settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó?

Idahun


Bíbélì ṣe àkọ́sílẹ̀ ṣíṣẹ̀dá ìgbeyàwó ní Jẹnẹsisi 2:23-24: "Adamu si wípé, "Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ra ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a ó maa pè e, nítorí ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá. Nitorina li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yio sì fi ara mọ́ aya rẹ̀, wọn o si di ara kan." Ọlọ́run ṣẹ̀dá ọkùnrin àti lẹ́hìn náà obìnrin láti ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Nínú Bíbélì ìgbeyàwó jẹ́ "ìyanjú" ti Ọlọ́run fún òtítọ́ wípé "kò dára kí okùnrin náà kí o níkàn ma gbé" (Jẹnẹsisi 2:18).

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ṣe àpejúwe ìgbéyàwó àkọ́kọ́ náà, ó ṣe àmúlò ọ̀rọ̀ olùrànlọ́wọ́ láti ṣe ìdánimọ̀ Éfà (Gẹnẹsisi 2:20). Láti "rànlọ́wọ́" nínú ọ̀rọ̀ yìí tùmọ̀ sí wípé "láti yíká, láti dáàbòbò tàbí ṣè ìrànlọ́wọ́." Ọlọ́run ṣẹ̀dá a Éfà láti wa lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ádámù gẹ́gẹ́ bíi "ìdàjì míìrán," rẹ̀ láti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Bíbélì sọ wípé ìgbeyàwó yóò mú kì ọkùnrin kan àti obìnrin kó di "ara kan." Dídi ara kan yìí ńfarahàn jùlọ ní kíkún nínù ìsopọ̀ lára nípa ìbárẹ́ ti ìbálòpọ̀. Májẹ̀mú Titun ṣe àfikún ìkìlọ̀ tì o nííṣe pẹ̀lú dídi ara kan yìí: "Nítorí wọn kìí ṣe méjì mọ́ bíkòṣe ara kan. Nítorì náà ohun tí Ọlọ́run ba so ṣọ̀kan, ki èniyàn ki o maṣe yà wọn" (Matteu 19:6).

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn èpistélì ti Pọ́ọ̀lù tọ́kasí ìgbeyàwó àti bí àwọn onígbàgbọ́ ṣe gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìbaṣepọ̀ ti ìgbeyàwó. Ọ̀kan lára ẹsẹ̀ náà ni Efesu 5:22–33. Kíkọ́ ẹkọ́ ẹsẹ́ yìí ńpèse díẹ̀ nínú àwọn kọ́kọ́rọ́ òtítọ́ nípa ohun tí Bìbélì sọ wípé bí ìgbeyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́.

Bíbélì náà, nínú Efesu 5, sọ wípé ìgbeyàwó tí yóò ní àṣeyọrí èyítí ó bá bíbélì mu yóò ní nínú kí ọkọ àti ìyàwó tí ó ńmù àwọn ojúṣe kan ṣẹ: "Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí fun Oluwa. Nítorípé ọkọ ni iṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe orí ìjọ rẹ̀: oun sì ni Olùgbàlà ara" (Efesu 5:22 -23). "Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un" (Efesu 5:25). "Bẹ́ẹ̀li ó tọ́ kí àwọn ọkunrin ki o máa fẹ́ràn àwọn aya wọn, gẹ́gẹ́ bí ara àwọn tìkararẹ̀wọn. Ẹnití ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, ó fẹ́ràn on tìkararẹ̀. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀. Bíkòṣe ki o máa bọ́ ọ ki o si máa ṣikẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kristi si ti ńṣe sí ìjọ" (Efesu 5:28-29). "Nítorí èyí li ọkunrin yóò ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, on o si dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan." (Efesu 5:31).

Nígbàtí ọkọ àti ìyàwó onígbàgbọ́ kan bá fi àwọn ìlànà Ọlọ́run fún ìgbeyàwó nínú Bíbélì kalẹ̀, ìgbèyáwò tí o dúró gírí, tí ó ní ìléra nì àbájade rẹ̀. Ìgbéyàwó tí ó ba bìbélì mu ńfi Kristi ṣe ori ọkọ àti ìyàwó náà l'ápapọ̀. Èròǹgbà tí ìgbeyàwó ti bíbélì ni nínú ìṣọ̀kan láàrín ọkọ àti ìyàwó tí ó bá àwòrán ìṣọ̀kan ti Kristi pẹ̀lú ìjọ Rẹ̀ mu.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries