Ibeere
Kínni ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò?
Idahun
"Létòlétò" túmọ̀ sí wípé kí á fi nǹkan sí ètò àgbékalẹ̀ kan. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò, túmọ̀ sí fífi ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run sí ètò àgbékalẹ̀ kan tí ó ṣàlàyé oríṣi abala tí ó ní. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé nínú Bíbélì sọ nípa àwọn ańgẹ́lì. Kò sí ìwé kankan tí ó sọ ohungbogbo nípa àwọn ańgẹ́lì. Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò kó gbogbo àwọn imọ̀ nípa ańgẹ́lì láti gbogbo ìwé nínú Bíbélì jọ, ó tò wọ́n sí ìpín, tí à ńpè ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa ańgẹ́lì. Ohun tí ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò jẹ́ nì yí—títo àwọn ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run sí àwọn ètò ìsọ̀rí.
Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run Gan-an tàbí Patirọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run Baba. Kristọ́lọjì ni ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run Ọmọ, Jésù Kristi Olúwa. Niumatọ́lọjì ni ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́. Bíbélìọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa Bíbélì. Sotẹriọ́lọjì ni ẹ̀kọ́ nípa ìgbàlà. Ẹklisiọ́lọ́jì ni ẹ̀kọ́ nípa ìjọ. Ẹskatọ́lọjì ni ẹ̀kọ́ nípa òpin ayé Angẹlọ́lọjì ni ẹ̀kọ́ nípa àwọn angẹ́lì. Dimọnọ́lọjì ti Kristiẹni ni ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀mí èṣù láti ìwò Kristiẹni. Antropọ́lọjì ti Kristiẹni ni ẹ̀kọ́ nípa ìran ènìyàn láti ìwò Kristiẹni. Hamatiọ́lọjì ni ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò jẹ́ ohun èlò tí ó ṣe pàtàkì láti ràn wá lọ́wọ́ kí á le ní òye Bíbélì, kí á sì kọ́ọ ní ọ̀nà tí ó létò.
Ní àfikún sí ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò, àwọn ọ̀nà míìrán náà wà tí a lè fi pín ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run ní ìlànà Bíbélì jẹ́ ẹ̀kọ́ lórí ìwe kan (tàbí àwọn ìwé) nínú Bíbélì, tí ó sì tẹnumọ́ oríṣi abala ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run tí ó ńtẹjúmọ́. Fún àpẹẹrẹ, ìhìnrere ti Johannu tẹ̀le ìlànà ti Kristọ́lọjì nitorí ó dá lórí ìjẹ́-Ọlọ́run ti Kristi (Johannu 1:1,14;8;58; 10:30;20:28). Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run tí Onítàn ni ẹ̀kọ́ àwọn ìlànà tí ó dá lórí ìtàn àti bí ìjọ Kristiẹni ṣe ńgbòrò si láti ìgbàdégbà. Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ni ẹ̀kọ́ nípa ìlànà-ẹ̀kọ́ ti àwọn ẹgbẹ́ Kristiẹni kan tí ó ní ẹ̀kọ́ tí ó wà lẹ́sẹ́sẹ́—fún àpẹẹrẹ, Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run ti ìlànà Kaalífìnì àti Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi sáà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run ti ìgbàlódé ni ẹ̀kọ́ lórí àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé tàbí wá sí ojútáyé ní àìpẹ́. Irúfẹ́ ọ̀nà ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run yóòwù tí a bá gbé yẹ̀wò, ohun tí ó ṣe pàtàkì ni wípé à ńkọ́ ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run.
English
Kínni ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run létòlétò?