Ibeere
Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà?
Idahun
Ìbéèrè tí ó rọ̀rùn yìí, jẹ́ síbẹ̀ èyí tí ó ṣe kókó, jẹ́ ìbéèrè tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a le bèèrè. "Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà?", nííṣe pẹ̀lú ibi tí a ó ti lo ayérayé wa lẹ́yìn tí ayé wa bá d'ópin ní ilé-ayé yìí. Kò sí ọ̀rọ̀ pàtàkì kankan mọ́ ju àyànmọ́ ayérayé wa. Pẹ̀lú ìdúpẹ́, Bíbélì fihàn kedere lórí bíí ènìyàn ṣe le di ẹni ìgbàlà. Asọ́bodè ará Filippi bi Pọ́ọ̀lù àti Sílà léèrè, "Alàgbà, kínni kí èmi kí ó ṣe kí n le là? (iṣe àwọn Apọsteli 16:30). Pọ́ọ̀lù àti Sílà dáa lóhùn, "Gba Jésù Krístì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là" (Iṣe àwọn Apọsteli 16:31).
Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà? Kílódé tí mo fi ní láti di ẹni ìgbàlà?
Gbogbo wa lati fi ara kó ẹ̀ṣẹ̀ (Romu 3:23). A bí wa sínú ẹ̀ṣẹ̀ (Orin Dafidi 51:5), a sì yàn fúnra wa láti d'ẹ́ṣẹ̀ (Oniwaasu 7:20; 1 Johannu 1:8). Ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ohun tí kò jẹ́ kí á di ẹni ìgbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó yà wá nípá kúdò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó mú wa wà ní ipa ọ̀nà ìparun ayérayé.
Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà? Gbàlà kúrò nínú kínni?
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gbogbo wa la l'ẹ́tọ̀ọ́ sí ikú (Romu 6:23). Nígbàtí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú ara, ìyẹn nìkan kọ́ ni irú ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ ńfà. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni à ń á gidigidi sí Ọlọ́run ayérayé àti àìlópin (Orin Dafidi 51:4). Nítorí ìyẹn, ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa tí ó yẹ jẹ́ ayérayé àti àìlópin pẹ̀lú. Ohun tí a nílò láti là kúrò nínú rẹ̀ ni ìparun ayérayé (Matteu 25:46; Ifihan 20:15).
Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà? Báwo ni Ọlọ́run ṣe pèsè Ìgbàlà?
Nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa tí ó yẹ jẹ́ àìlópin àti ayérayé, Ọlọ́run nìkan ló le san gbèsè ìjìyà náà, nítorí Òun nìkan ló jẹ́ àìlópin àti ayérayé. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, nínú àbùdá àti-òkè wá Rẹ̀, kò le kú. Ọlọ́run wá di ènìyàn ẹni tíí ṣe Jésù Kristi. Ọlọ́run gbé àwọ̀ ọmọ ènìyàn wọ̀, gbe pẹ̀lú wa, ó sì kọ́ wa. Nígbàtí àwọn ènìyàn kọ òun àti ọ̀rọ̀ Rẹ̀, tí wọ́n sì wá láti pa Á, Ó jọ̀wọ́ ara Rẹ̀ fún ìrúbọ wa, ó gbà fúnra Rẹ̀ láti kàn-án mọ́ àgbélèbú (Johannu 10:15). Nítorí Jésù Kristi jẹ́ ènìyàn, Ó le kú; àti nítorí Jésù jẹ́ Ọlọ́run, ikú Rẹ̀ ní iye ayérayé àti àìlópin. Ikú Jésù lórí igi àgbélèbú jẹ́ ìsan gbèsè tí ó péye tí ó sì pé fún ẹ̀ṣẹ̀ wa (1 Johannu 2:2). Òun gba ìyà tí ó yẹ fún wa. Àjíǹde Jésù kúrò nínú òkú fihàn wípé ikú Rẹ̀ jẹ́ ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ pípé tí ó kún jùlọ l'ótìítọ́.
Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà? Kínni mo ní láti ṣe?
"Gba Jésù Krístì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là" ((Iṣe àwọn Apọsteli 16:31). Ọlọ́run ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Ohun gbogbo tí o ní láti ṣe ni kí o gbàá, nínú ìgbàgbọ́, ìgbàlà tí Ọlọ́run múwá (Efesu 2:8-9). Gbẹ́kẹ̀lé Jésù nìkan l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìsanwó fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Gbàgbọ́ nínú Rẹ̀, ìwọ kò sì ní ṣègbé (Johannu 3:16). Ọlọ́run ńfún ọ ní ìgbàlà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ohun gbogbo tí o nílò láti ṣe ni kí o gbàá. Jésù ni ọ̀nà ìgbàlà (Johannu 14:6).
Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!
Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.
English
Báwo ni mo ṣe le di ẹni ìgbàlà?