Ibeere
Kílódé tí Ọlọ́run fifi igi ìmọ̀ rere àti búburú sínú ọgbà Édẹ́nì?
Idahun
Ọlọ́run fi igi ìmọ̀ rere àti búburú sínú ọgbà Édẹ́nì láti fún Ádámù àti Éfà láàyè láti yàn láti gbọ́ràn tàbí ṣe àìgbọràn sí Òun. Ádámù àti Éfà ní òmìnira láti ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́, àyààfi láti jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú. Jẹnẹsisi 2:16-17, "OLÚWA Ọlọ́run sì fi àṣẹ fún ọkùnrin ná pé, nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ kí ó máa jẹ: Ṣùgbọ́n nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú nì, ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí pé ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀ kíkú ni ìwọ yóo kú." Bí Ọlọ́run kò bá fún Ádámù àti Éfà ní àǹfàní láti yàn, wọn kò bá dàbí ṣìgìdì, tí ńṣe ètò tí a fi sínú wọn láti ṣe. Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà láti jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní "òmìníra", tí wọ́n lè ṣe ìpinnu, tí wọ́n lè yàn láàrin rere àti búburú. Kí Ádámù àti Éfà ba lè jẹ́ òmìníra ní tòótọ́, wọ́n nílò láti lè ṣe ìpinnu.
Kò sí kókó ohun tí ó burú nípa igi tàbí èso igi náà. Kò dàbí ẹni wípé, èso náà, nípa òhun tìkalára rẹ̀, fún Ádámù àti Éfà ní ìmọ̀ síwájú si. Èyí ní wípé, èso náà lè ní lára àwọn fítámìn C kan àti àwọn èpo (fíbà) tí ó ṣe ara lóre, ṣùgbọ́n kò ṣe ni lóre nípa ti ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, ìwà àìgbọràn ṣe àkóbá ní ti ẹ̀mí. Ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ṣí ojú Ádámù àti Éfà sí ibi. Fún ìgbà àkọ́kọ́, wọ́n mọ ohun tí ó jẹ́ láti burú, láti ní ìtìjú, àti láti fẹ́ sá pamọ́ kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ àìgbọràn wọn sí Ọlọ́run mú ìdibàjẹ́ wọ inú ayé wọn àti sínú ayé. Jíjẹ èso náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ àìgbọràn lòdì sí Ọlọ́run, ni ó fún Ádámù àti Éfà ní ìmọ̀ búburú—ìmọ̀ wípé wọ́n wà ní ìhòhò (Jẹnẹsisi 3: 6-7).
Ọlọ́run kò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀. Ọlọ́run mọ̀ síwájú àkókò ohun tí àyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ yóò jẹ́. Ọlọ́run mọ̀ wípé Ádámù àti Éfà yóò dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n yóò sì mú ibi, ìjìyà àti ikú wọ ayé nípa rẹ̀. Kíló wá dé tí Ọlọ́run ṣe gba Sátánì láàyè láti dán Ádámù àti Éfà wò? Ọlọ́run gba Sátánì láàyè láti dán Ádámù àti Éfà wò, láti mú kí wọn ṣe ìpinnu dandan. Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ yàn nípaṣẹ̀ ara wọn láti ṣe àìgbọràn sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ èso tí á kò gbọ́dọ̀ jẹ. Àyọrísí rẹ̀—ibi, ẹ̀ṣẹ̀, ìjìyà, àìsàn, àti ikú—ti bo ayé láti ìgbà náà lọ. Ìpinnu Ádámù àti Éfà yọrísí kí gbogbo ènìyàn ní àbùdá ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ṣeé ṣe láti dẹ́ṣẹ̀. Ìpinnu Ádámù àti Éfà ló jẹ́ kí ikú Jésù Kristi lórí igi àti láti ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀ fún wá kó nílò ní ìgbẹ̀yìn. Nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi, a lè di òmìnira kúrò nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀, kí á sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tìkalára rẹ̀. Ṣé a lè tún ọ̀rọ̀ Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù nínú ìwé Rómù 7:24-25 sọ, "Èmi ẹni òṣì! Tani yóò gbà mí lọ́wọ́ ara ikú yí? Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kríístì Olúwa wa!"
English
Kílódé tí Ọlọ́run fifi igi ìmọ̀ rere àti búburú sínú ọgbà Édẹ́nì?