settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ Ṣíṣe Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan? Kínni àwọn Mọ́mọ́nì gbàgbọ́?

Idahun


Ẹ̀sìn Mọ́mọ́nì (Ṣiṣe Mọ́mọ́nì), àwọn tí olùtẹ̀lé wọn jẹ́ àwọn tí a mọ̀ sí àwọn Mọ́mọ́nì àti àwọn Ẹní mímọ́ ti Ọjọ́ tí ó Kẹ́hìn (LDS), tí a dásílẹ̀ ní ó kéré sí bíi igba ọdún sẹ́yìn nípa ọkùnrin kan tí órúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Jósẹ́fù Smith. Òun jẹ́wọ́ wípé òhun ní ìbẹ̀wò ti ara ẹni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Krísti tí ó sọ fún òun wípé gbogbo àwọn ìjọ àti àwọn àgbékalẹ̀ wọn jẹ́ ìríra. Jósẹ́fù Smith wá bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn àkọ̀tun tí ó ńgbà láti jẹ́ "ìjọ òtítọ́ kan ṣoṣo lórí ayé." Ìṣòro tí ó wà pẹ̀lú ṣíṣe Mọ́mọ́nì ni wípé ó ńtako, ṣe àtúnṣe, àti fífẹ̀ Bíbélì lójú. Àwọn Kristiẹni kò ní ìdí láti gbàgbọ́ wípé Bíbélì kò jẹ́ òtítọ́ àti kún ojú òṣùwọ̀n. Láti gbàgbọ́ ní tòótọ́ kí a sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run túmọ̀ sí láti gbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ti gbogbo Ìwé Mímọ́ jẹ́ ìmísí nípa Ọlọ́run, èyí tí ó túmọ̀ sí wipé ó wá láti ọ̀dọ Rẹ̀ (2 Timoteu 3:16).

Kódà Mọ́mọ́nì gbàgbọ́ wípé àwọn orìsun mẹ́rin ti ọ̀rọ̀ ìmísí àtòkèwá lówà, kìí kan ṣe ẹyọ̀kan: 1) Bíbélì "níwọ̀n ìgbà tí a ti ṣe ìtúmọ̀ sí èdè míràn dáradára." È wo nínú àwọn ẹsẹ̀ wo là ńsọ wípé a kò ṣe ìtúmọ̀ rẹ̀ dáradára, èyí kò hàn kedere. 2) Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyí "tí a túmọ̀" nípasẹ̀ Smith ti a tẹ̀jáde ní 1830. Smith gbà wípé ó jẹ́ "ìwé tí ó péye jùlọ" lóri ayé àti wípé ènìyàn lè súnmọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀ "jú nípa ìwé míìrán lọ." 3) Àwọn Ẹ̀kọ́ àti Àwọn májẹ̀ẹ́mù, tí ó kún fún àkójọpọ̀ àwón àkójọpọ̀ àwọn ìfihàn ìgbàlódé tí ó ní "Ìjọ ti Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe múpadàbọ̀sípò." 4) Àwọn Píálì ti Ìdíyelé Ńlá, èyí tí à ńkà sí àwọn Mọ́mọ́nì láti "sọ di mímọ̀" àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ tí a pàdánù láti inú Bíbélì tí a ṣe àfikún ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá t'ayé.

Àwọn Mọ́mọ́nì gbà àwọn nǹkàn wọ̀nyìí gbọ́ nípa Ọlọ́run: Òun kò fi ìgbà kan jẹ́ Ẹ̀dá tí ó ga jùlọ ní gbogbo àgbáyé, ṣùgbọ́n dé ìpele náà nípa ìgbé-ayé ìṣododo àti ipá ìtẹpẹlẹmọ́. Wọ́n gbàgbọ̀ wípé Ọlọ́run Baba ní "àgọ́ ara àti egungun gẹ́gẹ́ bíi ti ènìyàn tí ó ṣeé dìnmú. Bí ò tìlẹ́ jẹ́ wípé àwọn àgbàgbà Mọ́mọ́nì tí òde òní ti kọ̀ọ́ sílẹ̀, Brigham Young ńkọ́ni wípé Ádámù tilẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run àti Bàba Jésù Kristi. Ní ìdákèjì, àwọn Kristiẹni mọ̀ èyí nípa Ọlọ́run: Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo ló wà (Deutarọnọmi 6:4; Isaiah 43:10; 44:6-8), àti Òun tì wà láàyè tẹ́lẹ̀ àti wà láàyè nígbàgbogbo (Deutarọnọmi 33:27; Orin Dafidi 90:2; 1 Timoteu 1:17), àti kò sí ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣùgbọ́n òún jẹ́ Aṣẹ̀dá (Jẹnẹsisi 1; Orin Dafidi 24:1; Isaiah 37:16). Ọún jẹ́ pípé, kò sí sí ẹni tí ó lè bá A dọ́gba (Orin Dafidi 86:8; Isaiah 40:25). Ọlọ́run Baba kìí ṣe ènìyàn, Òun kò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ rí (Numeri 23:19; 1 Samuẹli 15:29; Hòsíà 11:9). Òun jẹ́ Ẹ̀mí (Johannu 4:24) Ẹ̀mí kìí si ṣe èyi tí ó ní ẹran ara àti egungun (Luku 24:39).

Àwọn Mọ́mọ́nì gbàgbọ́ wípé àwọn oríṣiríṣí ìpele tàbí àwọn ìjọba ní ó wà lẹ́hìn ayé: ìjọba tí òkè, ìjọba tí ilẹ̀, ìjọba ti agbede méjì òkè àti ilẹ̀, àti ìta òkùnkùn. Ibi tí ẹ̀dá ènìyàn yóò parí sí ní fi ṣe pẹ̀lú ohun tí wọn gbàgbọ́ àti tí wọ́n ṣe nínú ayé. Ní ìdàkejì, Bíbélì sọ fún wa wípé, lẹ́hìn ikú, à ńlọ sí ọ̀run tàbí ọ̀run-àpáàdì, tí ó ni íse pẹlú bóyá a ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olúwa àti Olùgbàlà wa tàbí a kò gbàá gbọ́. Láti má sí ní ínú àgọ́ ara wa, gẹ́gẹ́ bíi onígbàgbọ́, túmọ̀ sì wípé a wà pẹ̀lú Olúwa (2 Kọrinti 5:6-8). Aláìgbàgbọ́ ni a rán sí ọ̀run-àpáàdì tàbí ibi òkú (Luku 16:22-23). Nígbà tí Jésù bá padà dé lẹ́ẹ̀kejì, a ó gba àgọ́ ara ọ̀tun (1 Kọrinti 15: 50-54). Ọ̀run titun àti ayé titun yóò wà fún àwọn onígbàgbọ́ (Ifihan 21:1), àti aláìgbàgbọ́ ní a ó sọ sínú adágún iná ayérayé (Ifihan 20:11-15). Kò sí ànfàní kejì fún ìràpadà lẹ́hìn ikú (Heberu 9:27).

Àwọn aládarí Mọ́mọ́nì ti kọ́ni wípé wíwá ní ènìyàn ti Jésù jẹ́ àbájáde ìbáṣepọ̀ tí a lè fójú rí tí ó wà láàrin Ọlọ́run ti Baba àti Màríà. Àwọn Mọ́mọ́nì gbàgbọ́ wípé ọ̀lọ́run kékeré ní Jésù, ṣùgbọ́n wípé ẹnikẹ́ni lè di ọlọ́run kékeré pẹ̀lú. Mọ́mọ́nì ńkọ́ni wípé a lè jèrè ìgbàlà nípa àkójọpọ̀ àwọn ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́ rere. Ní ìdàkejì sí èyí, nípa tí ìtàn, àwọn Kristiẹni ti kọ́ni wípé kò sí ẹnikan tí ó lè dé ipò tí Ọlọ́run—Òun nìkan ni ó jẹ́ mímọ́ (1 Samuẹli 2:2). A kàn lè di mímọ́ níwájú Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ (1 Kọrinti 1:2). Jésù ní Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run (Johannu 3:16), Òun nìkan ní ó ìgbé-ayé àìlẹ́ṣẹ̀, ìgbé-ayé àìlábùkù, tí ó si ní nísisìyí ipò tí ó l'ọ́lá jùlọ ní ọ̀run (Heberu 7:26). Jésù àti Ọlọ́run wà ní ọ̀kan ní pàtó, Jésù tí ó jẹ́ Ẹni tí ó ti ńwà kí a tó bíi nípa ti ara (Johannu 1:1- 8, 8:56). Jésù fi Ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ. Ọlọ́run jí I dìde kúrò nínú òkú, àti ní ọjọ́ kan ènìyàn gbogbo yóò jẹ́wọ́ wípe Jésù Kristi ni Olúwa (Filippi 2:6-11). Jésù wí fún wa wípé kò ṣeé ṣe láti dé ọ̀run nípa àwọn iṣẹ́ wa àti wípé nípa ìgbàgbọ́ nìkàn nínú Rẹ̀ ni yóò ṣeé ṣe (Matteu 19:26). Gbogbo wa ni ìjìyà ayérayé tọ́ sì fún àwọn ẹ̀sẹ̀ wa, ṣùgbọ̀n ìfẹ́ Ọlọ̀run tí kò lópin àti ore-ọ̀fẹ́ ti gbà wá láàyè ọ̀nà àbáyọ. "Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa." (Romu 6:23).

Ní kedere, ọ̀nà kan ṣoṣo ló wà láti rí ìgbàlà gbà èyí sì ní láti mọ Ọlọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù (Johannu 17:3). Kìí ṣe nípa iṣẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìgbàgbọ́ (Romu 1:17; 3:28). Ẹnikẹ́ni tí ó wù kí a jẹ́ láìkàsí ẹni ti a jẹ́ tàbí ohun tí a ti ṣe àwa lè gba ẹ̀bùn yìí (Romu 3:22). "Ìgbàlà ni a kò lè rí nínú elòmíràn, nítorí kò sí orúkọ kan lábẹ ọrun tí a fi fún àwọn èniyàn nípa èyí tí a lè fi ní ìgbalà." (Ìṣe àwọn Apọsteli 4:12).

Bí o tìlẹ jẹ́ wípé àwọn Mọ́mọ́nì a máa ni ọ̀yàyà, nífẹ̀ẹ́, tí wọn sì ní inú rere, a tàn wọn jẹ nípa ẹ̀sìn èké tí ó ṣe àyídáyida àbùdá Ọlọ́run, ẹni ti Jésù Kristi jẹ́, àti àwọn ọ̀nà ìgbàlà.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ Ṣíṣe Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan? Kínni àwọn Mọ́mọ́nì gbàgbọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries