settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ìjà ogun ẹ̀mí?

Idahun


Àṣìṣe méjì ni ó wà nígbàtí a bá ńsọ nípa ìjà ogun ẹ̀mí—títẹnumọ́jù àti àitẹnumọ́tó. Àwọn kan ńdá gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo èdè àiyedè, àti gbogbo ìṣòro lórí àwọn ẹ̀mí èṣù tí a nílò láti lé jáde lẹ́bi. Àwọn míìrán fo ipo ti ẹ̀mí dá pátápátá àti òtítọ́ wípé Bíbélì sọ fún wa wípé ìjà wa jẹ́ èyí tí ó lòdì sí àwọn agbára ẹ̀mí. Kókó sí àṣeyọrí ìjà ogun ẹ̀mí ni láti wa ipo ti bíbélì tí ó ṣe déédé rí. Jésù nígbàmíì máa ńlé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nínú àwọn ènìyàn; ìgbà míìrán Òun a wo àwọn ènìyàn sàn láì mẹ́nuba ẹ̀mí èṣù. Apọsteli Pọ́ọ̀lù tọ́ àwọn Kristiẹni láti gbógun lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú wọn (Romu 6) tí ó sì kìlọ̀ fún wa láti kojú àwọn ètò èṣù (Efesu 6:10-18).

Efesu 6:10-12 sọ wípé, "Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Ọlọ́run, ati ninu agbara ipá rẹ̀; Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọ́run wọ̀, ki ẹyin ki o kọ oju ija si arekereke èṣù. Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ̀ ati ẹran-ara li awa nba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkùnkùn aiye yi, ati awọn ẹmi buburu ni oju ọrun." Ọ̀rọ̀ yìí kọ wa ní àwọn òtítọ́ kan tí ó ṣe kókó: àwa lè dúró déédé nípa ti agbára Olúwa nìkan, ìhámọ́ra ti Ọlọ́run ni o ńdáàbòbò wá, àti ìjà wa ní ìkẹhìn jẹ́ èyí tí ó lòdì sí àwọn alágbára ibi nínú ayé.

Efesu 6:13-18 jẹ́ àpèjúwe ìhámọ́ra ti ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún wa. Àwa ní láti dúró gírí pẹ̀lú àmùrè òtítọ́, ìgbáìyà ti òdodo, ìhìnrere alaafia, apata ìgbàgbọ́, àṣíborí ìgbàlà, idà Ẹ̀mí, àti nípa gbígbàdúrà nínú Ẹ̀mí. Kínni àwọn ìhámọ́ra kékèké ti ẹ̀mí wọ̀nyìí dúró fún ní ìjà ogun ẹ̀mí? Àwa gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́, gba òtítọ́ gbọ́, kí a sì sọ òtítọ́. Àwa gbọ́dọ̀ sinmi nínú òtítọ́ wípé a pè wá ní olódodo nítorí ìrúbọ ti Kristi fún wa. Àwa gbọ́dọ̀ polongo ìhìnrere bí ó ti wù kí ìdojúkọ kí ó wà. Àwa kò gbọ́dọ̀ y'ẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wa, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí ti Ọlọ́run bí ó ti wù kí a takò wá. Ààbò wa tí ó dájú jùlọ ni ìdánilójú tí a ní nínú ìgbàlà wa, ìdánilójú wípé kò sí ipá ẹ̀mí kan tí o lè múu kúrò. Ohun ìjà wa ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kìí ṣe àwọn èrò àtí ìmọ̀lára ti ara wa. Àwa sì ní láti gbàdúrà nínú agbára àti ìfẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

Jésù ni àpẹẹrẹ wa fún dídojúkọ ìdanwò tí ó ga jùlọ fún ìjà ogun ẹ̀mí wa. Kíyèsi bí Jésù ṣe ṣe sí àwọn ìkojú Èṣù ní tààrà nígbàtí a dán Òun wò nínú aginjù (Matteu 4:1-11). Ìdánwò kọ̀ọ̀kan ni ó lo ọ̀rọ̀ "a ti kọọ́" láti kojú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ohun ìjà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ láti kojú àwọn ìdánwò èṣù. "Ọ̀rọ̀ rẹ ni mo pamọ́ li aya mi, ki emi ki o maṣe ṣẹ̀ si ọ" (Orin Dafidi 119:11).

Ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ nípa ìjà ogun ẹ̀mí ṣe déédé. Orúkọ Jésù kìí ṣe ọfọ̀ a jẹ́ bíi idán tí ó ńjẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù sá níwájú wa. Àwọn ọmọ Skefa méje jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ nígbàtí àwọn ènìyàn bá lérò wípé àwọn ní àṣẹ tí a kò fifún wọn (Iṣe awọn Apọsteli 19:13-16). Máikẹ́li olórí àwọn ańgẹ́lì pàápàá kò bá Èṣù wí nínú agbára rẹ̀ ṣùgbọ́n ó wípé, "Olúwa ni yio bá ọ wí!" (Juda 1:9). Nígbàtí àwa bá bẹ̀rẹ̀ sí ní bá èṣù sọ̀rọ̀, àwa wà nínú ewu à ti ṣìnà bíi Efa (Jẹnẹsisi 3:1-7). A gbọ́dọ̀ tẹjúmọ́ Ọlọ́run, kìí ṣe ẹ̀mí èṣù; àwa yóò bá Òun sọ̀rọ̀, kìí ṣe àwọn.

Ní àkótán, kínni àwọn kókó àṣeyọrí nínú ìjà ogun ẹ̀mí? Àwa yóò gbẹ́kẹ̀lé agbára ti Ọlọ́run, kìí ṣe ti wa. Àwa yóò gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀. Àwa yóò gba agbára Ìwé Mímọ́—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni idà ti Ẹ̀mí. Àwa yóò gbàdúrà láì ṣe àárẹ̀ àti nínú ìwà mímọ́, tí a ńsìpẹ̀ wa sí Ọlọ́run. Àwa yóò dúró ṣinṣin (Efesu 6:13-14; àwa yóò jọ̀wọ́ ayé wa fún Ọlọ́run; àwa yóò kọjú ìjà sí iṣẹ́ ti èṣù (Jakọbu 4:7), ní mímọ̀ wípé Olúwa àwọn ọmọ ogun ni aláàbò wa. "Oun nikan li apata mi ati igbala mi; oun li aabo mi, emi ki yoo ṣipo pada jọjọ" (Orin Dafidi 62:2).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ìjà ogun ẹ̀mí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries