Ibeere
Kínní ìdí tí àwọn ènìyàn nínú ìwé Jẹnẹsisi ṣe ní ẹ̀mí gígùn tí ó pẹ́ bẹ́ẹ̀?
Idahun
Ó jẹ́ àdìtú bí àwọn ènìyàn inú orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹnẹsisi ṣe gbé fún ìgbà tó pẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwọn onímọ̀ Bíbélì ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlànà síwájú. Àkọsílẹ̀ ìrandíran inú Jẹnẹsisi 5 fi àkọsílẹ̀ ìran mímọ́ Sẹ́tì hàn—ìran tí ó padà bí Mesiah. Ó ṣé e ṣe wípé Ọlọ́run bùkún ìran yìí lọ́tọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mì gígùn nítorí ìwà mímọ́ àti ìgbọràn wọn. Nígbàtí èyí jẹ́ àlàyé tí ó ṣeé ṣe, kò sí ibi kankan tí Bíbélì ti fi ìwọ̀n ní pàtó sí ẹ̀mì gígùn àwọn tí a dárúkọ nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 5. Síwájú síi, lẹ́yìn Énọ́kù, Jẹnẹsisi orí 5 kò sọ nípa ẹnìkan tí ó ní ìwà bíi Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ wípé gbogbo ènìyàn lákókò náà gbé fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rún ọdún. Ọ̀pọ̀lọpọ́ ìdí ló lè dákún èyí.
Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ nígbà ìkún omi láti dín ẹ̀mí ènìyàn kù. Ṣe àfiwé ẹ̀mì gígùn kí ìkún omi tó dé (Jẹnẹsisi 5:1-32) pẹ̀lú ti ẹ́yìn ìkún omi (Jẹnẹsisi 11:10-32). Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìkún omi, àwọn ọdún náà díkù gidigidi, ó sì ńdíkù lọ. Nǹkan pàtàkì kan wà nínú Jẹnẹsisi 6:3: "Olúwa sì wípé," Ẹ̀mí mi kì yíò fi ìgbà-gbogbo ba ènìyàn jà, ẹ́ran ara sáà li òun pẹ̀lú. Ọjọ́ rẹ̀ yíò sì jẹ́ Ọgọ́fà ọdún". Ọ̀pọ̀ ènìyàn rí atọ́ka sí "ọgọ́rún kan àti ogún ọdún" gẹ́gẹ́ bíi gbèdéke titun tí Ọlọ́run yàn fún ọjọ́ orí ènìyàn. Ní àkókò Mósè ( tí ó gbé fún Ọgọ́fà ọdún), gígùn ẹ̀mì kéré si. Lẹ́yìn Mósè, kò sí àkọsílẹ̀ ẹnikẹ́ni tó gbé ju ọgọ́fà ọdún lọ.
Ẹ̀kọ́ kan fún ìdí tí àwọn ènìyàn inú Jẹnẹsisi ṣe gbé fún ìgbà tó pẹ́ bẹ́ẹ̀ dálé lórí pé àgbá omi yí ayé ká. Gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀kọ́ àtíbàbà náà, omi tí ó wà "lókè ofurufu" (Jẹnẹsisi 1:7, KJV) ṣẹ̀dá ipa àtíbàbà tí ó dí ọ̀pọ̀ ìmọ́lẹ̀ tí ó bá ayé, èyí jásí ìgbé-ayé tí o bójúmu. Ní àkókò ìkún omi, a tú àgbá omi sórí ayé (Jẹnẹsisis 7:11), ó fi òpin sí àyíká tí o bójúmu. Ọ̀pọ̀lọọ̀ àwọn onimọ̀ nípa íṣẹ̀dá ti kọ ẹ̀kọ́ àtíbàbà sílẹ̀ lónìí.
Àgbéyẹ̀wò míìrán ni wípé, ni àwọn ìran àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀dá, wípé kóòdù jẹ̀nẹ́tiki ìran ènìyàn ti ní àwọn àbùdá àṣìṣe kan. A dá Àdàmù àti Éfà ní pípé. Ó dájú wípé wọn ní àjẹsára tí ó ga sí àìsàn àti àìléra. Ìran wọn kò bá ti jogún àwọn àǹfàní wọ̀nyìí, bí ó tilẹ̀ lè kéré díẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀, àwọn kóòdù jẹ̀nẹ́tiki ìran ènìyàn díbàjẹ́ síwájú si, tí àwọn ènìyàn sì ńṣe alábápàdé ikú àti àìsàn síi. Èyí sìí le fa kí ọdún náà dínkù gidigidi.
English
Kínní ìdí tí àwọn ènìyàn nínú ìwé Jẹnẹsisi ṣe ní ẹ̀mí gígùn tí ó pẹ́ bẹ́ẹ̀?