Ibeere
Ṣé ìkún omi Nóà jẹ́ àgbáyé tàbí àgbègbè?
Idahun
Àwọn àyọkà inú Bíbélì nípa ìkún omi fihàn gedegbe wípé ti àgbáyé ló jẹ́. Jẹnẹsisi 7:11 sọ wípé "ni gbogbo ìsun ibú ńlá ya, àti fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀". Jẹnẹsisi 1:6-7 àti 2:6 sọ fún wa wípé àkókò tí ó wà kí ó tó di ìgbà ìkún omi yàtọ̀ gédégbé sí èyítí à ńní ìrírí nípa rẹ̀ lónìí. Lórí èyí àti àwọn àpèjúwe míìrán nínú Bíbélì, ó mú ọgbọ́n wá láti lérò wípé ní àkókò kan irú àbò omi kan bo ayé mọ́lẹ̀. Irú àbò yìí lè jẹ́ àbò òkùùku, tàbí kí ó ní àwọn irin, tí ó dàbí ti irin yìnyín sátọ̀ọ̀nù. Èyi, pẹ̀lú àkójọpọ̀ omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, tí a tú sí orílẹ̀ ayé (Jẹnẹsisi 2:6) ni ó gbọ́dọ̀ yọrí sí ìkún omi àgbáyé.
Àwọn ẹsẹ tí ó ṣe gedegbe jù tó fíhàn bí ìkún omi náà ti pọ̀ tó wà nínú Jẹnẹsisi 7:19-23. Nípa ti àwọn omi náà, "Omi sì gbilẹ̀ gidigidi lórí ilẹ̀; àti gbogbo òkè gíga, tí ó wà ní gbogbo abẹ́ ọ̀run, li a bò mọ́lẹ̀. Omi ru sókè ní ìgbọ̀nwọ́ tí ó lé lógún, a sì bo gbogbo òkè ńlá mọ́lẹ̀. Gbogbo ẹ̀dá tó ń rìn lórí ilẹ̀ sì parun — ti ẹyẹ, ti ẹran—ọ̀sìn, ti ẹranko, ti ohun gbogbo tí ńrákò lórí ilẹ̀ àti gbogbo ènìyàn: Gbogbo ohun tí ẹ̀mí ìyè wà ní ihò imú rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó wà ní ìyàngbẹ ilẹ̀ sì kú. Ohun alààyè gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ni a sì parun, àti ènìyàn, àti ẹran- ọ̀sìn, àti ohun tí ńrákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọ́n sì run kúro ní orí ilẹ̀. Nóà nìkan ni ó kù, àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀."
Nínú àyọkà tí ó wà lókè yìí, kìí ṣe ọ̀rọ̀ yìí tíí ṣe, "gbogbo" nìkan ni à ńlò lemọ́lemọ́, ṣùgbọ́n a tún rí ọ̀rọ̀ bíi "àti gbogbo òkè gíga, tí ó wà ní gbogbo abẹ́ ọ̀run, li a bò mọ́lẹ̀." "omi náà ru sókè ní ìgbọ̀nwọ́ tí ó lé lógún" àti " gbogbo ẹ̀dá tó ń rìn lórí ilẹ̀ sì ṣègbé." Àwọn àpèjúwe yí júwe kedere ìkún omi àgbáyé tó bo gbogbo ayé mọ́lẹ̀. Àti pẹ̀lú, tí ìkún omi náà bá jẹ́ ti àgbègbè ni, kílódé tí Ọlọ́run fi sọ wípé kí Nóà kan ọkọ̀ dípò kí ó sọ pé kí ó kúrò, kí ó sì mú kí àwọn ẹranko ṣí kúro? Àti wípé, kíló dé tí Ó fi sọ fún Nóà wípé kó kan ọkọ̀ tí ó tóbi tó láti gba gbogbo onírúurú ẹranko ilẹ̀ tó ńrìn lórí ilẹ̀? Bí ìkún omi náà kò bá jẹ́ ti àgbáyé, a kò ní nílò ọkọ̀.
Pétérù ṣe àpèjúwe bí ìkún omi náà ṣe jẹ́ ti àgbáyé nínú ìwé Pétérù kejì tí ó sọ wípé,"Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà ní ìgbà náà, tí ó sì ṣègbé: ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé tí ń bẹ nísinsìnyí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà tí a ti tòjọ bí ìṣura fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run." Nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyìí, Pétérù fi ìdájọ́ "ayé" tí ó ńbọ̀ wé ìkún omi ìgbà ayé Nóà, ó sì sọ wípé ayé tí ó wà nígbà náà ti ṣègbé pẹ̀lú omi. Síwàjú si, ọ̀pọ̀ olùkọ̀wé nípa Bíbélì gba ìtàn nípa ìkún omi àgbáyè gbọ́ (Isaiah 54:9; 1 Peteru 3:20; 2 Peteru 2:5; Heberu 11:7). Ní ìparí, Jésù Kristi Olúwa gba ìtàn nípa ìkún omi àgbáyè gbọ́, tí ó sì fi wé iru ìparun tí ó ńbọ̀ wá sí ayé ní ìpadàbọ̀ Rẹ̀ (Matteu 24:37-39; Luku 17:26-27).
Àwọn àrídájú tí ó pọ̀ wà tí ó tayọ ti inú Bíbélì tí ó tọ́ka sí àjálù àgbáyé bíí ìkún omi àgbáyé. Wọ́n rí ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó ṣẹ́kù lẹ́hìn ikú nínú ibojì ní gbogbo kọ́ńtínẹ́ǹtì àti ọ̀pọ̀ èédú tí ó kalẹ̀, tí ó lè bo ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ọ̀gbìn kíákíá. Nǹkan tí ó ṣẹ́kù lẹ́hìn ikú tí ó wà ní òkun ni a rí ní orí àwọn òkè ńlá ní gbogbo àgbáyé. Àṣà ní ibi gbogbo lágbáyé ni wọ́n ní ìtàn lórí ìkún omi. Gbogbo àwọn òtítọ́ yìí àtí àwọn míìrán jẹ́ àrídájú ìkún omi àgbáyé.
English
Ṣé ìkún omi Nóà jẹ́ àgbáyé tàbí àgbègbè?