Ibeere
Kínni ó túmọ̀ sí wípé Bíbélì ní ìmísí?
Idahun
Nígbàtí àwọn ènìyàn bá ńsọ̀rọ̀ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí èyítí ó ní ìmísí, wọ́n ńtọ́ka síi wípé Ọlọ́run fi agbára darí àwọn ènìyàn tí ó kọ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó jẹ́́ wípé ohun tí wọ́n kọ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Ní ti Ìwé Mímọ́, Ọ̀rọ "ìmísí" túmọ̀ sìí "Ọlọ́run-mí." Ìmísí túmọ̀ sí wípé òótọ́ ni Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó sì mú kí Bíbélì dáyàtọ̀ láàrin àwọn Ìwé yòókù.
Níwọn ìgbàtí oríṣiríṣi ìwòye wà nípa bí ìmísí Bíbélì ṣe tó, kò sí iyèméjì wípé Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé gbogbo Ọ̀rọ̀ nínú gbogbo ẹ̀ka Bíbélì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá (1 Kọrinti 2:12-13; 2 Timoteu 3:16-17). Ìwòye Ìwé Mímọ́ yìí ni à ńpè ní ìmísí "àpérò ìfẹnusọ". Ìyẹn ni wípé ìmísí náà gùn dé bi àwọn Ọ̀rọ̀ náà fúnra wọn (ìfẹnusọ)— tí kìí ṣe àba tàbi èrò—àti wípé ìmísí náà gùn dé gbogbo ẹ̀ka Ìwé Mímọ́ àti gbogbo kókó Ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ (Àpérò). Àwọn kan gbàgbọ́ wípé díẹ̀ lára Bíbélì ló ní ìmísí àbí àwọn èrò tàbí àwọn àbá tó nííṣe pẹ̀lu ẹ̀sìn nìkan ló ní ìmísí, ṣùgbọ́n àwọn ìwòye yìí nípa ìmísí kéré sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ara rẹ̀. Ìmísí àpérò ìfẹnusọ kíkún jẹ́ àbùdá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó ṣe pàtàkì.
Bí ìmísí náà ṣe hàn kedere tó ni a lè rí nínú Timoteu keji 3:16, "Gbogbo Ìwé-Mímọ́ tí ó ní ìmísí Ọlọ́run ti ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbáni-wí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo: kí ènìyàn Ọlọ́run kí ó le pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo." Ẹṣẹ̀ yìí sọ fún wa wípé gbogbo Ìwé-Mímọ́ l'óní ìmísí Ọlọ́run èyí sì jẹ́́ èrè fún wa. Kìí ṣe apá Bíbélì tó ní íṣe pẹ̀lu ẹ̀sìn nìkan lóní ìmísí, ṣùgbọ́n gbogbo Ọ̀rọ̀ láti Jẹnẹsisi títí dé Ifihan. Nítórí ó jẹ́́ ìmísí Ọlọ́run, Ìwé-Mímọ́ wá jẹ́́ àṣẹ nígbàtí a bá fẹ́ fi ẹ̀kọ́ kan múlẹ̀, ó sì tó fún kíkọ́ ènìyàn láti ṣe déédé pẹ̀lú Ọlọ́run. Bíbélì kò gbà wípé òun ni ìmísí Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ó tún ní agbára tó tayọ láti yí wa padà kí ó sì sọ wá di "pípé." Kínni á tún nílò si?
Ẹṣẹ̀ tó tún nííṣe pẹ̀lú ìmísí Ìwé-Mímọ́ ni Peteru keji 1:21. Ẹṣẹ̀ yìí jẹ́́ kí á mọ̀ wípé bí ó tilẹ̀ jẹ́́ wípé Ọlọ́run lo àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìṣesí àti ọ̀nà ìkọ̀wé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Ọlọ́run mísí àwọn Ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ látòkè. Jésù fúnra Rẹ̀ fi ìdí ìmísí àpérò ìfẹnusọ tí Ìwé-Mímọ́ múlẹ̀ nígbàtí Ó sọ wípé, "Ẹ máse rò pé, èmi wá láti pa òfin tàbi àwọn wòólì run: èmi kò wá láti parun, bíkòse láti múuṣẹ. Lóòtọ́ ni mo sá wìí fún yín, títí ọ̀run àti ayé yóò fi kọjá lọ, ohun kíkíní kan nínú òfin kì yóò kọjá, bí ó ti wù kí ó rí..." (Matteu 5:17-18). Nínú àwọn ẹṣẹ̀ yìí, Jésù ńfi agbára kún ìṣedéédé Ìwé-Mímọ́ títí dé orí àlàyé tó kééré jù àti àmìn ìjánu, nítórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gangan ni.
Nítorí Ìwé-Mímọ́ jẹ́́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ni ìmísí, a lè kádìi rẹ̀ wípé wọn kò ní àṣìṣe tí wọ́n sì ní àṣẹ. Ìwòye tí ó tọ́ nípa Ọlọ́run yóò mú ìwòye tí ó tọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wá. Nítorí Ọlọ́run jẹ́ alágbára jùlọ, olùmọ̀-ohun-gbogbo, Ó sì pé yékéyéké, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nípa ẹ̀da rẹ̀ yóò ní àbùdá kańnáà. Ẹṣẹ̀ Bíbélì tó fìdí ìmísí Bíbélì múlẹ̀ náà ló sọ wípé kò ní àṣìṣe wọ́n sì ní àṣẹ. Láìsí iyèméjì Bíbélì jẹ́ ohun tí ó sọ wípé òun jẹ́—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kò le ṣẹ́, tí ó l'áṣẹ sí ìran ènìyàn.
English
Kínni ó túmọ̀ sí wípé Bíbélì ní ìmísí?