọ̀ níyànjú láti má lo àkànlò èdè sí ìtumọ̀ àyọkà, ààye bí ó bá tọ́ fún èròǹgbà àyọkà náà. Ó ṣe pàtàkì láti máa wá ìtumọ̀ tí ó "jinlẹ̀, kún fún ẹ̀mì ju" ìtumọ̀ ohun tí à ńgbé kalẹ̀ lọ. Ó léwu kí á máa fi ẹ̀mì tumọ̀ àyọkà nítorí wípé yóò mú ìpìlẹ̀ fún ìtumọ̀ tí ó péye kúrò nínú Ìwé Mímọ́ lọ sí ọkàn ẹni tí ó ńkàá. Nígbà náà, kò lè sí òṣùwọ̀n àtakò fún ìtumọ̀; bíkòṣe wípé Ìwé Mímọ́ tẹríba sí èróńgbà ẹnìkọ̀ọ̀kan nípa ohun tí ó túmọ̀ rẹ̀ sí. Ìwé Peteru kejì 1:20-21 rán wa létí wípé, "kí ẹ kọ́ mọ èyí pé kò sí ọ̀kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ tí ó ní ìtumọ̀ ìkọ̀kọ̀. Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipa ìfẹ́ ènìyàn wá rí: ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ńsọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ńdarí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí mímọ́ wá."

Mímú àwọn ìlànà ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyìí lò, a gbọ́dọ̀ ri wípé Isrẹli (àwọn ìran Ábráhámù) àti ìjọ náà (gbogbo onígbàgbọ́ Májẹ̀mú Titun) jẹ́ ìpin méjì tí ó yàtọ̀ gedegbe. Ó se pàtàkì láti mọ ìyàtọ̀ gedegbe tí ó wà láàrin Isrẹli àti ìjọ, nítorí wípé, tí a bá ṣi èyí mọ̀, a ma a ṣi Ìwé Mímọ́ túmọ̀. Àwọn àyọka tí ó lúgbàdì ìtumọ̀ òdì jù ni àwọn tí ó sọ nípa ìlérí tí a ṣe fún Isrẹli (àwọn tí ó ti ṣẹ àti àwọn tí kò tíì ṣẹ). A kò gbọ́dọ̀ mú àwọn ìlérí bẹ́ẹ̀ lò fún ìjọ. Rántí wípé, èròǹgbà àyọkà ló máa sọ ẹni tí a kọọ́ sí, tí yóo sì tọ́ka sí ìtumọ̀ tí ó yẹ jùlọ.

Pẹ̀lú, àwọn ìlànà wọ̀nyìí l'ọ́kàn, àwa lè wo oríṣiríṣi àyọkà nínú Ìwé Mímọ́ tí ó fi ìwò àkókò ẹgbẹ̀rún ọdún hàn. (Jẹnẹsisi 12:1-3): "Olúwa sì ti wí fun Ábrámù pé, "Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará rẹ, àti kúrò ní ilé bàbá rẹ, sí ilẹ̀ kan tí èmi ó fi hàn ọ́. Èmi ó sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi ó sì bùsi fún ọ, èmi ó sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ ó sì jásí. Èmi ó bùkún àwọn tí ńṣúre fún ọ, ẹnití ń fi ọ́ ré, ni èmi ó sì fi ré; nínú rẹ ni a ó sì ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé."

Ọlọ́run ṣ'èlérí nǹkan mẹ́ta fún Ábráhámù níbì yìí: Ábráhámù yóo ní ọmọ púpọ̀, orílẹ̀-èdè náà yóo ní ilẹ̀, wọn yóò sì máa gbé bẹ̀, ìbùkún àgbáyé yóo wá sí ìran éníyàn láti inú ìran Ábráhámù (àwọn Júù). Nínú ìwé Jẹnẹsisi 15:9-17, Ọlọ́run fi ìdí majẹ̀mú Rẹ̀ pẹ̀lú Ábráhámù múlẹ̀. Nípasẹ̀ ọ̀nà tí a ṣe ṣe èyí, Ọlọ́run fi ojúṣe fún majẹ̀mú náà sórí ara Òun tìkálára Rẹ̀. Àní wípé, kò sí ohunkóhun tí Ábráhámù lè ṣe tàbí kùnà láti ṣe tí ó lè bá majẹ̀mú tí Ọlọ́run báa dá jẹ́. Nínú àyọkà yìí náà, a yan ààlà fún ilẹ̀ tí àwọn Júù yóo padà gbé. Fún àkọsílẹ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí gbèdéke yìí, wo Deutarọnọmi 34. Àwọn àyọkà míìrán tí ó nííṣe pẹ̀lú ìlérí nípa ilẹ̀ ni Deutarọnọmi 30:3-5 àti Esikiẹli 20:42-44.

Nínú ìwé Samuẹli kejì 7:10-17, a rí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pẹ̀lú Ọba Dáfídì. Níbí, Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Dáfídì wípé yóò ní ọmọ púpọ̀, àti wípé láti inú àwọn irú-ọmọ rẹ̀, Ọlọ́run yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ láíláí. Èyí ńtọ́ka sí ìjọba Kristi ní àkókò ẹgbẹ̀rún ọdún àti títí láí. Ó ṣe pàtàkì láti pa àwọn nǹkan wọ̀nyìí mọ́ ní ọkàn wa wípé ìlérí yìí gbọ́dọ̀ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọọ́ àti wípé kò sì tíì ṣẹlẹ̀. Àwọn kan lè gbagbọ́ wípé ìjọba Sọlómọ́nì ní gẹ́lẹ́ ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n àṣìṣe wà pẹ̀lú ìyẹn. Àwọn ilẹ̀ ibi tí Sọlómọ́nì jọba lé kò sí ní abẹ́ Isrẹli mọ́ lónìí, bẹ́ẹ̀ sì ni Sọlómọ́nì kò jọba mọ́ lórí Isrẹli mọ́ lónìí. Rántí wípé Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábráhámù wípé ìran rẹ̀ ni yóò ni ilẹ̀ kan láíláí. Àti wípé, ìwé Samuẹli kejì 7 sọ wípé Ọlọ́run yóò fi ìdí ọba kan múlẹ̀ tí yóò jọba títí ayérayé. Sọlómọ́nì kò lè jẹ́ ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì. Nítorí náà, èyí jẹ́ ìlérí tí kò tíì ṣẹ.

Nísisìyí, pẹ̀lú gbogbo èyí lọ́kàn wa, ṣe àyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí ó wà nínú ìwé Ifihan 20:1-7. Ẹgbẹ̀rún ọdún náà tí à mẹ́nubà lemọ́lemọ́ nínú àyọkà yìí bá ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún ti Kristi lórí ayé mu gẹ́lẹ́. Ṣe ìrántí wípé, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì ńni láti wá sí ìmúṣẹ kò sì tíì wá sí ìmúṣẹ. Ẹ̀kọ́ àkókò tí ó ṣíwájú ẹgbẹ̀rún ọdún rí àyọkà yìí bí èyí wípé ó ńṣàlàyé ìmúṣẹ ìlérí náà ní ọjọ iwájú pẹ̀lú Kristi lórí ìtẹ́ náà. Ọlọ́run dá májẹ̀mú tí kò lẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Ábráhámù àti Dáfídì. Kò sí èyí tí ó ti ṣẹ nínú àwọn májẹ̀mú ná l'ẹ́kúnrẹ́rẹ́ tábí pátápátá. Ìjọba Kristi, ní gẹ́lẹ́ nínú ara ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí májẹ̀mú yìí fi lè wá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ṣ'èlérí wípé wọn yóò ṣẹlẹ̀.

Mímú ọ̀nà kan pàtó láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ bọ́ sí kíkó àwon ẹ̀yà àdìtú wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ jọ papọ̀. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nínú Májẹ̀mú Láíláí nípa ìwásáyé àkọ́kọ́ Jésù wá sí ìmúṣẹ gẹ́lẹ́. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ retí wípé àsọtẹ́lẹ̀ ìpadàbọ̀ kejì nípa Rẹ̀ yóo ṣẹ gẹ́lẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ẹ̀kọ́ àkókò tí ó ṣíwájú ẹgbẹ̀rún ọdún (premillenialism) ni ètò kan ṣoṣo tí ó gbà ìtúmọ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò òpin ayé gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọlé.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ẹ̀kọ́ àkókò tí ó ṣíwájú ẹgbẹ̀rún ọdún?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries