settings icon
share icon
Ibeere

Báwo àti nígbàwo ni a ṣe àkójọpọ̀ Bíbélì?

Idahun


Ọ̀rọ̀ náà "àkójọpọ̀ ìwé Mímọ́" ni a ńlò láti ṣe àpéjúwe àwọn ìwé tí wọ́n ní ìmísí l'átòkè tí wọ́n sì wà nínú Bíbélì. Ìṣòro àti mọ àkójọpọ̀ Bíbélì ni pé Bíbélì kò fún wa ní àkójọ àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì. Ṣíṣe àkójọpọ̀ jẹ́ ètò tí àwọn olùkọ́ àti ọ̀jọ̀gbọ́n Júù kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn náà ní àwọn Onígbàgbọ́ àkọ́kọ́ ṣeé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Ọlọ́run ló ṣe ìpinnu àwọn ìwé tó wà nínú àkójọpọ̀ Bíbélì. Ìwé inú Bíbélì kán wà nínú àkójọpọ̀ náà ní kété tí Ọlọ́run bá ti mísí kíkọ́ rẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ńpàrọwà irú àwọn ìwé tí ó gbọ́dọ̀ wà nínú Bíbélì fún àwọn olùtẹ̀lé Rẹ̀.

Ní àfìwé sí Májẹ̀mú Titun, àríyànjiyàn kékeré ló wà lórí àkójọpọ̀ Májẹ̀mú Láíláí. Àwọn onígbàgbọ́ Heberu mọ àwọn ìráńsẹ́ Ọlọ́run wọ́n tí wọ́n sì gba ọ̀rọ wọn bíi èyítí Ọlọ́run mísí. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ìtàkùrọ̀sọ kan tí a kò le f'ojú parẹ́ wà lórí àkójọpọ̀ Májẹ̀mú Láíláí, ní ọdún 250 A. D (lẹ́yìn ikú Kristi). ìfohùnsọ̀kan àgbáyé lórí àkójọpọ̀ ìwé Mímọ́ Hébérù fẹ́rẹ̀ wáyé. Ohun kan soso tó kù ni Apocrypha, pẹ̀lú àwọn ìtàkùrọ̀sọ àti ìjíròrò tó ńtẹ̀síwájú lóòní. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé Heberu gba Apocrypha láti jẹ́ ìtàn dáadáa àti ìwé ẹ̀sìn, ṣùgbọ́n kìí ṣe ní ìpele kańnàá pẹ̀lú ìwé Mímọ́ Heberu.

Fún Májẹ̀mú Titun, ètò ìfihàn àti ìgbájọ bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rún ọdún àkọ́kọ́ ti Ìjọ Onígbàgbọ́. Ní kùtùkùtù, àwọn ìwé Májẹ̀mú Titun ti jẹ́ èyí tí a dámọ̀. Pọ́ọ̀lù rí àwọn ìwé Luku bíi èyí tí ó ní àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi ti Májẹ̀mú Láíláí (1 Timoteu 5:18; wo Deuterọnọmi 25:4 àti Luku 10:7 pẹ̀lú). Peteru dá àwọn ìwé Pọ́ọ̀lù mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìwé Mímọ́ (2 Peteru 3:15-16). Lára àwọn ìwé Májẹ̀mú Titun kan tàn káàkiri láàrin àwọn ìjọ (Kolosse 4:16; 1 Tẹssalonika 5:27). Clement ti Romu dárúkọ ó kéré jù ìwé Májẹ̀mú Titun mẹ́jọ (ní ọdún 95 lẹ́yìn ikú Kristi). Iginatu ti Antioku mọ bíi ìwé méje (ní ọdún 115 lẹ́yìn ikú Kristi). Polycarp, ọmọ-ẹ̀hìn Johannu àpọ́stélì, gba àwọn ìwé 15 (ní ọdún 108 lẹ́yìn ikú Kristi). Lẹ́yìn náà, Irenaeus dárúkọ ìwé 21 (ní ọdún 185 lẹ́yìn ikú Kristi). Hippolytus dá ìwé 22 mọ̀ (ní ọdún 170-235 lẹ́yìn ikú Kristi) Àwọn ìwé Májẹ̀mú Titun tí wọn ńgba àríyànjiyàn jùlọ ni Heberu, Jakọbu, Peteru keji, Johannu keji, ati Johannu kẹta.

"Àkójọpọ̀ ìwé-mímọ́" àkọ́kọ́ ni àkójọpọ̀ Muratory, tí a ṣe àkójọ rẹ̀ ní ọdún 170 lẹ́yìn ikú Kristi. Àkójọpọ̀ Muratory ní gbogbo ìwé Májẹ̀mú Titun àyààfi Heberu, Johannu, ati Johannu kẹta. Ní ọdún 363 lẹ́yìn ikú Kristi, gẹ́gẹ́ bí alásẹ. Ìgbìmọ̀ Laodicea sọ wípé Májẹ̀mú Láíláí nìkan (ní ìbámu pẹ̀lú Apocrypha) àti àwọn ìwé 27 ti ìwé Májẹ̀mú Titun ni a gbọ́dọ̀ kà nínú ìjọ. Ìgbìmọ̀ Hippo (ọdún 393 lẹ́yìn ikú Kristi) ati ìgbìmọ̀ Carthage (ní ọdún 397 lẹ́yìn ikú Kristi) náà fi ìdí ìwé 27 kańnáà múlẹ̀.

Àwọn ìgbìmọ̀ náà tẹ̀lé ǹkan tó papọ̀ mọ́ àgbékalẹ̀ wọ̀nyìí láti pinnu bóyá ìwé Májẹ̀mú Titun ní ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ nítòótọ́: 1) Ṣé òǹkọ̀wé náà jẹ́ àpóstélì tàbí ó ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú àpóstélì kan? 2) Ǹjẹ́ ara Krístì l'ápapọ̀ ti gba ìwé náà wọlé? 3) Ṣé ìwé náà wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àti àbáláyé tó se déédé? 4) Ṣé ìwé náà ní ẹ̀rí ìwà àti ẹ̀mí tó yè kooro èyí tí yóò fi iṣọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ hàn? Lẹ́ẹ̀kansi, ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé ìjo kọ́ ló pinnu àkójọpọ̀ ìwé Mímọ́. Kòsí ìgbìmọ̀ ìjọ àkọ̀kọ̀ tó pinnu àkójọpọ̀ ìwé Mímọ́. Ọlọ́run ni, àní Ọlọ́run nìkan, ló pinnu àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fún àwọn olùtẹ̀le Rẹ̀ ní ohun tí Ó ti pinnu. Ẹ̀tọ̀ ènìyàn láti gba àwọn ìwé Bíbélì ní àbàwọ́n, sùgbọ́n Ọlọ́run, nínú agbára Rẹ̀, àti pẹ̀lú àìmọ̀kan àti ọkàn líle wa, mú ìjọ àkọ̀kọ̀ láti mọ àwọn ìwé tí Ó mísí.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo àti nígbàwo ni a ṣe àkójọpọ̀ Bíbélì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries