Ibeere
Kínni ètùtù arọ́pò náà?
Idahun
Ètùtù arọ́pò náà túmọ̀ sí kíkú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi pàṣíìpàrọ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ìwé Mímọ́ kọ́ wa wípé gbogbo ènìyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀ (Romu 3:9-18, 23). Ikú ni ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ìwé Romu 6:23 sọ wípé, "Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa."
Ẹsẹ yẹn kọ́ wa ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Láìsí Kristi, àwa yóò kú tí a ó si lo ayérayé ní ọ̀run-àpáàdì gẹ́gẹ́ bí ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ikú nínú Ìwé Mímọ́ túmọ̀ sí "ìyapa". Gbogbo ènìyàn ni yóò kú, ṣùgbọ́n àwọn kan yóó yè, wọn ò sì máà gbé pẹ̀lú Olúwa ní ayérayé, nígbàtí àwọn kan yòó gbé ayérayé wọn ní ọ̀run-àpáàdì. Ikú tí à ńsọ níbí ni ayé ní ọ̀run àpáàdì. Ṣùgbọ́n, nǹkan kejì tí ẹsẹ yìí ńkọ́ wa ni wípé ìyè ayérayé wà nípasẹ̀ Jésù Kristi. Èyí ni ètùtù arọ́pò Rẹ̀.
Jésù kú ní ipò wa nígbàtí a kàn mọ́ àgbélèbú. Àwa ló yẹ kí á kàn mọ́ igi àgbélèbú nàá láti kú nítorí wípé àwa ni a gbé-ìgbé ayé ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n Kristi gba ìjìyà náà jẹ fún wa—Òun fi ara rẹ̀ rọ́pò, tí Òun si gba ìyà tí ó tọ́ sí wa jẹ. "Kristi kò dẹ́ṣẹ̀. Sibẹ nítorí tiwa, Ọlọrun sọ ọ́ di ọ̀kan pẹlu ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí á lè di olódodo níwájú Ọlọrun nípa rẹ̀ "(2 Kọrinti 5:21).
"Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá " (1 Peteru 2:24). Síwájú si a ríi wípé Kristi gba ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa dá si ara Rẹ̀ nípa sísan gbèsè náà fún wa. Ẹsẹ díẹ̀ sílẹ̀ kà wípé, "Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí " (1 Peteru 3:18). Àwọn ẹsẹ wọ̀nyìí kò kọ́ wa nípa ìrọ́pò tí Kristi ṣe fún wa nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n kọ́ wa wípé Òun gan ni ètùtù, tí ó túmọ̀ sí wípé ó san gbogbo gbèsè tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn.
Ẹsẹ kan tí ó tún sọ nípa ètùtù arọ́pò náà ni ìwé Isaiah 53:5. Ẹsẹ yìí sọ nípa Kristi tí ó ńbọ̀ láti kú lórí àgbélèbú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àsọtẹ́lẹ̀ nàá jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kíkànmọ́ àgbélèbú náà rí gẹ́gẹ́ bí a ti sọ. "Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ́ nítorí irekoja wa, ina alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ina rẹ̀ li a fi mu wa lara da." Kíyèsí ìrọ́pọ̀ nàá. A tún ri ní ibíyí wípé Kristi san gbèsè nàá fún wa!
Ọ̀nà kan soso tí àwa le fi san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ nàá ni nípa ìjìyà àti lílo ayérayé ní ọ̀run-àpáàdì. Ṣùgbọ́n Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, wá sí ayé láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa. Nítorí tí ó ṣe èyí fún wa, àwa wá ní àǹfàní tí kìí ṣe láti rí ìdáríjì nìkan fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣùgbọ́n láti lo ayéráyé pẹ̀lú Rẹ̀. Láti ṣe èyí, àwa ní láti fi ìgbàgbọ́ sí ohun tí Kristì ṣe lórí igi àgbélèbú. Àwa kò lè gba ara wa là; a nílò arọ́pò kan láti gba ipò wa. Ikú Jésù Kristi sì ni ètùtù arọ́pò nàá.
English
Kínni ètùtù arọ́pò náà?