Ibeere
Kínni ète ìjọ?
Idahun
A lè pe Iṣe àwọn Apọsteli 2:42 ní gbólóhùn ète fún ìjọ: "Wọ́n dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn apọsteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà." Ní Ìbámu sí ẹsẹ yìí, àwọn ète/iṣẹ ijọ gbọ́dọ̀ jẹ́ 1) kíkọ́ ẹ̀kọ Bíbélì, 2) ìpèse ibi ìjọ́sìn fún àwọn onígbàgbọ́, 3) jíjẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àti 4) gbígbà àdúrà.
Ìjọ ní láti kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì kí á le gbilẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wa. Efesu 4:14 sọ fún wa wípé, "Kí àwa kí ó máṣe jẹ́ èwe mọ́, tí à ńfi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ ńtì síwá tì sẹ́hìn, tí a sì fi ńgbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fún ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti múni sìnà." Ìjọ yẹ kó jẹ ibi ìdàpọ̀, níbití àwọn onígbàgbọ́ ti lè farajìn fún ara wọn kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn (Romu 12:10), kilọ fún ara wọn (Romu 15:14), ṣe ore àti yọ́nú sí ara wọn (Efesu 4:32), gba ara wọn níyànjú (1 Tẹssalonika 5:11), àti ní pàtàkì jùlọ, nífẹ̀ẹ́ ara wọn (1 Johannu 3:11).
Ìjọ yẹ kó jẹ ibití àwọn onígbàgbọ́ ti lè jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ṣe ìrántí ikú Kristi àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ Rẹ̀ nítorí wa (1 Kọrinti 11:23-26). Ìṣe "bíbu àkàrà" (Iṣe àwọn Apọsteli 2:42) náà ní èrò jíjẹun papọ̀. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ míìrán tí ìjọ fí ńgbé ìdàpọ̀ lárugẹ. Ète tí ó kẹ́yìn ní ìbámu pẹ̀lú Iṣe àwọn Apọsteli 2:42 ní àdúrà. Ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ ibití ó gbé àdúrà lárugẹ, kẹ́kọ̀ọ́ nípa àdúrà, àti fífi àdúrà sójúṣe. Filipi 4:6-7 gbà wá níyànjú, "Ẹ máṣe àníyàn ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ, yóò sọ ọkàn àtì èrò yín nínú Kristi Jésù."
Iṣẹ́ míìrán tí a fún ìjọ ni láti polongo ìhìnrere ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Kristi (Matteu 28:18-20; Iṣe àwọn Apọsteli 1:8). A pe ìjọ láti jẹ́ olóòtọ́ nínú pípín ìhìnrere nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Ìjọ yẹ kó jẹ́ "ilé-ìmọ́lẹ̀" ní àwùjọ, tí ńtọ́ka àwọn ènìyàn sí Olúwa àti olùgbàlà wa, Jésù Kristi. Ìjọ yẹ kí ó gbé ìhìnrere lárugẹ kí ó sì pèsè àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ láti polongo ìhìnrere náà (1 Peteru 3:15).
Àwọn ète ìjọ tí ó kẹ́yìn la fún wa nínú Jakọbu 1:27: "Ìsín mímọ́ àti aíléèérí níwájú Ọlọ́run àti Bàbá ni èyí, láti máa bójútó àwọn aláìníbàbá àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò ní ayé." Ìjọ yẹ kó wà lẹ́nu iṣẹ́ ríran àwọn aláìní lọ́wọ́. Èyí kìí ṣe pípín ìhìnrere nìkan, ṣùgbọ́n àwọn pípèsè ohun ìní (oúnjẹ, aṣọ, ilé) ní bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ. Ìjọ yẹ kí ó pèsè àwọn ohun èlò tí wón nílò láti ṣẹ́gun ẹ̀sẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ nínú Kristi àti láti pa ara wọn mọ́ láìlábàwọ́n kúrò ní ayé. A ó ṣe èyí nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì àti ìdàpọ̀ onígbàgbọ́.
Nítorínáà, kínni ète ìjọ? Pọ́ọ̀lù pèsè àkàwé tí ó péye fún àwọn onígbàgbọ́ ní Kọrinti. Ìjọ jẹ́ ọwọ́, ẹnu, àti ẹsẹ̀ Ọlọ́run nínú ayé yìí — ara Krístì (1 Kọrinti 12:12-27). Ó yẹ kí á máa ṣe àwọn ohun tí Jésù Kristi yóò ṣe bi Òun ba wa nínú ara l'ayé. Ó yẹ kí ìjọ jẹ́ "Kristiẹni," "bíi-Kristi," àti olùtẹ̀lé Kristi.
English
Kínni ète ìjọ?