Ibeere
Kínni ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ ka Bíbélì/kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Idahun
Àwa gbọ́dọ̀ ka Bíbélì kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ nítorí ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa. "Ìmísí-Ọlọ́run" ni Bíbélì jẹ́ (2 Timoteu 3:16). Ní èdè míìrán, ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an sí wa. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni àwọn onímọ̀ ti bèèrè tí Ọlọ́run ti dáhùn fún wa nínú Ìwé mímọ́. Kínni ète fún ìgbé-ayé? Níbo ni mo ti wá? Ṣé ayé wà lẹ́yìn ikú? Báwo ni mo ṣe lè dé ọ̀run? Kílódé tí ayé fi kún fún ibi? Kílódé tí mo fi ńtiraka làti ṣe rere? Ní àfikún sí àwọn ìbéèrè ńlá wọ̀nyìí, Bíbélì pèsè àmọ̀ràn tí ó ṣé e mú wá si ìṣe gẹ́gẹ́ bíi: Kínni mo ńwá nínú ẹnìkejì? Báwo ni mo ṣe lè ní àṣeyọrí nínú ìgbéyàwó? Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ dáradára? Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ òbí dáradára? Kínni àṣeyọrí àti wípé báwo ni mo ṣe lè ṣeé? Báwo ni mo ṣe lè yípadà? Kínni ó ṣe pàtàkì gan ní ilé ayé? Báwo ni mo ṣe lè gbé tí mi ò fi ní k'àbámọ̀? Báwo ni mo ṣe lè ṣẹ́gun àwọn àkókò tí kò dára àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé burúkú?
Àwa gbọ́dọ̀ ka àti kẹ́ẹ̀kọ̀ Bíbélì nítorí ó ṣée gbáralé pátápátá tí kò sì ní àṣìṣe. Bíbélì dá yàtọ̀ láàrin àwọn ìwé tí à ńpè ní "mímọ́" níti wípé kìí kàn fún ni ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀ kó wá wípé, "Gbẹ́kẹ̀lé mí." Dípò bẹ́ẹ̀, àwa ní agbára láti dán-an wò nípa yíyẹ ọgọgọ́rọ̀rún ìsọtẹ́lẹ̀ ni kíkún wò, nípa yíyẹ àkọsílẹ̀ ìtàn tí ó kọ wò, àti nípa yíyẹ ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀ tó jọra wò. Àwọn tí ó sọ wípé Bíbélì ní àṣìṣe ti di etí wọn sí òtítọ́. Jésù ti bèèrè èyítí ó rọrùn láti wí, "A dárí àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ jìn," tàbí "Dìde, gbé àketè rẹ kí o sì ma rìn." Nígbànáà ó fihàn wá wípé Òun ni agbára láti darí ẹ̀sẹ̀ jìn (ohun tí a kò lè rí pẹ̀lú ojú wa) nípa wíwo arọ sàn (ohun tí àwọn tí ó yíi ká lè jẹ́rìí síi pẹ̀lú ojú wọn). Bákanáà, a fún wa ní ìdánilójú wípé òtítọ́ ni Ọ̀rọ́ Ọlọ́run nígbàtí ó bá ńjíròrò àwọn ohun ẹ̀mí tí a kò lè yẹ̀ wò pẹ̀lú ọpọlọ wa nípa sísọ ara rẹ̀ di òótọ́ ní àwọn ibi tí a lè yẹ̀wò, bíi ìṣedéédé ìtàn, ìṣedéédé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, àti ìṣedéédé àsọtẹ́lẹ̀.
Àwa gbọ́dọ̀ kà kí á sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí wípé Ọlọ́run kò yípadà àti nítorípé àbùdá ìran ọmọ ènìyàn kìí yípadà; ó wúlò fún wa gẹ́gẹ́ bíi ìgbà tí a kọ́ọ. Bí ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣe ńyípadà, àbùdá ìran ènìyàn àti ìfẹ́ ọkàn wọn kò yípadà. A rí , bí a ṣe ńka ojú ìwé ìtàn Bíbélì, wípé bóyá à ńsọ̀rọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ ọlọ́kanòjọ̀kan tàbí àwùjọ, "kò sí ohun titun lábẹ́ òòrùn" (Oniwaasu 1:9). Nígbàtí ọmọ ènìyàn l'àpapọ̀ bá ńtẹ̀sìwájú láti wá ìfẹ́ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ní gbogbo ibi àìtọ́, Ọlọ́run—Aṣẹ̀dá wa tí ó dára tó sì l'ógo—sọ ohun tí yóò fún wa láyọ̀ àìnípẹ̀kun. Ọ̀rọ̀ ìfihàn Rẹ̀, Bíbélì, ṣe pàtàkì tí Jésù fi sọ nípa Rẹ̀ wípé, "Ènìyàn kì yòó wà láàyè nípa àkàrà nìkan, bíkòse nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá" (Matteu 4:4). Ní ọ̀rọ̀ míìrán, tí a bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́, gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run ṣe fẹ́, àwa gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ kí a sì kíyèsi.
Àwa gbọ́dọ̀ kàá kí a sì kẹ́ẹ̀kọ́ Bíbélì nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ èké wáà. Bíbélì fún wa ní òdiwọ̀n èyítí a ó fi mọ òtítọ́ yàtọ̀ sí àṣìṣe. Ó ńsọ fún wa ohun tí Ọlọ́run jẹ́. Làti ní òye òdì nípa Ọlọ́run ni láti máa a sin òrìṣà tàbí Ọlọ́run èké. Àwa ńsín ohun tí kìí ṣe Òun. Bíbélì sọ fún wa bí ènìyàn ti lè dé ọ̀run lóòtọ́, kìí si ṣe nípa iṣẹ́ dáradára tàbí nípa ìrìbọmi tàbí nípa ohun yòwúù tí a ba ṣe (Johannu 14:6; Efesu 2:1-10; Isaiah 53:6; Romu 3:10-18, 5:8, 10:9-13). Ní ọ̀nà yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fihàn wá bí Ọlọ́run ti ṣe fẹ́ràn wa tó (Romu 5:6-8; Johannu 3:16). Nínú kíkọ́ èyí sì ni a fi ńfa sí ìfẹ Rẹ̀ pẹ̀lú (1 Johannu 4:19).
Bíbélì pèsè wa sílẹ̀ láti sin Ọlọ́run (2 Timoteu 3:17; Efesu 6:17; Heberu 4:12). Ó ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bí à ṣé ńdi ẹni ìgbàlà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìjìyà ńlá rẹ̀ (2 Timoteu 3:15). Ṣíṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìgbọràn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ yóò mú àṣeyọ́rí wa n'ílé ayé (Josua 1:8; Jakọbu 1:25). Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńràn wá lọ́wọ́ láti rí ẹ̀ṣẹ̀ nínú ayé wa ó sì ńràn wá lọ́wọ́ láti paárun (Orin Dafidi 119:9, 11). Ó ńfún wa ní ìtọ́sọ́nà ní ayé, ó ńmú kí á ní òye ju àwọn olùkọ́ wa lọ (Orin Dafidi 32:8, 119:99, Owe 1:6). Bíbélì ńpa wá mọ́ kúrò nínú ìfi ọjọ́ ayé wa ṣ'òfò lórí ohun tí kò wúlò àti èyí tí kò ni pẹ́ (Matteu 7:24-27).
Kíkà àti kí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńràn wá lọ́wọ́ láti rí tayọ "páńpẹ́" tó ńfanimọ́ra sí "àhámọ́" ọ̀rọ̀ nínú ìdáńwò ẹ̀ṣẹ̀, kí á lè kẹ́kọ̀ọ́ n'íbi àṣìṣe ẹlòmíìràn jù kí á ṣe wọ́n fúnra wá. Ìrírí ni olùkọ́ àgbà, ṣùgbọ́n bí ó bá di ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ó jẹ́ olùkọ́ líle burúkú. Ó dára jùlọ láti kẹ́kọ̀ọ́ n'íbi àṣìṣe ẹlòmíìràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn inú Bíbélì ni a lè kẹ́ẹ̀kọ́ lára wọn, díẹ̀ lára àwọn tó lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere àti búburú ní ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ilé-ayé wọn. Fún àpẹẹrẹ, Dafidi, nínú ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí Gòláyátì , kọ́ wa wípé Ọlọ́run ju ohunkóhun tí Òun ní kí á dojúkọ lọ (1 Samuẹli 17), nígbàtí gbigbà ìdánwò láàyè láti ṣe àgbèrè pẹ̀lú Baaṣeba ṣe àfihàn bí ìjìyà ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ti le pọ̀ àti burú tó (2 Samuẹli 11).
Bíbélì kìí ṣe ìwé fún kíkà lásán. Ó jẹ́ ìwé fún ẹ̀kọ́ kí á ba lè mulò. Bíbẹ́ẹ̀kọ́, ó dààbi gbígbé oúnjẹ mì láì jẹẹ́ kí á tún wá tuú dànù—kò sí ore kan tí a ó gbà nípa rẹ̀. Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ní agbára bíi àwọn òfin ìṣẹ̀dá. A le táá nù, ṣùgbọ́n a ṣe èyí sí ìparun ara wa, gẹ́gẹ́ bí a ó ti ṣe tí a bá ta òfin lálátóròkè. A kò lè tẹnumọ́ pàtàkì Bíbélì jù sí ayé wa. A lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wé wíwá wúrà. Bí a bá gbìyànjú díẹ̀ tí a sì "ṣe àyẹ̀wò àwọn òkúta inú odò fínífíní," a o rìí wúrà kékeré. Ṣùgbọ́n bí à ṣé ń gbìyànjú láti gbẹ́ ẹ sí, ni a ó ma rí èrè ìgbìyànjú wa.
English
Kínni ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ ka Bíbélì/kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?