Ibeere
Kínni Àbá Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání?
Idahun
Àbá Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání sọ wípé a nílò òkùnfà tí ó mọ́pọlọ dání láti lè ṣe àlàyé àkójọpọ̀ àgbékalẹ̀ ètò ti ẹ̀kọ́ nípa nǹkan alààyè (biology) tí ó kún fún ìmọ̀ àtí wípé a lè mọ òkùnfà yìí nipa àpẹ̀ẹrẹ. Àwọn amúyẹ ẹ̀kọ́ nípa nǹkan alààyè kan tako àlàyé nǹkan tí ó kan ṣẹlẹ̀ tí kò létò ti Darwin, nítorí wípé ó jọ wípé wọ́n ti ṣeé àgbékalẹ̀ rẹ̀. Nítorí wípé àgbékalẹ̀ nílo wípé kí á lo alágbékalẹ̀ tí ó jáfáfá, yíyọjú àgbékalẹ̀ túmọ̀ sí àrídájú fún alágbékalẹ̀. Àríyànjiyàn mẹ́ta tí ó ṣe pàtàkì ló wà lórí Àbá Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání: 1) àkójọpọ̀ tí kò ṣeé dínkù, 2) àkójọpọ̀ tí ó níra ní pàtó àti 3) ìlànà tí ó nííṣe pẹ̀lú ènìyàn.
A lè túmọ̀ nínira tí kò ṣe é dínkù sí "...ètò kan ṣoṣo tí ó ní onírúurú ẹ̀yà tí ó báramu, tí wọ́n ṣiṣẹ́ papọ̀ tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ wọn, èyí tí ó jẹ́ wípé tí a bá yọ ọ̀kan nínú ẹ̀yà náà kúrò yóò mú kí ètò náà kí ó má ṣiṣẹ́ rárá mọ́." Kí á sọọ́ báyìí, ayé ní àwọn ẹ̀yà tí ó wọnú ara wọn, tí wọ́n sì dúró lé ara wọn láti lè ṣiṣẹ́. Ìyípadà láì ní ètò lè fa ìdàgbàsókè ẹ̀yà titun míìrán, ṣùgbọ́n a kò lè gbára le fún ìdàgbàsókè àwọn ọ̀pọ̀ ẹ̀yà tí ó nílò fún àti ṣiṣẹ́pọ̀ ètò náà. Fún àpẹẹrẹ, a ríi kedere wípé ojú ènìyàn jẹ́ ètò tí ó wúlò púpọ̀. Láì sí ẹyin ojú, tánrán ojú, àti kọ̀tẹ́sìì ojú, ìyípadà láì ní ètò sí ojú tí kò pé yóò ṣe lòdì sí àti ṣiṣẹ́ sí yíyè irú ẹ̀dá báyìí, tí a ó sì yọ kúrò nípa ìlànà yìyàn nípa ìṣẹ̀dá. Ojú kìí ṣe ètò tí ó wúlò àyààfi bí gbogbo ẹ̀yà rẹ̀ bá wà tí wọ́n sì ńsiṣẹ́ déédé ní àkókò kan náà.
Àkójọpọ̀ tí ó nira ní pàtó ni èrò wípé nígbàtí àgbékalẹ̀ àkójọpọ̀ tí ó nira pàtó wà nínú ẹ̀dá, nítorí àwọn ìtọ́ni kan ni yóò ṣiṣẹ́ fún orísun wọn. Àríyànjiyàn lórí àkójọpọ̀ tí ó ṣe pàtó sọ wípé kò ṣeé ṣe fún ìlànà àkójọpọ̀ láti dàgbà nípa ọ̀nà tí a kò fètò sí. Fún àpẹẹrẹ, iyàrá tí ó kún fún ọgọ́rún (100) ọ̀bọ àtí ọgọ́rún (100) ẹ̀rọ ayárabíàṣá lé gbé ọ̀rọ̀ díẹ̀ jáde, tàbi kó tilẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó pọ̀, ṣùgbọ̀n kò lè pèsè eré Ṣekíspiẹ̀. Àti wípé báwo ni ayé ẹ̀kọ́ nípa nǹkan alààyè ṣe fẹjú ju eré Ṣekíspiẹ̀ lọ?
Ìlànà áńtírópíkì sọ wípé a ṣe "atúnṣe" ayé àti àgbáyé kí ó ba lè fi àyè gba ẹ̀mí láyè nílé ayé. Bí ìṣirò àwọn nǹkan tí ó wà lójú ọ̀run bá yípadà díẹ̀, ọ̀pọ̀ abẹ̀mí ni kò ní sí mọ́ l'órílẹ̀ ayé. Bí ayé bá fi máílì díẹ̀ súnmọ́ tàbí jìnnà sí òòrùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ abẹ̀mí ni kò ní sí mọ́ l'órílẹ̀ ayé. Wíwà àtí ìdàgbà ẹ̀mí l'órílẹ̀ ayé nílò kí àwọn nǹkan kan wà ní ipò pípé, wípé kò ṣeé ṣe fún àwọn nǹkan yìí kó wà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò létò, tí wọn kò fètò sí.
Nígbàtí ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání kò jọ wípé ó dá orísun ọgbọ́n mọ̀ (bóyá Ọlọ̀run ni tàbí àwọn UFO tàbí nǹkan míìrán), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹlẹ́kọ́ nípa Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání jẹ́ ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run wà. Wọ́n rí yíyọjú iṣẹ́ àkànṣe tí ó gbayé kan gẹ́gẹ́ bíi àrídájú wípé Ọlọ̀run wà. Ṣùgbọ́n, àwọn kan tí kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà tí kò lè tako àrídájú tí ó dájú nípa iṣẹ́ àkànṣe yìí, ṣùgbọ̀n tí wọn kò ṣetán láti jẹ́wọ́ Ọlọ̀run Ẹlẹ̀dá. Wọ́n gbìyànjú láti túmọ̀ àkójọ ọ̀rọ̀ fún àlàyé gẹ́gẹ́ bíi àrídájú wípé àwọn irú àwọn ìran olóyè àkàndá ẹ̀dá tí ó ńrìn nílẹ̀ (àjòjì) ló fúnrúgbìn ayé. Lótítọ́, wọn kò sọ nǹkan kan nípa orísun àwọn àjòjì yìí pẹ̀lú, nítorí náà wọ́n padà sí àríyànjiyàn àkọ́kọ́ láìní ìdáhùn tí ó ṣe gbẹ́kẹ̀lé.
Àbá Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání kò ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá. Ìyàtọ̀ kan tí ó ṣe pàtàkì wà láàrin ipó méjéèjì. Àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ìṣẹ̀dá ìlànà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu wípé àkọsílẹ̀ inú Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá ṣe gbẹ́kẹ̀lé, wípé ó sì tọ̀nà, wípé a dá ẹ̀mí sínú ayé láti ọwọ́ ikọ̀ kan tí ó jáfáfá—Ọlọ̀run. Wọ́n wá ẹ̀rí/àrídájú láti ìran ti ẹlẹ́ran-ara láti gbé ìpínnu yìí ró. Àwọn oní-àbá Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìran ti ẹlẹ́ran-ara, wọ́n sì fẹnu kò lórí ìpinnu wípé ikọ̀ kan tí ó jáfáfá (ẹni yòówù tí kò báà jẹ́) ló dá ẹ̀mí lórí ilé ayé.
English
Kínni Àbá Iṣẹ́ àkànṣe Tí ó mọ́pọlọ dání?