Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa ogun?
Idahun
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa ńṣe àṣìṣe nígbàtí wọ́n bá ka ìwé Ẹksodu 20:13, "Ìwọ kò gbọdọ̀ pa ènìyàn", nígbà náà wọn a fẹ́ lo àṣẹ yí nínú ogun. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ Hébérù túmọ̀ sí "kí á mọ̀ọ́mọ̀ọ́, pa ènìyàn míìrán pẹ̀lú odì; ìpànìyàn" Lọ́pọ̀ ìgbà Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Isrẹli láti lọ sí inú ogun pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè míìrán (1 Samuẹli 15:3, Joshua 20:11). Ọlọ́run pàṣẹ ìjìyà ikú fún onírúnrú ọ̀ràn. (Ẹksodu 21:12, 15; 22:19; Lẹfitiku 20:11) Nítorí náà Ọlọ́run kò lòdì sí ìpànìyàn nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀, àmọ́ ìpànìyàn. Ogun kò fi ìgbà kankan dará rí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nǹkan tí ó yẹ nígbà míìrán. Nínú ayé tí ó kún fún àwọn ènìyàn ibi (Romu 3:10-18), ogun jẹ́ kò ṣé maní. Nígbà míìrán ọ̀nà kan ṣoṣo tí a fi le pa àwọn ènìyàn ibi mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìṣẹ̀ kí wọ́n má baà ṣe wọ̀n níbi ni kí á lọ sínú ogun.
Nínú Májẹ̀mú Láíláí, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Isrẹli láti "gbẹ̀san àwọn ọmọ Isrẹli lára àwọn ọmọ Mídíánì"(Numeri 31:2). Deutarọnọmi 20:16-17, sọ wípé, "ṣùgbọ́n nínú ìlú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ ní ìní, kí ìwọ kí ó máṣe dá ohun kan sí tí ó ńmí: Ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n run pátápátá...bí OLÚWA Ọlọ́run rẹ́ ti pàṣẹ fún ọ". Bẹ́ẹ̀ni, 1 Samuẹli 15:18 sọ wípé, "Lọ kí o sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ará Ámélékì run, kí o sì bá wọn jà títí o fi run wọ́n" Ó hàn kedere wípé Ọlọ́run kò lòdì sí gbogbo ogun. Jésù wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba nígbà gbogbo (Johannu 10:32), nítorí náà a kò lè jíyàn wípé ogun jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run nikán nínú Májẹ̀mú Láíláí. Ọlọ́run kò lè yípadà (Malaki 3:6; Jakọbu 1: 17). Ipádabọ̀ Jésù ní ìgbà kejì yóò burú gan. Iwé Ifíhàn 19:11-21 ṣe àpèjúwe ogun ìkẹyìn pẹ̀lú Kristi, oluṣẹ́gùn olórí ogun tí yóò ṣe ìdájọ́, tí ó sì ńjagun "pẹ̀lú òdodo" (ẹsẹ̀ 11). Yóò kún fún ẹ̀jẹ̀ (ẹsẹ̀ 13), yóò sì burú gan. Àwọn ẹyẹ yóò jẹ ẹran ara àwọn tí ó kọjú ìjà sí Í (ẹsẹ̀ 17-18). Kò ní ní ojú àánú fún àwọn ọ̀tá Rẹ̀, tí yóò borí wọn pátápátá, tí yóò sì sọ sínú "adágún iná tí ńfi súlfúrù jó". (ẹsẹ̀ 20)
Ó jẹ́ àṣìṣe láti sọ wípé Ọlọ́run kò fọwọ́ sí ogun rárá. Jésù kìí ṣe ẹnití ó lòdì sí ogun. Nínú ayé tí ó kún fún ènìyàn búburú, nígbà míìrán ogun jẹ́ nǹkan tí a nílò láti fi dí àwọn ènìyàn ibi lọ́wọ́ ibi ńlá. Bí a kò bá borí Hítla nínú ogun àgbáyé kejì, míllíọnù ènìyàn méló ni a kò bá ti pa? Bí wọn kò bá tíì ja ogun abẹ́lé Amẹ́ríkà, báwo ni ọmọ Amẹ́ríkà láti Áfríkà yóò ti pẹ́tó nínú ìjìyà?
Ogun jẹ́ ohun tí ó burú. Àwọn ogun kan "dára" ju àwọn míìrán lọ, ṣùgbọ́n ogun jẹ àyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ nígbà gbogbo (Romu 3:10-18). Nígbà kan náà, ìwé oníwàásù 3:8 sọ wípé, ìgbà fífẹ́, àti ìgbà ìkóríra; ìgbà ogun, àti ìgbà àlàáfíà" Nínú ayé tí ó kún fún ẹ́ṣẹ̀, ìkóríra àti ibi (Romu 3:10-18), ogun jẹ́ kò ṣé maní. Kristiẹni kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ogun, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọ́dọ̀ ṣe àtakò ìjọba tí Ọlọ́run ti fi ṣe olórí lórí wọn (Romu13:1-4; 1 Peteru 2:17). Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù tí a lè ṣe ní àkókò ogun ni láti gbàdúrà fún ọgbọ́n Ọlọ̀run fún àwọn olórí wa, gbígbàdúrà fún ààbò àwọn ológun, gbígbàdúrà fún ìyanjú kíákíá àti gbígbàdúrà fún ìjàǹbá tí ó ṣẹ́pẹ́rẹ́ láàrin àwọn ará-ìlú ní ìhà méjèèjì (Fílíppi 4:6-7).
English
Kínni Bíbélì sọ nípa ogun?