Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa ìṣàkóso ìṣúná owó rẹ?
Idahun
Bíbélì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan láti sọ nípa ètò ìṣúná owó. Nípa owó yíyá, Bíbélì tilẹ̀ gbaniníyànjú lòdì síi. Wo ìwé Òwe 6:1-5; 20:16; 22:7, 26-27 ("Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún onígbèsè.... Máṣe wà nínú àwọn tí ńṣe ìgbọ̀wọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè. Bí ìwọ kò bá ní ǹkan tí ìwọ ó fi san, nítorí kíni yíò ṣe gba ẹní rẹ kúrò lábẹ́ rẹ''). Lórèkórè, Bíbélì kìlọ̀ fún wa nípa ìkó ọrọ̀ jọ, ó sì gbàwá níyànjú láti wá ọrọ̀ ọ̀run jọ dípò. Ìwé Òwe 28:20: "Olóòótọ́ ènìyàn yíó pọ̀ fún ìbùkún: ṣùgbọ̀n ẹnití ó kánjú àti là kì yíò ṣe aláìjìyà." Wo ìwé Òwe 10:15; 11:4; 18:11; 23:5.
Ìwé Òwe 6:6-11 fún wa ní ọgbọ́n nípa ìmẹ́lẹ́ àti ìparun ètò ìṣúná tó tibẹ̀ yọ láìní ọ̀nà àbáyọ. A sọ fún wa wípé kí á wo akínkanjú èèrà tí ó ńkó óunjẹ rẹ̀ jọ òn tìkalára rẹ̀. Àyọkà yìí kìlọ̀ wípé kí á má sùn nígbà tí ó yẹ kí á máa ṣe iṣẹ́ tó lérè nínú. "Oní ìmẹ́lẹ́ ènìyàn" jẹ́ ọ̀lẹ, ọ̀lẹ ènìyàn tí ó fẹ́ láti máa sinmi dípò kí ó ṣiṣẹ́. Òpin rẹ̀ dájú— ìṣẹ́ àti àìní. Òdì kejì rẹ̀ ni ẹni tí ìfẹ́ owó tí gbé wọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ́ ìwé Oníwàásù 5:10, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ọrọ̀ tí kò lè tẹ́ẹ lọ̀rùn, tí ó sì gbọ́dọ̀ máa wá si síwájú àti síwájú. Ìwé Timoteu Kínní 6:6-11 kílọ̀ fún wa nípa pàkúté ìfẹ́kúfẹ́ ọrọ̀.
Dípò kí á máa kó ọrọ̀ jọ fún ara wa, àwòkọ́ṣé Bíbélì ni ti ìfifúnni, kìí ṣe ti gbígbà. "Rántí èyí: Ẹnití ó bá fúnrúgbìn kíún, kíún ni yóò ká; ẹnití ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. Kí olúkúlukú ènìyàn kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu lí ọkàn rẹ́; kìí ṣe àfẹ̀kùnṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe, nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ" (1 Kọrinti 9:6-7). A rọ̀ wá wípé kí á jẹ́ ìríjú rere fún ohun tí Ọlọ́run fi fún wa. Nínú Ìwé Luku 16:1-13, Jésù pa òwe ìríjú aláìṣòótọ́ nì gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún ìríjú búburú. Ẹ́kọ́ tí ìtàn yìí kọ́ wa ni wípé "Ǹjẹ́ tí ẹ́nyin kò bá ti jẹ́ olóòótọ́ ní mámmónì àìsòótọ́, tani yóò fi ọrọ̀ tòótọ́ ṣú nyín? (ẹsẹ̀ 11). A sì ní ojúṣe láti pèsè fún ará ilé ẹni, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ́ ìwé Timoteu Kínní 5:8 ṣe rán wa létí: "Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ́, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ́, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ".
Ní àkótán, kínni Bíbélì sọ nípa ìṣàkóso ìṣúná rẹ? A lè ṣe ìdáhùn náà ní eréfèé pẹ́lú ọ̀rọ̀ kan—ọgbọ́n. A gbọ́dọ̀ gbọ́n pẹ̀lú owó wa. A gbọ́dọ̀ máa fi owó pamọ́, ṣùgbọ́n kí á má háwọ́ nípa rẹ̀. A ní láti ná owó, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọpọlọ àtí ìjánu. A gbọ́dọ̀ fi fún Ọlọ́run, tayọ̀tayọ̀ àti pẹ̀lú ìfarajìn. A gbọ́dọ̀ máa lo owó wa láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdámọ̀ àti ìdarí ẹ́mí Ọlọ́run. Kò burú láti ní owó, ṣùgbọ́n ó burú láti fẹ́ràn owó. Kò burú láti tòṣì, ṣùgbọ́n ó burú láti máa ná owó lórí nǹkan tí kò wúlò. Ìwàásù Bíbélì tí ó dúró ṣinsin lórí ṣíṣàkóso owó ni láti ní ọgbọ́n.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa ìṣàkóso ìṣúná owó rẹ?