settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa àwọn ańgẹ́lì?

Idahun


Àwọn ańgẹ́lì jẹ́ àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí tí enìkọ̀ọ̀kan wón ní ọgbọ́n, ìmọ̀lára, àti ìfẹ́. Èyí jẹ́ òtítọ́ fún irúfẹ́ ańgẹ́lì méjèèjì bóyá àwọn ańgẹ́lì rere tàbí búburú (àwọn ẹ̀mí èṣù). Àwọn ańgẹ́lì ní ọgbọ́n (Matteu 8:29; 2 Kọrinti 11:3; 1 Peteru 1:12), wọn máa ńfi ìmọ̀lára hàn (Luku 2:13, Jakọbu 2:19; Ifihan 12:17,) wọ́n sì tún máa ńse ìfẹ́ inú wọn (Luku 8:28-31; 2 Timoteu 2:26; Juda 6). Àwọn ańgẹ́lì jẹ́ àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí (Heberu 1:14), tí kò ní àgọ́ ara tòtọ́ọ́. Lótìtọ́ọ́ wọn kò ní àgọ́ ara, síbẹ̀ wọ́n ní àbùdá ènìyaǹ.

Nítorípé wọ́n jẹ́ ẹ̀dá tí a dá, ìmọ̀ wọn ni gbèdéke. Èyí túmọ̀ sí wípé wọn kò mọ ohun gbogbo tán bíi Ọlọ́run (Matteu 24:36). Ó jọ wípé wọ́n lọ́gbọ́n ju ènìyàn lọ, ṣùgbọ́n, ó lè jẹ̀ nítorí ìdí mẹ́ta. Àkọ́kọ́, a dá ańgẹ́lì ní ìlànà ìṣẹ̀dá tí ó ga ju ti ènìyàn lọ. Nítorínáà, wọ́n ní ìmọ̀ tí ó ga gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dá wọn. Ẹ̀kejì, àwọn ańgẹ́lì máa ńjíròrò lórí Bíbélì àti àgbáyé dáradára ju ènìyàn lọ, wọ́n a si máa ni ìmọ̀ láti ibẹ̀ (Jakọbu 2:19; Ifihan 12:12). Ẹ̀kẹta, àwọn ańgẹ́lì máa ńní ìmọ̀ nípa wíwo ìṣe ènìyàn fún ìgbà pípẹ́. Ní ìdàkejì ti ènìyàn, àwọn ańgẹ́lì kò nílò láti ṣe àṣàrò lóri ohun tí ó ti kọjá lọ; àwọ́n ti làá kọjá nì yẹn. Nítorínáà, wọ́n mọ bí àwọn yókù ṣe hùwà tàbí hùwà sí ìṣẹ̀lẹ̀, wọ́n sì le ṣọ dájúdájú bí ènìyàn yóò ṣe hùwà ní irú ìgbà bẹ́ẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n ní èròngbà ti wọn, bí ẹ̀dá míìrán, wọ́n fi ara wọn jìn fún ìfẹ̀ Ọlọ́run. Ọlọ́run rán àwọn ańgẹ́lì rere sí àwọn onígbàgbọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ (Heberu 1:14). Èyí ni àwọn iṣẹ́ tí Bíbélì sọ nípa àwọn ángẹ́lì:

Wọ́n máa ńyin Ọlọ́run (Orin Dafidi 148:1-2; Isaiah 6:3). Wọ́n máa ńjọ́sìn fún Ọlọ́run (Heberu 1:6; ifihan 5:8-13). Wọ́n máa ńyọ̀ nínú ohun tí Ọlọ́run ṣe (Jobu 38:6-7). Wọ́n máa ńsin Ọlọ́run (Orin Daafidi 103:20; Ifihan 22:9). Wọ́n máa ńfarahàn níwájú Ọlọ́run (Jobu 1:6; 2:1). Wọ́n jẹ́ ohun-èlò fún ìdájọ́ Ọlọ́run (Ifihan 7:1; 8:2). Wọ́n máa ńmú ìdáhùn wá sí ẹ̀bẹ̀ àdúrà (Iṣe àwọn Apọsteli 12:5-10). Wọ́n máa ńṣe ìrànlọ́wọ́ nínú ìjèèrè ọkàn fún Kristi (Iṣe àwọn Apọsteli 8:26; 10:3) Wọ́n a máa ṣe àrídájú ìlànà, iṣẹ́ àti ìjìyà Kristiẹni (1 Kọrinti 4:9;11:10, Efesu 3:10; 1 Peteru 1:12). Wọn a máa gbaniníyànjú nígbà ìpọ́njú (Iṣe àwọn Apọsteli 27:23-24). Wọn a máa mójútó àwọn olódodo ní ìgbà ikú (Luku 16:22).

Ańgẹ́lì jẹ́ ẹ̀dá alàyè tí ó dá yàtọ̀ gédégbé sí ọmọ ènìyàn. Ẹ̀dá ènìyàn kìí di ańgẹ́lì lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n bá kú. Ańgẹ́lì ò le di ẹ̀dá ènìyàn, wọn kò tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn rí. Ọlọ́run dá àwọn ańgẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Òun ṣe dá ìran ènìyàn. Bíbélì kò tilẹ̀ sọ ní ibì kankan wípé a dá àwọn ańgẹ́lì ní àwòrán tàbí ìrí Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dá ènìyàn (Jẹnẹsisi 1:26). Àwọn ańgẹ́lì jẹ́ ẹ̀dá abẹ̀mí títí dé àyè kan, tí wọ́n lè gbé àgọ́ ara wọ̀. Ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ ẹlẹ́ran ara ni gbòógì, ṣùgbọ̀n pẹ̀lú abala ti ẹ̀mí. Ohun kan tí ó ṣe pàtàkì jù tí a lè kọ́ lára àwọn ańgẹ́lì ni ìgbọràn lọ́gan láì bá Ọlọ́run wíjọ́ sí àwọn àṣẹ Rẹ̀.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa àwọn ańgẹ́lì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries