Ibeere
Àwọn wo ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ọmọbìnrin ènìyàn nínú ìwé Jẹnẹsisi 6:1-4?
Idahun
Jẹnẹsisi 6:1-4 tọ́ka sí àwọn ọmọ Ọlọ́run àti ọmọbìnrin ènìyàn. Oríṣíríṣi àbá nípa ẹni tí àwọn ọmọ Ọlọ́run jẹ́ àti ìdí tí àwọn ọmọ tí wọ́n bí nípasẹ̀ ọmọbìnrin ènìyàn ṣe dàgbà láti jẹ́ ìran àwọn òmìrán (èyí tí ó dàbí pé Nẹ́fílímù tọ́ka sí).
Àfojúsùn mẹ́ta tí ó ṣe kókó lórí ẹni tí àwọn ọmọ Ọlọ́run jẹ́ ni 1) pé ańgẹ́lì tí ó ṣubú ni wọ́n, 2) adarí alágbára ènìyàn ni wọ́n, tàbí 3) wọ́n jẹ́ ìran Sẹ́tì mímọ́ tí wọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn ìran búburú Káínì ní ìgbeyàwó. Àtìlẹyìn fún àfojúsùn àkọ́kọ́ ni òtítọ́ wípé nínú Májẹ̀mú Láíláí"àwọn ọmọ Ọlọ́run" máa túmọ̀ sí ańgẹ́lì ní ìgbà gbogbo (Jobu 1:6; 2:1; 38:7). Ìṣòro kan tí ó lè ní ni pé ìwé Matteu 22:30, fihàn wípé ańgẹ́lì kìí gbéyàwó. Bíbélì kò fún wa ní ìdí láti gbàgbọ́ wípé ańgẹ́lì ní ẹ̀dà tàbí agbára láti bí. Àwọn Àfojúsùn méjì yókù kò ní ìṣòro yìí.
Àìlera àfojúsùn ìkejì àti ìkẹta ni wípé àwọn ọmọkùnrin ènìyàn lásán tí wọ́n fẹ́ ọmọbìnrin ènìyàn lásán kò rọ̀mọ́ ìdí tí àwọn ọmọ wọn ṣe jẹ́ "òmìrán" tàbí "akinkanjú ìgbanì, àwọn ènìyàn tí ó gbajúgbajà". Síwájú si, kílódé tí Ọlọ́run fi pinnu láti fi omi pa ayé rẹ́ (Jẹnẹsisi 6:5-7), nígbàtí Ọlọ́run kò pèé ní èèwọ̀ fún alágbára ènìyàn ọkùnrin láti gbéyàwó pẹ̀lú ọmọbìnrin ènìyàn lásán tàbí ìran Káínì? Ìdájọ́ Jẹnẹsisi 6:5-7 tí ńbọ̀ nííṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ nínú Jẹnẹsisi 6:1-4. Ìgbéyàwó àìtọ́, ìwọ̀sí láàrin àwọn ańgẹ́lì tí ó ṣubú pẹ̀lú ọmọbìnrin ènìyàn ni ó jọ wípé ó le dá ìdájọ́ líle bayìí láre.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe pe àkíyèsí tẹ́lẹ̀ wípé àìlera àfojúsùn kínní ni wípé ìwé Matteu 22:30 sọ wípé "Nítorípé li àjíǹde òkú wọn ki gbéyàwó, ṣugbọn wọn dabi awọn ańgẹ́lì Ọlọ́run li ọ̀run." Ṣùgbọ́n, àyọkà náà kò sọ wípé "àwọn ańgẹ́lì kò lágbára láti lè gbéyàwó." Ṣùgbọ́n, ó tọ́ka si wípé ańgẹ́lì ò kí ńgbéyàwó. Lẹ́kèejì, ìwé Matteu 22:30 ńtọ́ka si "àwọn ańgẹ́lì lọ́run." Kò tọ́ka si àwọn áńgẹ́lì tí ó ti ṣubú, tí wọn ò bìkítà sí àṣẹ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ńwá ọ̀nà láti ba ètò Ọlọ́run jẹ́. Òtítọ́ pé àwọn ańgẹ́lì mímọ́ Ọlọ́run kìí gbéyàwó tàbí ní ìbálòpọ̀ kò sọ wípé bẹ̀ẹ́ lórí fún sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.
Àfojúsùn 1) ni ipò yìí jọmọ́ jù. Bẹ́ẹ̀ni, ó jẹ́ ohun tí ó dùn "tí ó tako ara wọn" wípé àwọn ańgẹ́lì kò ní akọ-n-bábo àti láti sọ wípe "ọmọ Ọlọ́run" jẹ́ àwọn ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú tí wọ́n bí ọmọ pẹ̀lú ọmọbìnrin ènìyàn. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn ańgẹ́lì jẹ́ ẹ̀dà abẹ̀mí (Heberu 1:14), wọn lè gbé àgọ́ ara ènìyàn wọ̀ (Marku 16:5). Àwọn ọkùnrin Sódómù àti Gòmórà fẹ́ bá àwọn ańgẹ́lì méjì tí ó wà pẹ̀lú Lọ́tì lòpọ̀ (Jẹnẹsisi 19:1-5). Ó jọ òtítọ́ wípé àwọn ańgẹ́lì lè gbé àgọ́ ara ènìyàn wọ̀, débi wípé wọ́n le bí irú ènìyàn tàbí irú ara wọn. Kílódé tí àwọn ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú náà kò ṣe ṣe èyí mọ́ lemọ́lemọ́? Ó dà bí ẹni wípé Ọlọ́run ti ti àwọn ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú tí wọ́n hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ búrubú yìí, mọ́ ẹ̀wọ̀n kí àwọn ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú míìrán má bàa ṣe irú ẹ̀ (gẹ́gẹ́ bíi àpèjúwe Juda 6). Àwọn olùtúmọ̀ Hébérù ní ṣàájú ati àkọsílẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí kìí ṣe òtítọ́ àti àwọn àkọsílẹ̀ tí kìí ṣe ti Bíbélì tí a ńpè ni ti Bíbélì fẹnukò nípa àfojúsùn tó sọ wípé ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú ni "àwọn ọmọ Ọlọ́run" tí a sọ nípa nínú Jẹnẹsisi 6:1-4. Èyí fi òpin si àríyànjiyàn yìí. Ṣùgbọ́n, àfojúsùn tó sọ wípé Jẹnẹsisi 6:1-4 nííṣe pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì tí ó ti ṣubú àti ọmọbìnrin ènìyàn ní ìpìlẹ̀ àyálò, gírímà àti ìtàn tó dúró re.
English
Àwọn wo ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ọmọbìnrin ènìyàn nínú ìwé Jẹnẹsisi 6:1-4?