Ibeere
Ṣé ó tọ̀nà fún Kristiẹni kan láti ṣe ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbì fẹ́ ẹni tí kìí ṣe Kristiẹni?
Idahun
Fún Kristiẹni kan, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ẹni tí kìí ṣe Kristiẹni jẹ́ aláìgbọ́n, àti fí fẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ kìí ṣe èyí tí a lè yàn. Kọrinti keji 6:14 (KJV) sọ fún wa láti má ṣe fi "àìdọ́gba dàpọ̀" pẹ̀lú aílàìgbàgbọ́. Àwòrán yìí jẹ́ bíi akọmàálù tí kò báramu tí wọn jọ ńpín àjàgà kan náà. Dípo kí wọn jùmọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ láti fa ẹrù náà, wọn a ma ṣiṣẹ́ lòdì sí ara wọn. Nígbà tí ẹsẹ yìí kò mẹ́nuba ìgbéyàwó ní pàtó, ni dandan o ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìgbeyàwó. Ẹsẹ̀ náà tẹ̀sìwájú láti sọ wípé kò sí ìṣọ̀kan láàrín Kristi àti Bélíálì (Sàtánì). Kò lè sí ìṣọ̀kan tẹ̀mí nínú ìgbéyàwó láàrín Kristiẹni kan àti ẹni tí kìí ṣe Kristiẹni kan. Pọ́ọ̀lù tẹ̀síwájú láti rán àwọn onígbàgbọ́ létí wípé àwọn ni ibùgbé ti Ẹ̀mí Mímọ́, tì ńgbé nínú àwọn ọkàn wọn láti ìgbà ìgbàlà (2 Korinti 6: 15-17). Nítorí ìdí yẹn, wọn ní láti yàtọ sí ti ayé—nínú ayé náà, ṣùgbọ́n kìí ṣe ti ayé—àti wípé kò sí ibi tí ìyẹn ti ṣe pàtàkì jùlọ nínú ayé ju ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́—ìgbéyàwó.
Bíbélì tún sọ wípé, "Kí a má tàn yín jẹ: 'Ẹgbẹ́ búburú ba ìwà rere jẹ́' (1 Kọrinti 15:33). Níní èyíkèyí ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú aláígbàgbọ́ lè mú kí a tètè yípadà sí ohun tí yóò jẹ́ ìdènà sí ìrìn rẹ pẹ̀lú Kristi. A pè wá láti jí ìhìnrere fún àwọn tí ó ti sọnù, kìí ṣe láti wà ní tímọ́tímọ́ pẹ̀lú wọn. Kò sí ohun tí o burú ní kíkọ́ ìrẹ́pọ̀ tí o dára pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ó ti yẹ kí o mọ ní yẹn. Bí o bá ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́, kínni yóò ṣe pàtàkì jùlọ fún ọ, fífi ìfẹ̀ hàn tàbí jíjèrè ọkàn fún Kristi? Bí o bá ti ṣè gbèyáwò pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kan, báwo ní ẹ̀yin méjèèjì yóo ṣe kọ́ wíwà ní tímọ́tímọ́ ní tẹ̀mí nínú ìgbéyàwó yin? Báwo ni ìgbeyàwó tí o dára ṣe lè dí kíkọ́ kí a sì ṣe àkóso bí ẹ kò bá gbà lórí ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ní àgbáyé—Jésù Kristi Olúwa wa?
English
Ṣé ó tọ̀nà fún Kristiẹni kan láti ṣe ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbì fẹ́ ẹni tí kìí ṣe Kristiẹni?