Ibeere
Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀bùn ìyanu Ẹ̀mí wà fún òde òní?
Idahun
Èkínní, ó ṣe pàtàkì láti damọ̀ wípé èyí kìí ṣe ìbéèrè bóyá Ọlọ́run ṣi ńṣe iṣẹ ìyanu lóde òní. Yóò jẹ́ ìjẹ́rì òmùgọ̀ àti èyí tí kò bá Bíbélì mu láti wípé Ọlọ́run kò wo àwọn ènìyàn sàn, bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, tí kò sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti ìṣẹ́ ìyanu lóde òní. Ìbéèrè náà ni wípé bóyá awọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí, tí a ṣe àpèjúwe ní Kọrinti kínní 12–14 ṣì ńṣiṣẹ́ lóde òní. Èyí kìí tún ṣe ìbéèrè wípé báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe le fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ìyanu. Ìbéèrè náà ni wípé bóyá Ẹ̀mí Mímọ́ ṣi ńpín àwọn ẹ̀bùn ìyanu lóde òní. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwa wòó wípé Ẹ̀mí Mímọ́ ṣì ní òmìnira láti fi àwọn ẹ̀bùn fún ni gẹ́gẹ́bí ìfẹ Rẹ̀ (1 Kọrinti 12:7-11).
Nínú ìwé Ìṣe àwọn Apọsteli àti àwọn Ẹpistili, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu ni a ṣe nípasẹ̀ àwọn apọsteli àti àwọn tí ó súnmọ́ wọn. Pọ́ọ̀lù fún wa ni ìdí fún èyí: "Nítòótọ́ a ti ṣe iṣẹ́ àmi Apọsteli láàrín yín nínú sùúrù gbogbo, nínú iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ agbára" (2 Kọrinti 12:12). Bí gbogbo onígbàgbọ́ bá ní agbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nígbà náà àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu kò lè jẹ́ àmì láti dá Apọsteli mọ̀. Ìṣe àwọn Apọsteli 2:22 sọ fún wa wípé nípasẹ̀ "àwọn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmi" ni a fi ṣe "òǹtẹ̀ lu" Jésù. Bákannáà, a dá àwọn apọsteli mọ̀ bíi ìráńsẹ́ tòótọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n ṣe. Ìṣe àwọn Àpọsteli 14:3 ṣe àpèjúwe ìfìráńṣẹ́ ìhìnrere bíi èyí "tí a ńjẹ̀rísí" nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu Pọ́ọ̀lù àti Bánábà.
Àwọn orí 12–14 ti Kọrinti kínní ńsọ ní pàtó nípa kókó ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí. Láti ìnú ọ̀rọ̀ yẹn, ó jọ wípé a má ńfún àwọn Kristiẹni "lásán" ní àwọn ẹ̀bùn ìyanu (12:8-10, 28-30). A kò sọ fún wa bí èyí ṣe wọ́pọ̀ sí. Láti ohun tí àwa kọ́ l'ókè, wípé a dá àwọn apọsteli mọ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, yóò jọ wípé àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu tí a fún àwọn Kristiẹni "lásán" jẹ́ àkànṣe, èyítí kò wọ́pọ̀, Yàtọ̀ sí àwọn apọsteli àti àwọn tí ó súnmọ́ wọn, Májẹ́mú Titun kò ṣe àpèjúwe níbì kankan àwọn ẹnikankan ní pàtó tí wọn lo àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu ti Ẹ̀mí.
Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ wípé ìjọ àkọ́kọ́ kò ní Bíbéli tí ó pé, bí àwa ṣe ni lóòní (2 Timoteu 3:16-17). Nítorínáà, àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, ìmọ̀, ọgbọ́n, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ wúlò fún àwọn Kristiẹni àkọ́kọ́ láti lè jẹ́ kí wọn mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọn ṣe. Ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ gba àwọn onígbàgbọ́ láàyè láti le sọ òtítọ́ àti ìfihàn titun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nísìnyí tí ìfihàn Ọlọ́run ti pé nínú Bíbélì, àwọn ẹ̀bùn "ìfihàn" ni a kò nílò mọ́, ó kéré jù ní ìwọ̀n bí a ṣe nílò wọn nínú Májẹ́mú Titun.
Ọlọ́run ńwo àwọn ènìyàn sàn ní ọ̀nà ìyanu l'ójojúmọ́. Ọlọ́run ṣì ńsọ̀rọ̀ lóòní,yálà pẹ̀lú ohùn tí a ńgbọ́, nínú ọkàn wa, tàbi nípa títẹ nǹkankan mọ́ ni lọ́kàn tàbí nípa ìmọ̀lára. Ọlọ́run ṣì ńṣe àwọn ìyanu, àti ìṣẹ́ àmì, tí Òun si ńṣe ìṣẹ́ yìí nípasẹ̀ Kristiẹni kan. Ṣùgbọ́n, àwọn nǹkan wọ̀nyìí lè má jẹ́ àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu Ẹ̀mí. Ète ní pàtó fún àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu ni láti jẹ́rìsí wípé ìhìnrere jẹ́ òtítọ́ àti wípé àwọn apọsteli jẹ́ ìráńsẹ́ tòótọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì kò sọ gbangba wípé àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu ti dáwọ́ dúró, ṣùgbọ́n ó fi ìpìlẹ̀ fún ìdí ti wọn fi lè má ṣẹlẹ̀ ní bí wọn ṣe ṣẹlẹ̀ àti bí a ṣe se àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Májẹ̀mú Titun.
English
Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀bùn ìyanu Ẹ̀mí wà fún òde òní?