settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò?

Idahun


L'ọ́nà tí ó gbòòrò, púpọ̀ nínú àwọn ohun tí àwọn ènìyàn ńwá lórí ayélujáre ló ní íṣe pẹ̀lú wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò. Wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò wọ́pọ̀ ní ayé òde òní. Bóyá ju ǹkankan lọ, Sàtánì ti yege láti lọ́jú àti láti yí ìbálòpọ̀ po. Ó ti mú ohun tí ó dára tí ó sì tọ́ kúrò (ìfẹ́ ìbálòpọ̀ láàrin ọkọ àti ìyàwó) ó sì rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́kùfẹ́, àwòrán ènìyàn ní ìhòhò, àgbèrè, ìfipá bá'ni lòpọ̀, àti àṣà ìbáló ọkùnrin sí ọkùnrin tàbí obìnrin sí obìnrin. Àwòrán ènìyàn ní ìhòhò lè jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lórí gegele tó ńyọ̀ fún ìwà ìkà àti àgbèrè (Romu 6:19). Àkọsílẹ̀ gidi wà fún ìwà bárakú ti wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò. Bí olóògùn olóró ti ńgbọ́dọ̀ mu ọ̀pọ̀ ìwọ̀n ògùn náà tàbí ògùn tí ó l'ágbára síi láti lè dé ìpele "gíga," bẹ́ẹ̀ni wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò ńsún ènìyàn wọnú àti sínú ìbálòpọ̀ líle àti ìfẹ́kùfẹ́ àìwàbíọlọ́run.

Kókó ìpele mẹ́ta ẹ̀ṣẹ̀ ni ìfẹ́kùfẹ́ ara, ìfẹ́kùfẹ́ ojú àti ìrera ayé (1 Johannu 2:16). Wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò má ńjẹ́ kí á ní ìfẹ́kùfẹ́ ara, àti láì ṣe àríyànjiyàn ìfẹ́kùfẹ́ oju. Wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò kò tó ohun tí a le máa rò, gẹ́gẹ́ bíi Filippi 4:8. Wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò jẹ́ bárakú (1 Kọrinti 6:12; 2 Peteru 2:19) àti ìparun (Owe 6:25-28; Esikiẹli 20:30; Efesu 4:19). Ìfẹ́kùfẹ́ ẹlòmíràn ní ọkàn wa, èyítí ó jẹ́ gbòǹgbò wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò, ńbí Ọlọ́run nínú (Matteu 5:28). Nígbàtí ayé ènìyàn bá ti farajìn sí àṣà wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò tí òun sì ńtẹ̀síwájú láti máa dá ẹ̀ṣẹ̀ láì wá ìránlọ́wọ́, tí kò sì gbìyánjú láti fi òpin síi tàbí kó wu láti yí ìwà rẹ̀ padà, ó ńfihàn wípé ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì di ẹni ìgbàlà (1 Kọrinti 6:9-12).

Fún àwọn tí ńwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò, Ọlọ́run lè, yóò sì fún yín ní ìṣẹ́gun. Ṣé ìwọ ńwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò tí ìwọ sì fẹ́ òmìnira kúrò nínú rẹ̀? Èyí ni àwọn ìgbésẹ̀ sí ìṣẹ́gun: 1) Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sí Ọlọ́run (1 Johannu 1:9). 2) Bèèrè kí Ọlọ́run ó wẹ̀ ọ́ mọ́, kí Òun sì ra ọkàn rẹ padà (Romu 12:2). 3) Bèèrè kí Ọlọ́run kún inú rẹ pẹ̀lú ohunkóhun tíi ṣe òótọ́, ọ̀wọ̀, títọ́, mímọ́, fífẹ́, àti ìròyìn rere (Filippi 4:8). 4) Kọ́ láti pa ara rẹ mọ́ ní mímọ́ (1 Tẹsalonika 4:3-4). 5) Mọ ìtumọ̀ ìbálòpọ̀ tó yẹ kí o sì gbáralé ẹnìkejì rẹ nìkan làti bá àìní náà pàdé (1 Kọrinti 7:1-5). 6) Mọ̀ dájú wípé tí o bá ńrìn nípa ti Ẹ̀mí, ìwọ kì yóò sì mú ìfẹ́kùfẹ́ ara ṣẹ (Galatia 5:16). 7) Gbé ìgbésẹ̀ ìṣe láti dín ìfihàn rẹ̀ sí àwòrán kú. Fi olùdènà sí àwòrán ènìyàn ní ìhòhò sí orí ẹ̀rọ ayára-bí-àsá rẹ, dín wíwo amóhùnmáwóràn àti lílo fídíò kù, kí o sì wá onígbàgbọ́ míìrán tí ó lè gbàdúrà fún ọ tí yóò sì ma mú ọ ṣe déédé.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries