Ibeere
Báwo ni mo ṣe le di Kristiẹni?
Idahun
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti di Kristiẹni ni láti mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà "Kristiẹni" túmọ̀ sí. Orísun ọ̀rọ̀ "Kristiẹni" náà ni ìlú Antiọku ní ẹgbẹ̀rún ọdún àkọ́kọ́ A.D. (wo iṣe Apọsteli 11:26). Ó ṣe é ṣe wípé, ní àkọ́kọ́, ọ̀rọ̀ "Kristiẹni" náà jẹ́ fún bíi àbùkù. Ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí "Krístì kékèéké." Ṣùgbọ́n, láti àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún wá, àwọn onígbàgbọ́ nínú Kristi ti gba ọ̀rọ̀ "Onígbàgbọ́" náà tí wọ́n sìì ńlòó láti fi dá ara wọn mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Ìtumọ̀ Kristiẹni tí ó rọrùn ni ènìyàn tí ó ńtẹ̀lé Jésù Kristi.
Kínni ìdí tí mo gbọ́dọ̀ fi di Kristiẹni?
Jésù Kristi kéde wípé "kò wàá kí á ba máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun, bíkòṣe láti máa ṣe ìránṣẹ́ fúnni, àti láti fi ẹ̀mi rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn" (Marku 10:45). Ìbéèrè náà wá jẹyọ – kínni ìdí tí a fi nílò ìràpadà? Èrò ìràpadà ni gbèsè tí a gbọ́dọ̀ san ní pàṣípààrọ̀ ìdásílẹ̀ ẹnìkan. À má ńsábà lo èrò ìràpadà ní àkókò ìjínigbé, nígbàtí wọ́n bá jí ènìyàn gbé tí wọ́n sì gbé e pamọ́ títí di ìgbà tí owó ìdásílẹ̀ ẹni bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ sísan.
Jésù san gbèsè ìràpadà wa láti dá wa sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn! Ìgbèkùn kúrò nínú kínni? Ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìjìyà rẹ̀, ikú ara lẹ́yìn náà ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kínni ìdí tí Jésù fi gbọ́dọ̀ san gbèsè ìràpadà yìí? Nítorí wípé gbogbo wa la ti fi ara kó ẹ̀ṣẹ̀ (Romu 3;23), a sì ti lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdájọ́ làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (Romu 6:23). Báwo ni Ọlọ́run ṣe san gbèsè ìràpadà wa? Nípa kikú lórí igi àgbélèbú láti san gbèsè ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa (1 Kọrinti 15:3; 2 Kọrinti 5:21). Báwo ni ikú Jésù ṣe tó láti san gbogbo gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa? Jésù jẹ́ Ọlọ́run nínú ara ènìyàn, Ọlọ́run wá sí ayé láti jẹ́ ọ̀kan lára wa kí Òun lè darapọ̀ mọ́ wa àti kí Òun lè kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa (Johannu 1:1, 14). Gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run, ikú Jésù jẹ́ iye tí kò ṣeé díyelé, tí ó tó láti san gbèsè àwọn ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé (1 Johannu 2:2). Àjíǹde Jésù lẹ́yìn ikú Rẹ̀ ṣe àfihàn wípé ikú Rẹ̀ jẹ́ ètùtù tí ó péye, wípé ó ti sẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ní tòótọ́.
Báwo ni mo ṣe le di Kristiẹni?
Èyí ní ìpín tí ó dára jùlọ. Nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa, Ọlọ́run ti jẹ́ kí ó rọrùn gidigidi láti di Kristiẹni. Ohun tí o nílò láti ṣe ní kí o gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà rẹ, gba ikú Rẹ̀ pátápátá gẹ̀gẹ̀ bíi ètùtù tí ó péye fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ (Johannu 3:16), kí o sì gbẹ́kẹ̀lé pátápátá gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ (Johannu 14:6; Iṣe àwọn Apọsteli 4:12). Jíjẹ́ Kristiẹni kìí ṣe ní ìrúbọ nìkan, lílọ sí ilé-ìjọsìn, tàbí ṣíṣe àwọn ohun kan nígbàtí ò ńfi àwọn ohun míìrán sílẹ̀ láì ṣe. Jíjẹ́ Kristiẹni nííṣe pẹ̀lú níní ìbáṣepọ̀ ti ara ẹni pẹ̀lú Jésù Kristi. Ìbáṣepọ̀ ti ara ẹni pẹ̀lú Jésù Kristi, nípa ìgbàgbọ́, ni ohun tí ó ńsọ ènìyàn di Kristiẹni.
Sé o ti setán láti di Kristiẹni ?
Bí o bá ti setán láti di Kristiẹni nípa gbígba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ, ohun gbogbo tí o nílò láti ṣe ni kí o gbàgbọ́. Ṣé ó yé ọ tí ó sì gbàgbọ́ wípé ìwọ́ ti dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run tí ó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdájọ́ Ọlọ́run? Sé ó yé ọ tí ó sì gbàgbọ́ wípé Jésù ti mú ìjìyà rẹ sí orí ara Rẹ, tí ó sì kú ní ipò rẹ? Sé ó yé ọ tí ó sì gbàgbọ́ wípé iku Rẹ̀ jẹ́ ètùtù tí ó péye làti san gbèsè àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ? Bí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyìí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, nígbà náà kí ìwọ kíì o wá fi ìgbẹ́kẹ̀le rẹ sínú Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ. Gbà Òun, nípa ìgbàgbọ́, kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Òun nìkan pátápátá. Gbogbo ohun tí ó nííṣe làti di Kristiẹni nìyẹn!
Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!
Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.
English
Báwo ni mo ṣe le di Kristiẹni?