Ibeere
Kínni ìwò Kristiẹni nípa sìgá mímu? Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni sìgá mímu?
Idahun
Bíbélì kò mẹ́nuba sìgá mímu ní tààrà. Ṣùgbọ́n, àwọn ìlànà wà, tí ó kan sìgá mímu. Àkọ́kọ́, Bíbélì paá láàṣẹ fún wa kí á máse gbà kí ara wa jẹ́ "ọ̀gá" wa 'ípasẹ̀ ohunkóhun. "Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi—ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi—ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí á fi mí sábẹ́ agbára ohunkóhun" (1 Kọrinti 6:12). Sìgá mímu láì ṣe àríyànjiyà jẹ́ bárakú tí ó le. Nínú àyọkà a sọ fún wa wípé, "Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, tí ńbẹ nínú yín, tí ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì sí ì ṣe ti ara yín; nítorí a ti rà yín ní iye kan. Nítorínà ẹ yin Ọlọ́run lógo nínú ara yín" (1 Kọrinti 6:19-20). Sìgá mímu láì ṣiyèméjì, kò dára fún ìlera rẹ. A ti ṣe àfihàn wípé sìgá mímu lè ba àwọn ẹ̀dọ̀-fóró àti ọkàn jẹ́.
Ṣé a lè ní sìgá mímu ní "àǹfààní" (1 Kọrinti 6:12)? Ṣé a lè sọ wípé sìgá mímu jẹ́ bíbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run pẹ̀lú ara rẹ̀ (1 Kọrinti 6:20)? Ṣé ẹnìkan lè mu sìgá "fún ògo Ọlọ́run" l'ótìítọ́ (1 Kọrinti 10:31)? A gbàgbọ́ wípé ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọnyi jẹ́ "bẹ́ẹ̀kọ́" tó rinlẹ̀. Fún ìdí éyí, a gbàgbọ́ wípé sìgá mímu jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nítorínà kò yẹ kí àwọn ọmọ-lẹ́hìn Jésù Kristi máa mú.
Àwọn kan jiyàn tako ìwò yìí nípa títọ́kasí òdodo ọ̀rọ̀ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ńjẹ oúnjẹ tí kò ṣe ara lóore, tí ó sì lè jẹ́ bárakú bí ó ti lòdì fún ara. Fún àpẹẹrẹ, òògùn káfììnì ti di bárakú fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láìsí ìránlọ́wọ́ tó jẹ́ wípé wọn kò lè ṣe nǹkan dáradára láì mu ife kọfí àkọ́kọ́ ní àárọ̀. Bí èyí ti jẹ́ òtítọ́, kí ló wá mú kí sìgá mímu tọ̀nà? Nínú ìwòye wa wípé kí àwọn Kristiẹni yàgò fún wọ̀bìà àti jíjẹ ohun tí kò ṣe ara lóore l'ápòjù. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Kristiẹni jẹ́ alágàbàgebè láti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan l'ẹ́ẹ̀bi kí á sì faramọ́ òmííràn, ṣùgbọ́n, èyí kò mú kí sìgá mímu bu ọlá fún Ọlọ́run.
Àríyànjiyàn míìrán tako ìwò sìgá mímu ni wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ńmu sìgá, bíi gbajúmọ̀ oníwàásù òyìnbó C.H. Spurgeon, ẹnití a mọ̀ wípé o mu sìgá. Lẹ́ẹ̀kansíi, a kò gbàgbọ́ wípé àríyànjiyàn yìí gbé ìwọ̀n kankan. A gbàgbọ́ wípé Spurgeon ṣe àṣìṣe láti máa mu sìgá. Ṣé kìí ṣe ọmọ Ọlọ́run àti olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gidi? Pátápátá! Ṣé ìyẹn mú kí gbogbo àwọn ìṣe àti ìhùwàsí rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run bí? Bẹ́ẹ̀kọ́.
Nínú sísọ wípé ẹ̀ṣẹ̀ ni sìgá mímu, a kò sọ wípé gbogbo àwọn tó ńmu sìgá kò tíì di ẹni ìgbàlà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́ tòótọ́ nínú Jésù Kristi ńmu sìgá. Sìgá mímu kò dí ènìyàn lọ́wọ́ láti di ẹni ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ni kò sì mú kí ènìyàn kó pàdánù ìgbàlà rẹ̀. Ìdáríjìn sìgá mímu kò tó ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yòókù, bóyá fún ẹnití ó fẹ́ di onígbàgbọ́ tàbí onígbàgbọ́ tí ó ńjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ sí Ọlọ́run (1 Johannu 1:9). Ní àkókò kańnáà, a gbàgbọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ wípé sìgá mímu jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a gbọdọ̀ kọ̀ sílẹ̀ àti, pẹ̀lú ìrànlọ̀wọ̀ Ọlọ́run, borí.
English
Kínni ìwò Kristiẹni nípa sìgá mímu? Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni sìgá mímu?