settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìgbàsókè ìjọ?

Idahun


Kò sí ọ̀rọ̀ ìgbàsókè nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ náà wá láti inú ọ̀rọ̀ Látínì tí ó túmọ̀ sí "gbígbé lọ, mímú lọ, tàbí jíjá gbà lọ". "Èrò gbígbé lọ" tàbí ìgbàsókè ìjọ jẹ́ nǹkan tí Ìwé Mímọ́ kọ́ yékéyéké.

Ìgbàsókè ìjọ jẹ́ iṣẹ̀lẹ̀ nínú èyí tí Ọlọ́run yóò "já àwọn onígbàgbọ́ gbà lọ" kúrò ní ayé kí ó lè mú kí ìdájọ́ òdodo Rẹ̀ tú jáde sí órilẹ̀ ayé ní àkókò ìpọ́njú. A ṣe àpèjúwe ìgbàsókè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú Ìwé Tẹssalonika kínní 4:13-18 àti Ìwé Kọrinti kínní 15:50-54. Ọlọ́run yóò jí àwọn onígbàgbọ́ tí ó ti kú dìde, yóò fún wọn ní ara tí ó lógo, yóò sì gbà wọ́n kúrò láyé pẹ̀lú gbogbo onígbàgbọ́ tí ó wà láàyè, tí àwọn náà yóò sì gbé àgọ́ ara tí ó lógo wọ̀ nígbà náà. "Nítorí Oluwa tikararẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run tí on ti ariwo, pẹlu ohun olori àwọn angẹli, ati pẹlu ìpè Ọlọ́run; àwọn òkú ninu Kristi ni yóò si kọ́ jinde. Nigbana li a o gbà awa ti o wà laye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, láti pàdé Oluwa li ojú ọrun. bẹẹli awa ó sì máa wà titi lai lọ́dọ̀ Oluwa. (1 Tẹssalonika 4:16-17).

Ìgbàsókè náà yóò ní ṣe pẹ̀lú ìpaláradà kíákíá kí á le yẹ fún ayérayé. "Olufẹ ọmọ Ọlọ́run li awa ṣe nisisiyi, a kò si ti fihan bi awa o ti ri: awa mọ̀ pé nígbàtí a ba fihan, a o dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri" (1 Johannu 3:2). A gbọ́dọ̀ mọ ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ìgbàsókè àti ìpadàbọ̀ kejì. Ní ìgbàsókè, Olúwa yóò yọ "nínú àwọsánmà" láti pàdé wa "ní òfuurufú" (1 Tẹssalonika 4:17). Ní ìpadàbọ̀ kejì, Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá sáyé láti dúró sí orí Òkè Ólífì, àyọrísí rẹ̀ sì ni ilẹ̀ mímìtìtì tí ìṣubú àwọn ọ̀tá Ọlọ́run yóò sì tẹ̀lé (Sẹkariah 14:3-4)

Ẹ̀kọ́ ìgbàsókè kò sí nínú Májẹ́mú Láíláí, nítorí náà ni Pọ́ọ̀lù ṣe pèé ní "nǹkan ìjìnlẹ̀" tí a fihàn: "Kiyesii, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun yin; Gbogbo wa kì yòó sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palaradà. Lọgan, iṣẹju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yóò dún, a o si jí àwọn okù dide li aidibajẹ, a o si pa pawalara dà". (1 Kọrinti 15:51-52).

Ìgbàsókè náà jẹ́ iṣẹ̀lẹ̀ tí ó lógo tí gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa pòǹgbẹ fún. À ó bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. A ó máa wà ní iwájú Ọlọ́run títí lái. Ìjiyàn púpọ̀ wà lórí ìtumọ̀ àti iṣẹ̀lẹ̀ ìgbàsókè náà. Èyí kìí ṣe èróngbà Ọlọ́run. Dípò bẹ́ẹ̀, Ìgbàsókè gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ̀kọ́ ìtùnú tí ó ńfún ni ní ìrètí; Ọlọ́run fẹ́ kí á máa "ẹ máa fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí tu ara yín ninu" (1 Tẹssalonika 4:18).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìgbàsókè ìjọ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries