settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé Ìpin méjì ni a ní tàbí mẹ́ta? "Ǹjẹ́ ara, ọkàn, àti ẹ̀mí- tàbí — ara, ọkàn-ẹ̀mí la jẹ́?

Idahun


Jẹnẹsisi 1: 26-27 tọ́ka sí wípé Ọlọ́run dá ìran ènìyàn yàtọ̀ gédégbé sí gbogbo àwọn ẹ̀dá míìrán. Ìwé Mímọ́ kọ́ wa kedere wípé ènìyàn yẹ kí ó ní ìrírí ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí náà, ni Òun ṣe dá wa ní ìrẹ́pọ̀ agbọn tí ó ṣe gbámú (fi ojú rí) àti èyí tí kò ṣe gbámú (abẹ̀mí) (Oniwasu 12:7; Matteu 10:28; 1 Kọrinti 5:5; 2 Kọrinti 4:16; 7:1, Jakọbu 2:26). Ipa tí ó ṣé e gbámú ní pàtó jẹ́ èyí tí ó ṣe kókó tí ó wà fún ìgbá díẹ̀: àgọ́ ara. Agbọn tí kò ṣé e gbámú kò ṣe kókó: ọkàn, ẹ̀mí, ọpọlọ, ìpínnu, ẹ̀rí ọkàn, èrò,ìmọ̀lára, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn èyí wà fún ìgbà àìnípẹ̀kun lẹ́yìn tí àgọ́ ara bá ti kú.

Gbogbo ènìyàn ni ó ní àbùdá tí ó ṣé e gbámú (fi ojú rí) àti tí kò ṣe gbámú (ẹ̀mí). Ẹnìkọ́kan ni ó ní àgọ́ ara. Ṣùgbọ́n, àríyànjiyàn máa ńwà lórí àbùdá èyí tí kò ṣe kókó, tí a kò lè fi ojú rí. Kínni Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyìí? Jẹnẹsisi 2:7 sọ wípé a dá ènìyàn ní "alààyè ọkàn"(KJV). Numeri 16:22 pe Ọlọ́run ní "Ọlọ́run ti ẹ̀mí gbogbo ẹran ara". Ìwé òwe sọ fún wa wípé, "Ju gbogbo ohun ìpamọ́, pa aya rẹ mọ́, nítoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun iye," èyí tí ó ńtọ́ka sí wípé ọkàn ( kìí ṣe iṣan àyà) ṣe pàtàkì sí ìfẹ́ àti ìhùwàsí ènìyàn. Nínú ìṣe àwọn Apọsteli 23:1, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí wípé ẹ̀rí ọkàn jẹ́ ipa ọkàn tí ó maá d'áwaláre tàbí d'áwalẹ́bi. Romu 12:2 sọ nípa agbára ìparadà ọkàn tí a ti sọ d'ọ̀tun. Àwọn ẹsẹ wọ̀nyìí, àti ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀, sọ nípa àwọn agbọn àbùdá ẹ́mì ènìyàn. A jẹ́ àfọwọ́sowọ́ ìdàpọ̀ àbùdá tí a lèrí àti èyí tí a kò lè rí.

L'ọ́nà kan, ọkàn, ẹ̀mí, ìmọ̀lára, ẹ̀rí ọkàn, ìfẹ́ ati èrò sopọ̀, wọ́n sì wọ inú ara wọn. Àmọ́, ọkàn-ẹ̀mí náà jẹ́ àkójọpọ̀ gbogbo agbọn ènìyàn tí kò ṣe é gbámú. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, ṣé ènìyàn jẹ́ ẹ̀yà méjì ("pín sí ọ̀nà méjì") tàbí ẹ̀yà mẹ́ta ("pín sí ọ̀nà mẹ́ta")? Ní ọ̀rọ̀ míìrán, ṣé ènìyàn pín sí ipa méjì (ara àti ọkàn-ẹ̀mí), tàbí ṣé ènìyàn pín sí ipa mẹ́ta (ara, ọkàn, àti ẹ̀mí)? Kò ṣeé ṣe, kí á kàn tẹ̀le bẹ́ẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ti ní ìyàtọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ́rùn ọdún, wọn kò sì tíì fi ẹnu kò lórí èyí tí gbogbo wọn gbà wípé ó jẹ́ òtítọ́.

Àwọn tí ó gba wípé Ìwé Mímọ́ kọ́ wa wípé ènìyàn pín sí ipa méjì, wọn rí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìpín méjì: ara kan àti ẹ̀mí kan. Àfojúsùn méjì ni ó wà nípa wípé ènìyàn pín sí ìpin méjì. Àfojúsùn àkọ́kọ́ ni wípé ènìyàn jẹ́ àpapọ̀ ara àti ẹ̀mí tí ó parapọ̀ di alààyè ọkàn. Ọkàn ènìyàn kan jẹ́ ẹ̀mí àti ara tí o wà papọ̀ láti di ènìyàn kan. Jẹnẹsisi 2:7; Numeri 9:13; Orin Dafidi 16:10, 97:10 àti Jona 4:8 jẹ́ àtìlẹyìn fún àfojúsùn yìí. Àfojúsùn yìí tẹnumọ́ wípé ọ̀rọ̀ Hébérù náà tíí ṣe nephesh nínú àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyìí tọ́kasi àkópọ̀ (apapọ̀) ọkàn, alààyè ènìyàn, ìyè/ayé, tàbí ẹ̀dá— tíí ṣe, apapọ̀ ènìyàn (ọkàn) tíí ṣe ara àti ẹ̀mí. A kíyèsí wípé, ìgbàtí Bíbélì bá sọ nípa ìpínyà ruach ("èémí, afẹ́fẹ́, tàbí ẹ̀mí") ba kúrò lára, ènìyàn náà ti túká (kán kúrò) —di òkú (Oniwasu 12:7; Orin Dafidi 104:29; 146:4).

Àfojúsùn kejì tí ó sọ nípa wípé ènìyàn pín sí ipa méjì ni wípé ẹ̀mí àti ọkàn jẹ́ ohùn kan pẹ̀lú orúkọ méjì tí ó yàtọ̀. Àfojúsùn yìí tẹnumọ́ òtítọ́ wípé ẹ̀mí àti ọkàn ni a ńsábà lò wọnú ara wọn (Luku 1:46- 47; Isaiah 26:9; Matteu 6:25; 10:28; 1 Kọrinti 5:3,5), a sì gbọdọ̀ ní òye wípé wọn jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a le fi rọ́pò ara wọn tí ó sì túmọ̀ sí òdodo nínú ẹ̀mí tí ó wà nínú ènìyàn kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, ipò tí ó sọ nípa wípé ènìyàn pín sí ipa méjì, wípé ènìyàn jẹ́ ìpín méjì. Ènìyàn jẹ́ ara tàbí ẹ̀mí, tí ó jẹ́ ọkàn kan, tàbí ara kan àti ọkàn- ẹ̀mí.

Àwọn tí ó gba wípé Ìwé Mímọ́ kọ́ wa wípé ènìyàn pín sí ipa mẹ́ta, rí ènìyàn gẹ́gẹ́ bíi ìpín mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀: ara, ọkàn, àti ẹ̀mí. Wọ́n tẹnumọ́ Tẹssalonika kínní 5:23 àti Heberu 4:12, tí ó jọ wípé ó ṣe ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀mí àti ọkàn. Àwọn aláfojúsùn tí ó sọ nípa wípé ènìyàn pín sí ipa méjì ṣe àtakò wípé tí Tẹssalonika kínní 5:23 bá ńkọ́ nípa àfojúsùn wípé ènìyàn pín sí ipa mẹ́ta, ṣe Marku 12:30 kọ́ wa wípé ènìyàn pín sí ipa mẹ́rin lábẹ́ẹ ìlànà kańnáà?

Ṣé ó ṣe pàtàkì kí á fẹnukò láàrin wípé ènìyàn pín sí ìpín méjì tàbí mẹ́ta? Kò ríì bẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n, ààbọ̀ ọ̀rọ̀ tó fún ọmọlúwàbí. Ṣùgbọ́n àwọn aláfojúsùn onípa mẹ̀ta ṣe àlàyé àjọṣepọ̀ ipa ènìyàn, àwọn kan ti ṣini lọ́nà láti kọ́ wípé ẹ̀mí nìkan ni Ọlọ́run maá ńbá sọ̀rọ̀, kìí ṣe ọpọlọ wa. Ní ìlànà pẹ̀lú àṣìṣe yìí, awọn ìjọ kan lo aláfojúsùn onípa mẹ̀ta láti sọ wípé ó ṣe é ṣe kí ẹ̀mí èṣù gbé Kristiẹni wọ̀. Nítorí wọ́n rí ẹ̀mí àti ọkàn bíi ipa ọ̀tọ̀tọ̀ nínú agbọn ayé Kristiẹni èyí tí kò ṣe gbámú, wọ́n gbà wípé Ẹ̀mí Mìmọ́ lè máa gbé apá kan kí ẹ̀mí èṣù máa gbé apá kejì. Ìṣòro ni èyí jásí nítorí kò bá bíbélì mu láti sọ wípé Ẹ̀mí Mìmọ́ àti ẹ̀mí èṣù lè jọ gbé papọ̀ nígbà kańnáà.

Láìnì fiṣe bóyá Kristiẹni kan gbàgbọ́ nínú ìpín méjì tàbí ìpín mẹ́ta, jẹ́ èyítí ó fi gígúnrégé òye Ìwé Mìmọ́ hàn, a lè darapọ̀ pẹ̀lú olórin láti máa yin Ọlọ́run wípé: "Èmi ó yìn ọ́; nítorí tẹ̀rù-tẹ̀rù àti tìyanu-tìyanu ni a dá mi: ìyanu ni iṣẹ́ Rẹ; èyí ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú " (Orin Dafidi 139:14).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé Ìpin méjì ni a ní tàbí mẹ́ta? "Ǹjẹ́ ara, ọkàn, àti ẹ̀mí- tàbí — ara, ọkàn-ẹ̀mí la jẹ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries