Ibeere
Kínni ọ̀nà tí ó tọ́ láti k'ẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Idahun
Mímọ́ ìtumọ̀ Ìwé-Mímọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú iṣẹ́ pàtàkì tí onígbàgbọ́ ní n'ílé ayé yìí. Ọlọ́run kò sọ fún wa wípé kí á kàn ṣáà ka Bíbélì. A gbọ́dọ̀ kàá kí a sì dìímú lọ́nà tí ó tọ́ (2 Timoteu 2:15). Iṣẹ́ takuntakun ni ìkẹ́ẹ̀kọ́ Ìwé-Mímọ́ jẹ́. Sísáré wo Ìwé-Mímọ́ le yọrí sì ìpinnu òdì nígbà míìrán. Nítorínáà, ó ṣe pàtàkì láti mọ àwọn ìpele òye púpọ̀ fún mímọ ìtumọ̀ Ìwé-Mímọ́ tí ó tọ́.
Àkọ́kọ́, akẹ́ẹ̀kọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ gbàdúrà kí ó sì bi Ẹ̀mí-Mímọ́ fún ìmísí òye, nítorí ọkàn nínú àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ nìyẹn. "Ṣùgbọ́n nígbàtí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì bá dé, yóò tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; Nítorí kì yóò sọ ti ara Rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, on ni yóò ma sọ: yóò sì sọ ohun tí ńbọ̀ fún yín" (Johannu 16:13). Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe tọ́ àwọn àpọ́stélì sọ́nà ní kíkọ́ Májẹ̀mú Titun, Òun ńtọ́ wa pẹ̀lú láti ní òye Ìwé-Mímọ́. Rántí, Ìwé Ọlọ́run ni Bíbélì jẹ́, àwa sì nílò láti bi Òun léèrè ohun tí ó túmọ̀ sí. Bí ìwọ́ ba jẹ́ onígbàgbọ́, ẹni tí ó kọ Ìwé-Mímọ́—Ẹ̀mí Mímọ́—ńgbé inú rẹ̀, Òun sì fẹ́ kí ó ní òye ohun tí Òun kọ.
Ẹ̀kejì, a kò nílò láti yọ ẹṣẹ̀ Ìwé-Mímọ́ kan kúrò lára àwọn ẹsẹ̀ tí ó yíiká kí á wá máa fún un ní ìtumọ̀ tí kò tọ̀nà. A gbọ́dọ̀ máa ka àwọn ẹṣẹ̀ àti orí tó yíiká láti mọ ìtumọ̀ náà. Nígbàtí gbogbo Ìwé-Mímọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (2 Timoteu 3:16; 2 Peteru 1:21), Ọlọ́run lo ènìyàn láti kọọ́ sílẹ̀. Àwọn ènìyàn yìí ní àkòrí kan l'ọ́kàn, ìdí fún kíkọ, àti kókó ọ̀rọ̀ tí wọ́n ńkojú. A gbọ́dọ̀ ka ìfáàrà Ìwé Bíbélì tí a nkọ láti mọ ẹnití ó kọọ́, ẹnití a kọ ọ́ sí, ìgbà tí a kọ, àti ìdí tí a fi kọ́. Bákannáà, a gbọ́dọ̀ sọ́ra láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà sọ̀rọ̀ fún ara rẹ̀. Nígbà míìrán àwọn ènìyàn má ńfún ọ̀rọ̀ ní ìtumọ̀ ara wọn láti ní ìtumọ̀ tí wọ́n fẹ́.
Ẹ̀kẹta, a kò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti dáwà nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa. Ìgbéraga ni láti ro wípé a kò le l'óye nípasẹ̀ iṣẹ́ ẹlòmíràn tó tii k'ẹ́kọ̀ọ́ Ìwé-Mímọ́. Àwọn míìrán, nínú àṣìṣe, ka Bíbélì pẹ̀lú èrò wípé àwọn yóò gbẹ́kẹ̀lé Ẹ̀mí Mímọ́ nìkan àwọn yóò sì ṣe àwárí gbogbo òtítọ́ tó pamọ́ nínú ìwé Mímọ́. Kristi, nínú fífi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ti fún àwọn ènìyàn ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún ara Kristi. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí ni ti ìkọ́ni (Efesu 4:11-12; 1 Kọrintí 12:28). Olúwa ló fún wa ní àwọn olùkọ́ yìí kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye àti láti gbọ́ràn sí Ìwé Mímọ́. Ó jẹ́ ọgbọ́n láti k'ẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míìrán nígbàgbogbo, nípa rírán ara-ẹni lọ́wọ́ nínú ìlóye àti lílo òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ní àkótán, kínni ọ̀nà tí ó tọ́ láti k'ẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Àkọ́kọ́, nípa àdúrà àti ìrẹ̀lẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbáralé Ẹ̀mí Mímọ́ láti fún wa ní òye. Ẹ̀kejì, a gbọ́dọ̀ máa k'ẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà gbogbo ní ipò rẹ̀, ní mímọ̀ wípé Bíbélì ńṣàlàyé ara rẹ̀. Ẹ̀kẹta, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún akitiyan àwọn onígbàgbọ́ míìrán, tí àtẹ̀yìnwá àti ìsinsìnyí, tí wọ́n ti lépa láti k'ẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáradára. Rántí, Ọlọ́run ní ẹni tí ó kọ Bíbélì, Ó sì fẹ́ kí á ní òye rẹ̀.
English
Kínni ọ̀nà tí ó tọ́ láti k'ẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?