Ibeere
Kínni ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́?
Idahun
Ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́ ni a lè túmọ̀ bíi iṣẹ́ nipasẹ̀ èyítí Ẹ̀mí Ọlọ́run ńmú ìdàpọ̀ wà láàrín onígbàgbọ́ àti Kristi pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míìrán nínú ara Kristi ní àkókò ìgbàlà. Ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ṣe ìlérí nípasẹ̀ Jòhánnù Onítẹ̀bọmi (Marku 1:8) àti nípasẹ̀ Jésù kí Òun tó lọ sí ọ̀run: "Nítorí nítòótọ́ ni Johannu fi omi baptisi; ṣùgbọ́n a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ baptisi yin, kì iṣe ọjọ́ púpọ̀ láti òní lọ" (Iṣe awọn Apọsteli 1:5). Ìlérí yìí ni a múṣẹ ní Ọjọ́ Pẹntikọsti (Iṣe awọn Apọsteli 2:1-4); fún ìgbà àkọ́kọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ ńgbé nínú àwọn ènìyàn láíláí, ìjọ si ti bẹ̀rẹ̀.
Kọrinti kínni 12:12-13 ni ẹsẹ̀ Bíbélì tí ó wà ní àarin gbùngbùn nípasẹ̀ ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́: "Nítorípé nínú Ẹ̀mí kan li a ti baptisi gbogbo wa sínú ara kan, iba ṣe Ju, tàbí Hellene, iba ṣe ẹrú, tàbí omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹ̀mí kan" (1 Kọrinti 12:13). Kíyèsi wípé "gbogbo" wa ni a ti baptisi nípasẹ̀ Ẹ̀mí náà — gbogbo onígbàgbọ́ ti gba baptisi, tí ó ṣé rọ́pò ìgbàlà, tí kìí si ṣe ìrírí àkànṣe fún àwọn díẹ̀. Nígbàtí Romu 6:1–4 kò dárúkọ Ẹ̀mí Ọlọ́run ní pàtó, ó ṣe àpèjúwe ipò onígbàgbọ́ níwájú Ọlọ́run ní èdè tí ó ba ẹsẹ̀ 1 Kọrinti mu: "Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí? Kí àwa kí ó ha jókò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí ore-ọ̀fẹ́ kí ó lè ma pọ̀ síi? Kí á ma ri! Àwa ẹnití o ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa o ha ṣe wà láàyè nínú rẹ̀ mọ́? Tàbí ẹ kò mọ̀ pé, gbogbo wa ti a ti baptisi sínu Kristi Jésù, a ti baptisi wa sínú ikú rẹ̀? Ǹjẹ́ a fi baptismu sínú ikú sin wá pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀: pé gẹ́gẹ́ bí a ti jí Kristi dìde kúrò nínú òkú nípa ògo Baba bẹ́ẹ̀ni kí àwa kí o máa rìn li ọ̀tun ìwà."
Àwọn òtítọ́ wọ̀nyìí ni a nílò láti mú kí òye wa nípa ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́ kí ó dúró déédé: Àkọ́kọ́, 1 Kọrinti 12:13 sọ gbangba wípé gbogbo ènìyàn ni a ti rì bọmi, gẹ́gẹ́ bí a ti fún gbogbo ènìyàn ní Ẹ̀mí láti mu (kí Ẹ̀mí kí ó máa gbé inú ẹni). Ìkejì, kò sí ibi kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí a ti sọ fún àwọn onígbàgbọ́ kí a baptisi wọn pẹ̀lú, nínú tàbí nípasẹ̀ Ẹ̀mí, tàbí ní òye kankan láti wá ìrìbọmi ti Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí túmọ̀ sí wípé gbogbo onígbàgbọ́ ni o ti ní ìrírí yìí. Ìkẹta, ó jọ wípé Efesu 4:5 ńtọ́kasí ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, ìrìbọmi ti Ẹ̀mí jẹ́ ohun tí ó dájú fún gbogbo onígbàgbọ́, gẹ́gẹ́bíi "ìgbàgbọ́ kan" àti "Baba kan" ṣe jẹ́.
Ní àkótán, ìrìbọmi ti Ẹ̀mí Mímọ́ ńṣe ohun méjì, 1) ó ńso wa pọ̀ pẹ̀lú ara Kristi, àti 2) ó ńmu kíkàn wá mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú Kristi ṣẹ. Wíwà nínú ara Rẹ̀ túmọ̀ sí wípé a jí wa dìde pẹ̀lú Rẹ̀ sínú ayé ọ̀tun (Romu 6:4). A wá gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí wa si ojú ìṣe láti mú kí ara yẹn ṣiṣẹ́ déédé bí a tí kọọ́ ní Kọrinti kínni 12:13. Níni ìrírí ìrìbọmi kannáà ńṣiṣẹ́ fún pípa ìdàpọ̀ ìjọ mọ́ gẹ́gẹ́bí Efesu 4:5 ti sọ. Níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Kristi nínú ikú Rẹ̀, àti àjíǹde nípasẹ̀ ìrìbọmi Ẹ̀mí ńfi ẹsẹ̀ ìpilẹ̀sẹ̀ fún ìyàsọ́tọ́ wa kúrò nínú agbára ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ńgbé inú ẹni àti rírìn nínú ìgbé ayé ọ̀tun múlẹ̀ (Romu 6:1-10; Kolosse 2:12).
English
Kínni ìrìbọmi Ẹ̀mí Mímọ́?