Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa àwọn ẹ̀mí èṣù?
Idahun
Àwọn ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú ni àwọn ẹ̀mí èṣù, bí Ìfihàn 12:9 ṣe tọ́kasi: "A si le dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npe ni Èṣù, tabi Satani tí ó ńtan gbogbo aiye jẹ. A si lé e si ile aiyé, a si le àwọn angeli rẹ̀ jade pẹ̀lú rẹ̀." Ìṣubú Sàtánì láti ọ̀run ni a ṣe àpèjúwe pẹ̀lú àmì àlàyé ní inú Isaiah 14:12–15 àti Esíkiẹli 28:12–15. Nígbà tí Sàtánì ṣubú, Ó mú ìdámẹ́ta àwọn ańgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìfihàn 12:4 ṣe kọọ́ sílẹ̀. Júdà ẹṣẹ kẹfà tún mẹ́nuba àwọn ańgẹ́lì tí ó ti dẹ́sẹ̀. Ní ìlànà pẹ̀lú bíbélì, àwọn ẹ̀mí èṣù ni àwọn ańgẹ́lì tí ó ṣubú pẹ̀lú Sàtánì tí ó ṣe lòdì sí Ọlọ́run.
Díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀mí èṣù yìí "ni o pamọ́ nínú ẹ̀wọ̀n àínípẹ́kun nísàlẹ̀ òkùnkùn de ọjọ́ ìdájọ́" (Juda 1:6) fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn míìrán ńrìn kiri, a sì pè wọ́n ní "àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí àti . . . àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run" ní Efesu 6:12 (Kolosse 2:15). Àwọn ẹ̀mí èṣù náà sìí ńtẹ̀lé Sàtánì olórí wọn láti kọjú ìjà sí àwọn áńgẹ́lì mímọ́ ní èròǹgbà láti da ète Ọlọ́run rú àti láti dènà àwọn ènìyàn Ọlọ́run (Daniẹli 10:13).
Àwọn ẹ̀mí èṣù, gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀mí, ní agbára láti máa gbé inú àgọ́ ara. Ẹ̀mí èṣù tí ó ńgbé ni wọ̀ ńwáyé nígbàtí ẹ̀mí èṣù bá ńṣe ìṣàkóso ara ẹni náà pátápátá. Èyí kò lè ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Ọlọ́run, nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ ńgbé inú ònígbàgbọ́ nínú Kristi (1 Johannu 4:4).
Jésù, nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ láyé, bá ẹ̀mí èṣù púpọ̀ pàdé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sí èyí tí a lè fi ṣe àfiwé Agbára Kristi: "wọ́n gbé ọ̀pọ́lọpọ̀ àwọ́n ẹniti o ní ẹ̀mí èṣù wá sọ́dọ̀ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè àwọn ẹ̀mí náà jáde "(Matteu8:16). Àṣẹ tí Jésù ní lórí àwọn ẹ̀mí èṣù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí wípé ọmọ Ọlọ́run ni nítòótọ́ (Luku 11:20). Àwọn ẹ̀mí èṣù tí ó bá Jésù pàdé mọ ẹni tí ó jẹ́, wọ́n sì bẹ̀rù Rẹ̀: "Kíní ṣe tàwa-tìrẹ, ìwọ Ọmọ Ọlọrun? [àwọn ẹ̀mí èṣù náà] kígbe Ìwọ́ wá láti wá da wa lóró ki ó tó tó àkókò? (Matteu 8:29). Àwọn ẹ̀mí èṣù náà mọ̀ wípé ìgbẹ̀yìn wọn yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdálóró.
Sàtánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù wá ńba iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́, wọ́n sì ńtan ẹni yòówù jẹ (1 Peteru 5:8; 2 Kọrinti 11:14–15). Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí náà ni ẹ̀mí búburú (Matteu 10:1), ẹ̀mí àìmọ́ (Marku 1:27), ẹ̀mí irọ́ (1 Àwọn Ọba 22:23), àti Àwọn ańgẹ́lì Sàtánì (Ifihan 12:9). Sàtánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù ńtan ayé jẹ (2 Kọrinti 4:4), polongo ẹ̀kọ́ òdì (1 Timoteu 4:1), tako àwọn Kristiẹni (2 Kọrinti 12:7, 1 Peteru 5:8), wọ́n síì gbógun ti àwọn ańgẹ́lì mímọ́ (Ifihan 12:4-9).
Àwọn ẹ̀mí èṣù/ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú jẹ́ ọ̀ta Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ ọ̀ta tí a ti ṣẹ̀gun. "O si ti ja àwọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ ayọ iṣẹgun lori wọn loju ọna, o si kan a mọ agbelebu" (Kolosse 2:15). Bí a bá jọ̀wọ́ ayé wa fún Ọlọ́run tí a sì kọjú ìjà sí èsù, a kò ní ohunkóhun láti bẹ̀ru. "Ẹnití ó nbẹ ninu yín tóbi ju ẹnití ó nbẹ ninu ayé lọ "(1 Johannu 4:4)
English
Kínni Bíbélì sọ nípa àwọn ẹ̀mí èṣù?