Ibeere
Kínni ìwò Kristiẹni nípa ayé?
Idahun
"Ìwò nípa ayé" túmọ̀ sí ìmọ̀ lẹ́kúnrẹ́rẹ́ nípa ayé láti abala kan ní pàtó. "Ìwò kristiẹni nípa ayé" nígbà náà túmọ̀ sí ìmọ̀ lẹ́kúnrẹ́rẹ́ nípa ayé láti abala kristiẹni kan ní pàtó. Ìwò ti ẹnìkan nípa ayé ni "àwòrán ńlá" rẹ̀, àkójọpọ̀ gbogbo ìgbàgbọ́ rẹ̀ nípa ayé. Ó jẹ́ ọ̀nà rẹ̀ láti ní òye nípa òtitọ́. Ìwò èníyàn nípa ayé ní ìpílẹ̀ fún ṣíṣe ìpinnu l'ójojúmọ́, nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gidigidi.
Ọ̀pọ̀ èníyàn ni ó rí èso Ápù lórí tábílì. Onímọ̀ewéko ríi Ápù yóò sì pín sí ìsọ̀rí. Ayàwòrán yóò rí ayé tí ó dákẹ́rọ́rọ́, yóò sì yàá. Oníṣòwò yóò rí dúkìa yóò sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ọmọdé yóò rí oúnjẹ ọ̀sán, yóò sì jẹẹ́. Bí a ṣe ńwo èyíkéyì ìṣẹ̀lẹ̀ dá lé lórí bí a ṣe ńwo ayé l'ápapọ̀. Gbogbo ìwo nípa ayé, kìí báà jẹ́ ti Kristiẹni àtí aláìgbàgbọ́, nííṣe pẹ̀lú ó kéré jù àwọn ìbéèrè mẹ́ta wọ̀nyìí:
1) Níbo ni àwa ti wá? (àti wípé kínni àwa ńṣe níbí?)
2) Kínni ó burú nípa ayé?
3) Báwo ni a ṣe lè ṣe àtúnṣe rẹ̀?
Ìwò ayé tí ó gbilẹ̀ jù ni naṣọnálísímù, tí ó dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta náà báyìí: 1) Àwa jẹ́ àbájáde àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kan wáyé, èyí tí kò sí ní ète kankan. 2) Àwa kò bọ̀wọ̀ fún ìṣẹ̀dá gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ. 3) A lè pa ayé mọ́ nípa ẹ̀kọ́ nǹkan nípa ìṣẹ̀dá àtí nípa kí a má ṣe pa nǹkan ìṣẹ̀dá run. Ìwo naṣọnálísímù jẹ́ atọ́nà sí àwọn èròǹgbà bíi ìhùwasí rẹletífísíìmù, ẹ̀sísítẹnsiálísímù, paragimátísímù àti utopiánísímù.
Ìwò Kristiẹni nípa ayé dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta náà ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì: 1) Àwa jẹ́ ẹ̀dá Ọlọ́run, tí á da láti ṣe ìjọba ayé, kí á sì ní ìbáṣepọ́ pẹ̀lú Rẹ̀ (Jẹnẹsisi 1:27-28;2:15). 2) Àwa ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, a sì fi gbogbo ayé sí abẹ́ ègún (Jẹnẹsisi 3). 3) Ọlọ́run tìkalára Rẹ̀ ra aráyé padà nípa ìrúbọ ọmọ Rẹ̀, Jésù Kristi (Jẹnẹsisi 3:15; Luku 19:10), ní ọjọ́ kan yóò sì dá ìṣẹ̀dá padà sí ipó pípé rẹ̀ òwúrọ̀ (Isaiah 65:17-25). Ìwò Kristiẹni nípa ayé mú wa gbàgbọ́ nínú ìhùwàsí rere/ẹ̀kọ́ ilé, iṣẹ́ ìyanu, iyì ènìyàn àti wípé ìràpadà ṣeéṣe.
Ó ṣe pàtàkì kí á rántí wípé ìwò nípa ayé jẹ́ ohun tí ó gbòòrò. Ó kó ipa nínú gbogbo abala ayé, láti owó sí ìhùwàsí, láti òṣèlú sí iṣẹ́-ọnà. Jíjẹ́ Kristiẹni tòótọ́ ju àwọn àkójọ èróńgbà èròǹgbà tí a lè lò nínú ìjọ lọ. Jíjẹ́ Kristiẹni nínú ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe kọ́ wa jẹ́ ìwò nípa ayé. Bíbélì kò fi ìyàtọ̀ sí ìgbé-ayé "ẹ̀lẹ́sìn" àti ìgbé-ayé "lásán"; ìgbé-ayé Kristiẹni nìkan ni ìgbé-ayé tí ó wà. Jésù pe ara Rẹ̀ ní "ọ̀nà, òtitọ́ àti ìyè" (Johannu 14:6), nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó di ìwò wa nípa ayé.
English
Kínni ìwò Kristiẹni nípa ayé?