Ibeere
Kínni ìtumọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn?
Idahun
Nígba tí àwọn ènìyàn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn, wọn á ní ìrònù tí ẹgbẹ́ kan tí ó ńsin Sátánì, ńṣe ìrúbọ àwọn ẹranko, tàbì kópa nínú ibi, ohun tí ó jẹ́ èèmọ̀, àti àwọn ìrúbọ kèfèrí. Ṣùgbọ́n, ní ojú ayé, ó ṣọ̀wọ́n kí ẹgbẹ́ òkùnkùn kan máa ṣe irú àwọn nǹkàn bá wọ̀nyìí. Ní òtítọ́, ẹgbẹ́ òkùnkùn kan, ní ọ̀na tí ọ̀rọ̀ náà gbòrò jùlọ, jẹ́ ètò ẹlẹ̀sìn pẹ̀lú àwọn àṣà àti ojúṣe kan ní pàtó.
Nígbà kànkan, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wípé, a máa ǹṣe ìtúmọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn l'ọ́nà tóóró jùlọ, ọ̀rọ̀ náà síì túmọ̀ sí ẹgbẹ́ tí kìí ṣe ti àtíjọ́ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ńṣe àyípadà sí àwọn ẹ̀kọ́ ojúlówó tí ẹ̀sìn náà. Ní ti àkọsílẹ̀ Kristiẹni, itúmọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn jẹ́, ní pàtó, "ẹgbẹ́ ẹlẹ̀sìn kan tí ó ńsẹ́ ọ̀kan tàbí jùbẹ́ẹ̀ lọ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ òtítọ́ Bíbélì." Ẹgbẹ́ okùnkùn jẹ́ ẹgbẹ́ kan tí ńkọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ wípé, bí a bá gbàá gbọ́ a mú kí ẹni náà wà ní àìní ìgbàlà. Ẹgbẹ́ òkùnkùn gbà láti jẹ́ ara ẹ̀sìn kan, síbẹ̀ a máa kọ (awọn) òtítọ́ tí ó ṣe kókó ti ẹ̀sìn yẹn. Nítorí náà, ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ó jẹ́ ti Kristiẹni, yóò kọ ọ̀kan tàbí jùbẹ́ẹ̀ lọ̀ àwọn òtítọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbé-aye Kristiẹni, nígbàtí wọn ńjẹ́wọ̀ láti jẹ́ Kristiẹni síbẹ̀síbẹ̀.
Ẹ̀kọ́ méjì pàtàkì jùlọ tí ó wọ́pọ̀ ti àwọn ẹ̀kọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn Kristiẹni ni wípé Jésù kìí ṣe Olọ́run àti wípé ìgbàlà kìí ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan ṣoṣo. Ìkọ̀jálẹ̀ jíjẹ́ Ọlọ́run ti Kristi ńyọrí sí ojú ìwòye wípé ikú ti Jésù kú kò tó láti san ìtanràn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ìkọ̀jálẹ̀ tí ìgbàlà nípa ìgbàgbọ́ nìkan, ńyọrí sí inú ẹ̀kọ́ tí ó ń wípé à ńní ìgbàlà nípa àwọn iṣẹ́ ṣíṣe wa. Àwọn àpọ́sítélì bá àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn wí ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ti ìjọ: fún àpẹrẹ, Johannu sọ̀rọ̀ sí ẹ̀kọ́ ti Ìṣiyèméjì ní 1 Johannu 4:1-3. Ìdánwò ti Johannu fún ẹ̀kọ́ ìwàbí Ọlọ́run jẹ́ "Jésù Kristi ti wà nínú ara" (ẹsẹ̀ 2)—àtakò tààrà sí ẹ̀kọ́ òdì ti Ìṣiyèméjì (cf. 2 Johannu 1:7).
Àwọn àpẹẹrẹ méjì ẹgbẹ́ òkùnkùn tí a mọ̀ dáradára lóde ònì jẹ́ àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà àti àwọn Mọ́mọ́nì. Ẹgbẹ́ méjèèjí yìí ńgbà láti jẹ́ Kristiẹni, síbẹ̀ àwọn méjèèjì kọ̀ jálẹ̀ jíjẹ́ Ọlọ́run ti Kristi àti ìgbàlà nípa ìgbàgbọ́ nìkan ṣoṣo. Àwọn ajẹ́rìí Jèhófà àti àwọn Mọ́mọ́nì gbàgbọ́ nínú ohun púpọ̀ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú tàbí tí ó farajọ ohun tí Bíbélì ńkọ́ni. Ṣùgbọ́n, ní òtítọ́ wípé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ jíjẹ́ Ọlọ́run ti Kristi àti wí wàásù ìgbàlà kan nípa iṣẹ́ ṣíṣe wọn yẹ gẹ́gẹ́ bíi àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ajẹ́rìí Jèhófà, àwọn Mọ́mọ́nì, àti ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn míìrán jẹ́ ẹni oníwà rere tí ó gbàgbọ́ tinútinú wípé àwọn di òtítọ́ mú. Gẹ́gẹ́ bí Kristiẹni, ìrètí àti àdúrà wa gbọ́dọ̀ jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó ńbẹ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn yóò rí ìran àwọn irọ́ náà ti wọn yóò sì fà sí òtítọ́ ìgbàlà nípa ìgbàgbọ̀ nínú Jésù Kristi nìkan ṣoṣo.
English
Kínni ìtumọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn?