Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa ẹ̀mí èṣù tí ńgbé ni wọ̀/gbígbé ni wọ̀ ẹ̀mí èṣù? Ṣé ó ṣeé ṣé ní òde òní? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kínni àwọn ààmì?
Idahun
Bíbelì fi àwọn àpẹẹrẹ ènìyàn tí ẹ̀mí èṣù gbé wọ̀ tàbí tí ẹ̀mí èṣù ní ipa lórí wọn hàn. Nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyìí, a le rí àwọn àmì ipa ẹ̀mí èṣù, kí ó sì là wá lọ́yẹ̀ bí ẹ̀mí èṣù ṣe lè gbé ènìyàn wọ̀. Èyí ni àwọn àyọkà Bíbelì náà: Matteu 9:32-33; 12:22; 17:18; Marku 5:1-20; 7:26-30; Luku 4:33-36; Luku 22:3; Iṣe awọn Apọsteli 16:16-18. Nínú àwọn àyọkà yìí, ẹ̀mí èṣù tí ó gbé ni wọ̀ fa àìlera ara bi àìle ṣọ̀rọ̀, àmì wárápá, ìfọ́jú àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ní àwọn ọ̀nà míìrán, ó ńjẹ́ kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ ṣe ibi, Judasi jẹ́ àpẹẹrẹ gbòógì. Nínú Iṣe awọn Apọsteli 16:16-18, ẹ̀mí náà fún ẹrú bìnrin kan ní agbára láti mọ àwọn nǹkan tí ó kọjá ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù gbé wọ̀ ti àwọn ará Gádárà, tí ó ní ẹ̀mí òkùnkùn púpọ̀ (Líjíónì), ní agbára tí ó ju ti ènìyàn lásán lọ, ó sì ńgbé ní ìhòhò láàrín isà òkú. Ẹ̀mí èṣù yọ Sọ́ọ̀lù ọba lẹ́nu, lẹ́hìn tí ó ṣe àìgbọràn sí Olúwa (1 Samuẹli 16:14-15; 18:10-11; 19:9-10), pẹ̀lú ìyọrísí ìbànújẹ́ ọkàn àti ìgbèrò ọkàn tí ó ńgbèrú láti pa Dáfídì.
Fún ìdí èyí, onírúurú ọ̀nà ní àmì ẹ̀mí èṣù tí ó gbé ni wọ̀ lè fi jẹ yọ, bíi àìlera ara tí a kò lè sọ wípé ó jẹ́ ìṣòro ara lásan, ìyípadà ẹ̀dá bí ìbìnújẹ̀ tàbí ìbínú, agbára tó tayọ, ìwà èérì, ìwà tí kò bá àwùjọ mu, agbára láti pín ìmọ̀ tí ènìyàn lásán, Ìyípadà ara ẹni bíi ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìwà ìpáǹle, agbára tí ó ju ti ènìyàn lásán lọ, ìwà ẹhànnà, ìwà tí kò bójú mu, áti agbára láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọjá òye ènìyàn. Ó ṣe pàtàkì kí á mọ̀ pé àwọn àmì wọ̀nyìí lè ní àlàyé míìrán, nítorínáà, Ó ṣe pàtàkì kí á mọ̀ pé kìí ṣe gbogbo ẹnití ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkan tàbí àmì wárápá ni ó ní ẹ̀mí èṣù gbé wọ̀. Ní ọ̀nà míìrán, àṣà ìwà ọ̀làjú kò gbà dájúdájú wípé sàtánì le máa bá àwọn ènìyàn fín ra.
Ní àfikún sí ìyàtọ̀ lára àti lọ́kàn wọ̀nyìí, ènìyàn lè wo àwọn àbùdá l'ẹ́mí tí ó ńfi ipa ẹ̀mí èṣù hàn. Èyi farahàn nínú kíkọ̀ láti dáríjì (2 Kọrinti 2:10-11), ígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ òdì tàbí títan ẹ̀kọ́ òdì kálẹ̀, pàápàá jùlọ nípa Jésù Kristi àti iṣẹ́ ètùtù Rẹ̀ (2 Kọrinti 11:3-4, 13-15; 1 Timoteu 4:1-5; 1 Johannu 4:1-3).
Nípa ti lílọ́wọ́sí ti ẹ̀mí èṣù nínú ayé Kristiẹni, Àpóstélì Peteru jẹ̀ àpẹ̀ẹrẹ ònígbàgbọ́ tí ẹ̀mí èṣù yálò (Matteu 16: 23). Àwọn míìrán gbà ki wọn pe àwọn Kristiẹni tí wọn wà lábẹ́ ipa ẹ̀mí èṣù ni "ẹni tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso ẹ̀mí èṣù", ṣùgbọ́n kò sí àpẹ̀ẹrẹ ònígbàgbọ́ nínú Kristi tí ẹ̀mí èṣù gbé wọ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Púpọ̀ nínú àwọn onímọ̀ nípa bíbélì gbàgbọ́ wípé ẹ̀mí èṣù kò lè gbé Kristiẹni wọ̀ nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ńgbé inú wọn. (2 Kọrinti 1:22; 5:5; 1 Kọrinti 6:19), bẹ́ẹ̀ni Ẹ̀mí Ọlọ́run kò lè gbé papọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí èṣù.
A gbọ̀ bí àwọn ènìyàn ti má ńṣílẹ̀kùn ayé wọn ṣílẹ̀ fún ẹ̀mí èṣù. Bí ti Júdàsi bá jẹ́ àpẹ̀ẹrẹ, ó ṣílẹ̀kùn ọkàn rẹ̀ ṣílẹ̀ fún ibi – nípa ojúkòkúrò rẹ̀ (Johannu 12:6). Èyí túmọ̀ sí wípé, bí ènìyàn bá fi ààyè gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè lọkàn rẹ̀ lemólemó, ó le fún ẹ̀mí èṣù láyè láti wọlé. Láti inú ìrírì àwọn Míṣánnárì, a gbà wípé, ẹ̀mí èṣù le wọ inú àwọn tí ó bá ńsin òrìṣà tàbi àwọn tí ó ní ẹrù ẹgbẹ́ òkùnkùn lọ́wọ́. Ìwé mímọ́ tẹnu mọ́ wípé sínsin òrìṣà kò yàtọ̀ sí sínsin ẹ̀mí èṣù (Lefitiku 17:7; Deutarọnọmi 32:17; Orin Dafidi 106:17; 1 Kọrinti 10:20), nítorí náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu wípé sínsin òrìṣà le fa kí ẹ̀mí èṣù gbé ni wọ̀.
Láti inú àwọn àyọkà òkè yìí áti àwọn ìrírì àwọn Míṣánnárì, a lè sọ wípé, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni ó má ńṣílẹ̀kùn ayé wọn ṣílẹ̀ fún ẹ̀mí èṣù nípa gbígba ẹ̀ṣẹ̀ láàyè tàbi lílọ́wọ́sí ẹgbẹ́ òkùnkùn (bóyá wọ́n mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀). Àpẹ̀ẹrẹ èyí ni ìwà àìmọ́, àṣìlò òògùn olóró/ọtí tí ó le ṣe ènìyàn gángàngán, ìṣọ̀tẹ̀, àrankàn àti ṣíṣàṣàrò tí ó ńpín ọkan àti ara sọ́tọ̀.
Ó tún ní àfikún kan. Sàtánì àti àwọn ọmọ ogun ibi rẹ̀ kò lè ṣe ohunkóhun bíkòṣe wípé Olúwa bá gbà wọ́n láàyè (Jobu 1-2). Níbí yìí, Sàtánì rò wípé, òhun ńṣe ìfẹ́ ara òhun ni, kò mọ̀ wípé ìfẹ́ Ọlọ́run ni òhun ńṣe, gẹ́gẹ́ bíi tí Judasi tí ó da Jésù. Àwọn ènìyàn kan bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ràn, tí kò dára, sí iṣẹ́ ẹ̀mí èṣù àti ẹgbẹ́ òkùnkùn. Èyí kò mú ọpọlọ wá tàbí bá bíbélì mu. Bí a bá lépa Ọlọ́run, tí a sì gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, tí a sì gbẹ́kẹ̀le agbára Rẹ̀, kò sí ohun kankan láti bẹ̀rù, nítorí Ọlọ́run ńjọba lórí ohun gbogbo.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa ẹ̀mí èṣù tí ńgbé ni wọ̀/gbígbé ni wọ̀ ẹ̀mí èṣù? Ṣé ó ṣeé ṣé ní òde òní? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kínni àwọn ààmì?