Ibeere
Àwọn wo ni àwọn àpọ́stélì méjìlá (12)/àwọn àpọ́stélì Jésù Kristi?
Idahun
Ọ̀rọ̀ tí ó ńjẹ́ "ọmọ-ẹ̀hìn" ńtọ́kasí ẹni tí ó ńkọ́ ẹ̀kọ́ tàbi ẹni tí ó ńtẹ̀lé ni lẹ́hìn. Ọ̀rọ̀ tí ó ńjẹ́ "àpọ́stélì" túmọ̀ sí "ẹni tí a rán jáde lọ." Nígbàtí Jésù wà ní ilè ayé, àwọn méjìlá tí wọn ńtẹ̀lé E ni a pè ní ọmọ-ẹ̀hìn. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn méjìlá tí wọn ńtẹ̀lé Jésù Kristi kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí Òun sí kọ́ wọn. Lẹ́yìn àjíǹde àti ìgbàsókè Rẹ̀, Jésù rán àwọn ọmọ-ẹ̀hìn jáde láti jẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí Rẹ̀ (Matteu 28:18-20; Iṣe àwọn apọsteli 1:8). Wọ́n wá ńpè wọn ní àwọn àpọ́stélì méjìlá. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jésù ṣì wà ní ayé, àwọn ọ̀rọ̀ "ọmọ-ẹ̀hìn" àti "àpọ́stélì" pàápàá ni a ńlò dípò ara wọn.
Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn/àpọ́stélì méjìlá tí wọn jẹ́ Ojúlówó ni a ṣe àkójọ ní Matteu 10:2-4, "Ìwọ̀nyìí ni orúkọ awọn apọsteli méjìlá náà: ìkíní, Simọni (tí a ńpè ní Peteru) àti arakunrin rẹ Andreu; Jakọbu ọmọ Sibede, àti arakunrin rẹ Johannu; Filipu àti Batilomiu; Tọmọsi àti Matteu agba owó òde; Jakọbu ọmọ Alfeu, àti Taddeu; Simon Selote àti Judasi Iskariọti, tí ó fi I hàn. Bíbélì tún ṣe àkójọ àwọn àpọ́stélì/ọmọ-ẹ̀hìn méjìlá ní Marku 3:16-19 àti Luku 6:13-16. Àgbéyẹ̀wò àwọn àyọkà mẹ́tẹ̀ẹta fihàn àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ nínú àwọn orúkọ náà. Ó jọ wípé Taddeu ni a tún mọ̀ sí "Judasi, ọmọ Jakọbu"(Luku 6:16) àti Lebbeu (Matteu 10:3). Simoni Selote ni a tún mọ̀ ní Simoni ará Kanani (Marku 3:18) Judasi Iskariọti, tí o sẹ́ Jésù ni a rọ́pò pẹ̀lú Matayasi nínú àwọn àpọ́stélì (wo Iṣe àwọn apọsteli 1:20-26). Àwọn olùkọ́ Bíbélì kan wo Matayasi bíi àpọ́stélì kan tí "kò yẹ" tí wọn si gbàgbọ́ wípé Pọ́ọ̀lù ni ẹni tí Ọlọ́run yan láti dípò Judasi Iskariọti gẹ́gẹ́ bíi àpọ́stélì kejìlá.
Àwọn àpọ́stélì/ọmọ-ẹ̀hìn méjìlá jẹ́ ènìyàn lásán tí Ọlọ́run lò ní ọ̀nà àrà. Lára àwọn méjìlá náà ni a ní, apẹja, agbowó òde, àti ajìjà gbara. Àwọn Ìhìnrere ṣe àkọsílẹ̀ ṣísubú nígbàgbogbo, ìlàkàkà, àti iyèméjì àwọn ọkùnrin méjìlá wọ̀nyìí tí wọn tẹ̀lé Jésù. Lẹ́yìn tí wọ́n ní ìrírí àjíǹde àti ìgbàsókè Jésù sí ọ̀run, Ẹ̀mí Mímọ́ yí ayé àwọn àpọ́stélì/ọmọ-ẹ̀hìn padà sí àwọn ọkùnrin Ọlọ́run tí ó lágbára tí wọn yí ayé pada (Iṣe àwọn apọsteli 17:6). Kínni àyípadà náà? Àwọn àpọ́stélì/ọmọ-ẹ̀hìn méjìlá "ti wà pẹ̀lú Jésù" (Iṣe àwọn Apọsteli 4:13). Kí a sọ irú rẹ̀ fún wa!
English
Àwọn wo ni àwọn àpọ́stélì méjìlá (12)/àwọn àpọ́stélì Jésù Kristi?