Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá àti ẹfolúṣàn?
Idahun
Kìí ṣe ète ìdáhùn yìí láti gbé àríyànjiyàn tí ó bá ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì mu kalẹ̀ lórí ìjiyàn láàrin ìṣẹ̀dá àti ẹfolúṣàn? Ète àkọsílẹ̀ yìí ni láti ṣe àlàyé, ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, ìdí tí àríyànjiyàn ṣe wà lórí ìṣẹ̀dá àti ẹfolúṣàn ní ipò rẹ̀ ní àkókò yìí. Romu 1:25 sọ wípé, "Àwọn ẹniti ó yí òtítọ́ Ọlọ́run padà sí èké, ńwọn sì bọ, nwọn sì sin ẹ̀dá ju Ẹlẹ̀dá lọ—ẹnití íṣe olùbùkún títí láí láí. Àmín."
Ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kókó nínú ipò àríyànjiyàn tí ó wà láàrin ìṣẹ̀dá àti ẹfolúṣàn ni wípé ọ̀pọ̀ nínú àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí àwọn tí kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà. Àwọn kan di irú ẹfolúṣàn kan mọ́wọ́ wípé kò sí Ọlọ́run rárá. Àwọn míìrán ní àfojúsùn wípé Ọlọ́run wà bíi òriṣà, wípé Òun wà ṣùgbọ́n kò nííṣe pẹ̀lú ayé àti wípé ohun gbogbo jẹ yọ fúnra wọn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá tí kò dáwọ́ dúró. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wo àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ fún àlàyé náà pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n sì pinnu wípé ẹfolúṣàn ni àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ fún àlàyé náà jọ. Ṣùgbọ́n, àlàyé tí ó jẹ yọ jù nínú ọ̀rọ̀ yìí ni wípé ẹfolúṣàn kò bá Bíbélì àti ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run mu.
Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ wípé àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì tí wọ́n di ìgbàgbọ́ ẹfolúṣàn mú tún gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Bíbélì láì rií wípé ọ̀kan tàbí òmíràn tako ara wọn. Ṣùgbọ́n, àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì ti ẹfolúṣàn gbà wípé ayé jẹyọ pátápátá láìní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹlẹ́dàá rárá. Àwọn àbá ìgbàlódé nípa ẹfolúṣàn, ní ti ìṣe, fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ sáyẹ̀nsì iṣẹ̀dá.
Àwọn atọ́ni ti ẹ̀mí kán wà lẹ̀yìn àwọn ipò yìí. Fún àwọn tí kò gbà wípè Ọlọ́run wà,wọ́n gbọ́dọ̀ ní àlàyé míìrán—yàtọ̀ sí Ẹlẹ̀dá—fún bí àgbáyé àti ẹ̀mí ṣe wà sípò. Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ nínú ẹfolúṣàn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Charles Darwin, òun ni ó kọ́kọ́ dá èrò wípé ó lè ṣeé ṣe nípa orísun ẹ̀dá fún ìlànà ẹfolúṣàn: yíyàn abínibí. Darwin rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristiẹni nígbà kan rí, ṣùgbọ́n, nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ayé rẹ̀, ó padà sẹ́ ìgbàgbọ́ Kristiẹni àti ìwàláyè Ọlọ́run.
Ìlépa Darwin kìí ṣe láti tẹ́mbẹ́lú ìwàláyè Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò rí àfojúsùn rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeni láàánú wípé, báyìí ni àwọn ti kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà ṣe gbé àbá rẹ̀ lárugẹ nìyí. Ìdí kan tí àwọn onígbàgbọ́ lónìí ṣe tako àbá ẹfolúṣàn ìgbàlódé ní wípé wọ́n máa ńfi ipá pọ́n-ọn lọ́pọ̀ ìgbà pẹ̀lú àfojúsùn ayé tí àwọn tí ó gbà wípé Ọlọ́run kò ṣí. Ó dàbí ẹni wípé àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì ti ẹfolúṣàn kò nígbà wípé ìlépa wọn ni láti fún ni ní àlàyé míìrán nípa orísun ayé, àti nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọ́n fún ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run kò sí ní ìpìlẹ̀. Àti síbẹ̀, ní ìlànà pẹ̀lú Bíbélì, èyí ni ìdí kan tí á ṣe ńwo ẹ̀kọ́ ẹfolúṣàn ní ọ̀nà tí a fi ńwòó lónìí.
Bíbélì sọ fún wá wípé" Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé," Ọlọ́run kò ṣí""(Orin Dafidi 14:1; 53:1). Bíbélì tún polongo wípé kò sí àwáwí fún ènìyàn láti má gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run Ẹlẹ̀dá. "Nítorí ohun Rẹ̀ tó farasin láti ìgbà dídá àyé a rí wọn gbangba, à ńfi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n, àní agbára àti ìwà- Ọlọ́run rẹ̀ ayérayé, kí wọn le wà ní àìríwí"(Romu 1:20). Gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì, aṣiwèrè ni ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ ìwàláyè Ọlọ́run. Ìṣiwèrè kò túmọ̀ sí àìní òye. Ó pọn dandan kí àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì ti ẹfolúṣàn mọ̀'wé dáradára. Ìṣiwèrè túmọ̀ sí àìlèlo ìmọ̀ lọ́nà tí ó dára. Òwe 1:7 sọ fún wa wípé,"ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìpilẹ̀sẹ̀ ọgbọ́n, ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè gan ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́."
Àwọn tí kò gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà tí wọ́n gba ẹfolúṣàn wọlé máa ńgan ìṣẹ̀dá àti/tàbí àgbékalẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n wípé wọn kò tọ̀nà pẹ̀lú sáyẹ̀nsì àti wípé wọ́n kò yẹ fún àyẹ̀wò sáyẹ̀nsì. Kí á tó lè gba nǹkan bí "sáyẹ̀nsì "wọ́n jiyàn wípé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ti ìṣẹ̀dá". Ìṣẹ̀dá, nípa ìtumọ̀, ju àwọn òfin nípa ayé tí a rí lọ. Níwọ̀n ìgbàtí a kò lè dán Ọlọ́run wò, nítorí náà, àríyànjiyàn náà tẹ̀síwájú wípé, a kò lè pe ìṣẹ̀dá àti/tàbí àgbékalẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ní sáyẹ̀nsì.
Ní kí a sọ òdodo ọ̀rọ̀, a kò lè ri tàbí ṣe àyẹ̀wò ẹfolúṣàn ju tàbí kéré bíi àgbékalẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, ṣùgbọ́n èyí kò jọ ọ̀ran pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́ nínú ẹfolúṣàn. Nítorí èyí, gbogbo àkójọ fún àlàyé ni a sẹ́, nípa èyi tí a yàn ṣíwájú àkókò, tí a rò ṣíwájú àkókò tí a gbà ṣíwájú àkókò ti àfojúsùn nípa ayé ti àwon olùtẹ̀lé ìṣẹ̀dá.
Àti orísun ti àgbáyé àti orísun ẹ̀mí ni ó ṣe yẹ̀wò tààrà tábí wò. Àti ìṣẹ̀dá àti ẹfolúṣàn ni ó nílò ìpele ìgbàgbọ́ kan kí á tó le gbà wọ́n. A kò lè padà sẹ́yìn láti wo orísun àgbáyé tàbí ìgbé-ayé inú àgbáyé. Àwọn tí ó kọ̀jálẹ̀ láti gba ìṣẹ̀dá, ṣe èyí lórí ìpílẹ̀ tí ó lè padà mú wọn kọ ẹfolúṣàn pẹ̀lú.
Bí ìṣẹ̀dá bá jẹ́ òtítọ́, nígbà náà Ẹlẹ̀dá kan ńláti wà tí a ní láti jíhìn fún. Bí a ṣe ńgbé ẹfolúṣàn kalẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà jẹ́ àtìlẹyìn fún ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run kò sí. Ẹfolúṣàn fún ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run kò sí ní ìpìlẹ̀ láti ṣe àlàyé bí ayé ṣe bẹ̀rẹ̀ láì sí Ọlọ́run Ẹlẹ̀dá. Bí ó ṣe rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ ìgbàlódé lórí ẹfolúṣàn jẹ́ pàṣípàrọ̀ fún "ìtàn ìṣẹ̀dá" nínú ẹ̀sìn ẹ̀kọ́ wípé Ọlọ́run kò sí.
Bíbélì sọ kedere: Ọlọ́run ni Ẹlẹ̀dá náà. Èyíkéyì ìtumọ̀ ti sáyẹ̀nsì bá gbìyànjú láti yọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀rọ̀ orísun kò bá Ìwé Mímọ́ mu.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá àti ẹfolúṣàn?