settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ìwòsàn? Ṣé ìwòsàn wà nínú ètùtù Kristi?

Idahun


Isaiah 53:5 tí a sọ nípa rẹ̀ nínú Peteru Kínní 2:24, jẹ́ ẹsẹ̀ gbòógì lórí ìwòsàn, ṣugbọ́n a máa ńṣe àṣìgbọ́ àti àṣìlò rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. "Ṣùgbọ́n a ṣá a ní ọgbẹ́ nítorí ìrékọjá wa, a pa á lí ara àìsedédé wa, ìnà àlàáfíà wa wà lára rẹ̀; àti nípa ìnà ẹni rẹ̀ li a mú wa lárada" Ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí "lárada" lè jẹ́ ìmúláradá lẹ́mí tàbí lára. Ṣùgbọ́n, àwọn àyọkà ìwé Isaiah 53 àti ìwé Peteru Kínní ori 2 fihàn kedere wípé ìmúláradá lẹ́mí ni à ńsọ. "Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá " (1 Peteru 2:24). Ẹsẹ̀ yìí ńsọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti òdodo, kìí ṣe àìlera àti àìsàn. Nítorínà, jíjẹ́ ẹni tí a mú "láradá" ní ẹsẹ̀ méjèèjì sọ nípa jíjẹ́ ẹni tí a dáríjì àti tí a gbàlà, kì íṣe ìmúláradá lára.

Bíbélì kò so ìmúláradá lẹ́mí àti lára pọ̀ ní pàtó. Nígbà míìrán a mú àwọn ènìyàn lárada nígbàtí wọ́n bá fi ìgbàgbọ́ wọn sínú Kristi, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo. Nígbà míìrán, ìfẹ́ Ọlọ́run ni láti wòsàn, ṣùgbọ́n nígbà míìrán kò rí bẹ́ẹ̀. Àpọ́stélì Johannu fún wa ní àfojúsùn tí ó tọ̀nà: "Eyi si ni igboya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa. Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ngbọ́ ti wa, ohunkóhun tí àwa bá bèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti bèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà"( 1 Johannu 5:14-15). Ọlọ́run sì ńṣe ìyanu. Ọlọ́run sì ńwòsàn síbẹ̀. Àìsàn, àrùn, ìrora àti ikú jẹ́ ohun ti ó dájú nínú ayé. Àyààfi bí Olúwa bá padà, gbogbo ènìyàn tó wà láyé lónìí ni yóo kú, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn (pẹ̀lú àwọn Kristiẹni) ni yóo kú gẹ́gẹ́ bí àyọrísí ìṣoro ara (àrùn, àìsàn, ọgbẹ́). Kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run láti wòwásàn lára.

Ní ìkẹhìn, ìlera pípé ńdúró dè wá lọ̀run. Ní ọ̀run, kò ní sí ìrora àìsàn, àrùn, ìjìyà tàbí ikú mọ́ (Ifihan 21). Gbogbo wa nílò láti máa kọbiara sí ipò ara wa nínú ayé yìí, ṣùgbọ́n kí nǹkan ẹ̀mí kàn wá púpọ̀ (Romu 12:1-2). Kí á sì fọkàn wa sí ọ̀run níbi tí a kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìṣòró ara. Ifihan 21:4 ṣe àpèjúwe ìwòsàǹ tòótọ́ tí a gbọ́dọ̀ máa pòǹgbẹ fún: Ifihan 21:4 sọ fún wa wípé "Òun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn. Kì yóò sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ni kì yóò sí ìrọra mọ́: nítorípé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ."

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ìwòsàn? Ṣé ìwòsàn wà nínú ètùtù Kristi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries