Ibeere
Kínni ó túmọ̀ sí wípé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run?(Jẹnẹsisi 1:26-27)?
Idahun
Ní ọjọ́ tí ó parí ìṣẹ̀dá, Ọlọ́run wípé, "Jẹ́ ki a dá ènìyàn li àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí ìrí wa" (Jẹnẹsisi 1:26). Bẹ́ẹ̀ni, ó parí iṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú "ọwọ́ òun tìkalára Rẹ̀". Ọlọ́run mọ Ádámù láti inú erùpẹ̀, ó sì fun ní ẹ̀mí nípa pínpín èémí Rẹ̀ (Jẹnẹsisi 2:7). Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀, ìran ènìyàn dá yàtọ̀ nínú gbogbo iṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá, ó ní ara tí ó ṣé e gbámú àti ọkàn/ ẹ̀mí tí kò ṣé e gbámú.
Ní ọ̀nà tó rọrùn jùlọ, níní "àwòrán" tàbí "ìrí" Ọlọ́run túmọ̀ sí wípé a jọ Ọlọ́run. Ádámù kò jọ Ọlọ́run nípa ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ wípé "ẹ̀mí ni Ọlọ́run" (Johannu 4:24), nítorí náà kò ní àgọ́ ara. Ṣùgbọ́n, àgọ́ ara Ádámù fi ògo Ọlọ́run hàn, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ wípé, a dáa pẹ̀lú àlàáfíà pípé, ikú kò sì nípá lórí rẹ̀.
Àwòrán Ọlọ́run (Latin: imago dei) túmọ̀ sí abala tí kò ṣé e gbámú nínú ayé ènìyàn. Ó ya ènìyàn sọ́tọ̀ kúrò ni ìgbé-ayé ẹranko, ó kà wọ́n yẹ fún ìjọba tí Ọlọ́run pinnu ní lọ́kàn wípé kí wọ́n ní lórí ayé (Jẹnẹsisi 1:28), ó sì fún wọ́n láyè láti bá Ẹlẹ́dàá wọ́n sọ̀rọ̀. Ó jẹ́ ìrí ní lérò, ní ìwà àti l'áwùjọ.
Ní ti èrò, a dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ tó le dánúrò. Lọ́nà míràn, ènìyàn le ronú, ó sì lè yàn. Èyí jẹ́ ìfihàn ọgbọ́n àti òmìnira Ọlọ́run. Nígbàkúùgbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀dá ẹ̀rọ kan, kọ ìwé, kun àwòrán ilẹ̀, gbádùn iṣẹ́ ọwọ́, ṣe ìṣirò, tàbí fún ohun ọ̀sìn ní orúkọ, irú ẹni bẹ́ẹ̀ l'ọ́kùnrin tàbí l'óbìnrin ńpolongo òtitọ́ wípé àwòrán Ọlọ́run la dá wa.
Ní ìwà, a dá ènìyàn nínú òdodo àti láìlẹ́bi rárá, èyítí ó jẹ́ ìfihàn ìwà mímọ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run wo ohun gbogbo tí Òun dá (pẹ̀lú ènìyàn) ó sì sọ wípé wọ́n "dáradára ni" (Jẹnẹsisi 1:31). Ẹ̀rí ọkàn wa tàbí " làákàyè" jẹ́ ààmì ipò àkọ́kọ́ náà. Nígbàkúùgbà tí ẹnìkan bá kọ òfin kan, yípadà kúrò nínú ibi, gbé ìwà rere lárugẹ, rò wípé òun jẹ̀bi, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ l'ọ́kùnrin tàbí l'óbìnrin ńfìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwòrán Ọlọ́run la jẹ́.
Níti ìhùwàsí l'áwùjọ, a dá ènìyàn fún ìbáṣepọ̀. Èyí fi àbùdá mẹ́talọ̀kan Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ hàn. Ní Édẹ́nì, ìbáṣepọ̀ àkọ́kọ́ tí ènìyàn ní jẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run (Jẹnẹsisi 3:8 tọ́ka sí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run), Ọlọ́run dá obìnrin àkọ́kọ́ nítorí "kò dára kí ọkùnrin náà ó nìkàn má a gbé" (Jẹnẹsisi 2:18). Gbogbo ìgbà tí ènìyàn bá ṣe ìgbéyàwó, ní ọ̀rẹ́, dìmọ́ ọmọdé, tàbí lọ sí ilé ìjọsìn, irú ẹni bẹ́ẹ̀ l'ọ́kùnrin tàbí l'óbìnrin ńpolongo òtitọ́ wípé a dáwa gẹ́gẹ́ bí ìrí Ọlọ́run.
Ara jíjẹ́ àwòrán Ọlọ́run ni wípé Ádámù ní agbára láti yàn bí ó ti wùú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, àbùdá òdodo ni a fún wọn, Ádámù àti Éfà yan búburu láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ba àwòrán Ọlọ́run jẹ́ nínú wọn, wọ́n fún gbogbo ìran wọn ni ìrí tó díbàjẹ́ (Romu 5:12). Lónìí, a sì ní àwòrán Ọlọ́run (Jakọbu 3:9), ṣùgbọ̀n, a tún ní àwọn àpá ẹ̀ṣẹ̀. À ńfi àtubọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ hàn ní èrò, ní ìwà, l'áwùjọ àti àgọ́ ara.
Ìròyìn ayọ̀ náà ni wípé, nígbàtí Ọlọ́run bá ra ẹnìkọ̀ọ̀kan padà, Òun bẹ̀rẹ̀ sí ní mú àwòrán Ọlọ́run padà bọ̀sípò àkọ́kọ́, ó da "ọkùnrin titun, èyítí a dá nípa ti Ọlọ́run li òdodo àtí ìwa mímọ́ òtítọ́" (Efesu 4:24). Wípé ìràpadà wà nípa ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi tí ó gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yàwá lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Efesu 2:8-9). Nípa Kristi, a di ẹ̀dá titun gẹ́gẹ́ bí ìrí Ọlọ́run (2 Kọrinti 5:17).
English
Kínni ó túmọ̀ sí wípé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run?(Jẹnẹsisi 1:26-27)?