Ibeere
Ṣé Bíbélì wúlò lóòní?
Idahun
Heberu 4:12 sọ wípé, "Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run yè ó sì ní agbára. Ó mú ju idà olójú méjì lọ, ó sì ńgúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn." Nígbàtí a parí Bíbélì ní bíi ọdún ẹgbàádínlọ́gọ́rùún (1900) sẹ́yìn, ìṣedéédé àti wíwólò rẹ̀ fún òní kò yàtọ̀. Bíbélì nìkan ni orisùn-un tòótọ́ fún gbogbo ìfihàn tí Ọlọ́run ti fifún wa nípa ara Rẹ̀ àti ìpinnu Rẹ̀ fún ènìyàn.
Bíbélì kún fún àlàyé púpọ̀ nípa ayé tí a rí èyítí àwọn àyèwò ìwáàdí sáyẹ̀ǹsì ti jẹ́rìsí. Díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ wọ̀nyìí ni Lefitiku 7:11; Oniwaasu 1:6-7; Jobu 36:27-29; Orin Dafidi 102:25-27 àti Kolosse 1:16-17. Gẹ́gẹ́bí ìtàn Bíbélì nípa ètò ìràpadà Ọlọ́run fún ènìyàn ṣé ńjẹyọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwa oríṣiríṣi la ṣe àpèjúwe rẹ̀ dáradára. Nínú àwọn àpèjúwe wọ̀nyìí, Bíbélì pèsè àlàyé púpọ̀ nípa ìhùwàsí ènìyàn àti àwọn ìkúndùn wọn. Àwọn ìrírí wà l'ójoójúmọ́ fihàn wá wípé àwọn àlàyé yìí gúnrégé tí wọn sì ṣe àpèjúwe ipò ènìyàn ju ìwé èrò-inú-ọkàn kankan lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtàn tí ó jẹ́ òtítọ́ tí a àkọsílẹ̀ nínú Bíbélì ni a ti jẹ́rìsí nípasẹ̀ àwọn orísun àfikún Bíbélì. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ìwáàdí ìtàn máa ńfi ìpèsè àsopọ̀ láàrin àkọsílẹ̀ Bíbélì àti àkọsílẹ̀ àfikún Bíbélì nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kańnàá hàn.
Ṣùgbọ́n, Bíbélì kìí ṣe ìwé ìtàn, ìwé èrò-inú-ọkàn, tàbí ìwé ìmọ̀ sáyẹ́ńsì. Bíbélì jẹ́ àpèjúwe tí Ọlọ́run fún wa nípa ẹnítí Òun jẹ́, àti àwọn ìfẹ́ àti èrò Rẹ̀ fún ènìyàn. Ìpín ìfihàn yìí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ìtàn ìpínyà wà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìpèsè Ọlọ́run fún ìmúpadàbọ́sípò ìdàpọ̀ nípasẹ̀ ìrúbọ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Kristi, lórí igi àgbélébùú. Àìní wa fún ìràpadà kò yípadà. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ Ọlọ́run láti báwa làjà sí ọ̀dọ̀ ara Rẹ̀.
Bíbélì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé tí ó gúnrégé tí ó sì wúlò. Ìwàásù Bíbélì tó ṣe pàtàkì jùlọ ni —ìràpadà—jẹ́ èyí tí ó wúlò fún ènìyàn jákèjádò ayé àti títí laí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò le ṣákìí, tẹríba, tàbí nílò àfikún láíláí. Àṣà máa ńyípadà, òfin má ńyípadà, ìran kan ńwá tí ó sì ńlọ, ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wúlò lóòní ní bí ó ti wà nígbàtí a kọ́kọ́ kọọ́. Kìí ṣé gbogbo Ìwé Mímọ́ ló bá wa mú lóòní tààrà, ṣùgbọ̀n gbogbo Ìwé Mímọ́ kún fún òtítọ̀ tí a le, àti gbọ́dọ̀, múlò sí ayé wa lóòní.
English
Ṣé Bíbélì wúlò lóòní?