settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé Kristiẹni gbọ́dọ̀ ṣe eré ìdárayá? Kínni Bíbélì sọ nípa ìlera?

Idahun


Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ní ayé, àwọn àṣejù wà nípa eré ìdárayá. Àwọn míìrán kọjú mọ́ jíjẹ́ ènìyàn ẹ̀mí, dé ibi tí wọn kò bìkítà nípa ara wọn. Àwọn míìrán kọjú mọ́ ipò àti àbùdá àgọ́ ara wọn dé bi wípé wọn kò bìkítà nípa ìdàgbàsókè ẹ̀mí wọn. Kò sí èyí tí ó túmọ̀ sí pípéye nínú méjèèjì gẹ́gẹ́ bíi ìlànà Bíbélì. Ìwé Timoteu Kínní 4:8 fi yé wa wípé "Nítorí ṣíṣe eré ìdárayá ní èrè díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ní èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ayé ìsisìyí àti ti èyí tí ńbọ̀" Ṣe àkíyésìí wípé ẹsẹ̀ yí kò tako ṣíṣe eré ìdárayá. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ńsọ wípé eré ìdárayá wúlò, ṣùgbọ́n ó gbé eré ìdárayá dáradára nípa bí ó ti sọ pé ìwà-bí-Ọlọ́run ní èrè tó ga jùú lọ.

Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù náà tún sọ nípa ìdárayá ní ṣíṣe àlàyé òtítọ́ nípa ẹ̀mí nínú ìwé Kọrínti Kínní 9:24-27. Òun ṣe àfiwé ìgbé-ayé Kristiẹni pọ́ọ̀lú eré-ìje tí ènìyàn ńsá "láti gba èrè." Ṣùgbọ́n èrè tí àwa ńwá ni adé ayérayé tí kò ní ṣá tábí díbàjẹ́. Nínú ìwé Timoteu Kejì 2:5 "Bí ẹnikẹ́ni bá sì ńjà, a kì dé e lí adé, bíkòṣepé ó bá jà lí àìṣe ẹ̀rù." Pọ́ọ̀lù tún lo àfiyé ẹni tí ńsáré ìje nínú ìwé Timoteu Kejì 4:7: "Èmi ti ja ìjà rere, èmi ti parí ìre-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́." Nígbàtí àfojúsùn àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ yìí kìí ṣe ti eré ìdárayá, òtítọ́ ni wípé Pọ́ọ̀lù lo àyálò àwọn tí ńsáré ìje láti kọ́ wa ní òtítọ́ nípa ẹ̀mí tọ́ka sí wípé Pọ́ọ̀lù wo eré ìdárayá àti ìdíje ní ìhà tí ó dára. A jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀mí. Sísọ ní ìlànà pẹ̀lú Bíbélì, abala ẹ̀mí wa ṣe pàtàkì jù, a kò gbọ́dọ̀ pa ìlera abala ẹ̀mí àti àgọ́ ara wa tì.

Nítorí náà, kò sí ohun tí ó burú nínú kí Kristiẹni ṣe eré ìdárayá. Kódà bíbélì sọ kedere wípé kí á ṣe ìtọ́jú ara wa dáradára (1 Kọrinti 6:19-20). Nígbà kanná, Bíbélì ṣe ìkìlọ̀ nípa asán (1 Samuẹli 16:7; Òwe 31:30; 1 Peteru 3:3-4). Èròńgbà wa nípa eré ìdárayá kò gbọ́dọ̀ jẹ́ láti tún dídára ara wa ṣe kí àwọn ènìyàn lè rí wá kí wọ́n sì máa jíwa wò, kí á sì dáwọn lọ́rùn. Dípò èyí, èròńgbà fún eré ìdárayá yẹ kí ó jẹ́ láti tún ìlera ara wa ṣe kí a ba lè ní okun lára láti fi ara wa jìn fún ìlepa ẹ̀mí.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé Kristiẹni gbọ́dọ̀ ṣe eré ìdárayá? Kínni Bíbélì sọ nípa ìlera?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries