Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa ìbáṣepọ̀/ ìbádọ́rẹ̀ẹ́?
Idahun
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ọ̀rọ̀ " ìbádọ́rẹ̀ẹ́" àti "ìbáṣepọ̀" náà ni a kò ríi nínú Bíbélì, a fún wa ní àwọn ìlànà kan èyítí o yẹ kí àwọn Kristiẹni sì tẹ̀lé ní àkókò tí ó ṣáájú ìgbeyàwó. Àkọ́kọ́ ni wípé a gbọ́dọ̀ pìnyà kúrò ní ojú ìwòye ti ayé lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ nítorí ọ̀nà ti Ọlọ́run tako ti ayé (2 Peteru 2:20). Ìwòye ti ayé lè jẹ́ láti ṣe ìbádọ́rẹ̀ẹ́ káàkiri bíi a bá ṣe fẹ́, ohun tí o ṣe pàtàkì jù ni láti ṣe àwárí ìwà ẹ́ni náà ṣáájú ṣíṣe ìpinnu ifaraji síi lọ́kùnrin tàbí l'óbìnrin. A gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí bí ẹni náà bá ti jẹ́ àtúnbí nínú Ẹmí ti Kristi (Johannu 3:3-8) àti bí òùn l'ọ́kùnrin tàbí l'óbìnrin bá ní ìfẹ́ kannáà pẹ̀lú dídàbii Kristi (Filippi 2:5). Ìlépa pátápátá kan ti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbí ìbáṣepọ̀ ní wíwá alábaṣepọ̀ ayé kan. Bíbélì náà sọ fún wa wípé, gẹ́gẹ́ bíi àwọn Kristiẹni, a kò gbọ́dọ̀ fẹ́ aláìgbàgbọ̀ (2 Kọrinti 6:14-15) nítorí wípé èyí yóò sọ ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Kristi dí aláìlàgbára ti yóò si mú àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ìpìlẹ̀ wa gbọ̀jẹ̀gẹ́.
Nígbàtí ènìyàn báwà nínú ìbáṣepọ̀ tí ó fọkànsí, bóyá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbí ìbáṣepọ̀, ó ṣe pàtàkì láti rántí fẹ́ràn Ọlọ́run lékè ohun gbogbo (Matteu 10:37). Láti sọ tàbí gbàgbọ́ wípé ẹnìkan jẹ́ "ohun gbogbo" tàbí pàtàkì jùlọ nínú ayé ti ẹni jẹ́ ìbọ̀rìṣà, èyìtí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ (Galatia 5:20; Kolosse 3:5). Bákannáà a kò gbọ́dọ̀ ba àgọ́ ara wá jẹ́ nípa níní ìbálòpọ̀ láì tìí ṣe ìgbéyàwó (1Kọrinti 6:9, 13; 2 Timoteu 2:22). Ìbálòpọ̀ aláìmọ̀ jẹ ẹ̀ṣẹ̀, kìí ṣe lòdì sí Ọlọ́run nìkan ṣùgbọ́n lòdì sí àgọ ara wa (1 Kọrinti 6:18). Ó ṣe pàtàkì láti nì ìfẹ́ àti bú ọlá fún àwọn míìrán bí a ṣe fẹ́ràn ara wa (Romu 12:9-10), èyí sì jẹ́ òtítọ́ tí ó dájú fún ìbáṣepọ̀ tàbí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan. Yálà ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbí ìbáṣepọ̀, tí tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú bíbélì jẹ́ ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ní ìpìlẹ̀ tí ó ní ààbò fún ìgbéyàwó kan. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpinnu pàtàkì jùlọ èyí tí àwa yóò ṣe, nítori ní ìgba tí ẹni méjì bá fẹ́ra wọ́n, wọn yóò so papọ̀ wọn yóò si di ara kan nínú ìbáṣepọ̀ èyítí Ọlọ́run fẹ́ kó jẹ́ fún ayérayé àti aláìletúká (Jẹnẹsisi 2:24; Matteu 19:5).
English
Kínni Bíbélì sọ nípa ìbáṣepọ̀/ ìbádọ́rẹ̀ẹ́?