settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ọkàn àti ẹ̀mí ènìyàn?

Idahun


Ọkàn àti ẹ̀mí jẹ́ abala méji pàtàkì tí kò ṣé e gbámú tí Ìwé Mímọ́ fi pe ẹ̀dá ènìyàn. Ó lè rú ènìyàn lójú láti mọ ìyàtọ̀ gbòógì tí ó wà láàrin méjèèjì. Ọ̀rọ̀ yìí, "ẹ̀mí" tọ̀ka sí abala tí kò ṣé e gbámú nípa ènìyàn nìkan. Àwọn ènìyàn ní ẹ̀mí ṣùgbọ́n wọn kìí ṣe àwọn ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, nínú Iwé Mímọ́, àwọn onígbàgbọ́ nìkan ni ó wà láàyè nínú ẹ̀mí (1 Kọrinti 2:11; Heberu 4:12; Jakọbu 2:26), nígbàtí àwọn aláìgbàgbọ́ jẹ́ òkú nínú ẹ̀mí (Efesu 2:1-5; Kolosse 2:13). Nínú àkọsílẹ̀ Pọ̀ọ́lù, nǹkan ẹ̀mí ṣe pàtàkì sí ìgbé-ayé onígbàgbọ́ (1 Kọrinti 2:14; 3:1; Efesu 1:3; 5:19; Kolosse 1:9; 3:16). Ẹ̀mí jẹ́ ìpín kan nínú ènìyàn tí ó fún wa ní agbára láti ní ìbáṣepọ̀ tímọ́ tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìgbàkúùgbà tí a bá lo ọ̀rọ̀ "ẹ̀mí", ó túmọ̀ sí abala ènìyàn tí kò ṣé e gbámú tí ó "farakínra" pẹ̀lú Ọlọ́run, tí Òun tìkalára jẹ́ Ẹ̀mí (1 Johannu 4:24).

Ọ̀rọ̀ yìí, "ọkàn" tọ̀ka sí abala ènìyàn tí kò ṣé e gbámú àti èyí tí ó ṣe gbámú. Yàtọ̀ sí wípé ènìyàn ní ẹ̀mí, ènìyàn jẹ́ ọkàn. Ní ìtumọ̀ tààrà jùlọ, "ọkàn" túmọ̀ sí "ayé". Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí ìtumọ̀ tó ṣe kókó yìí, Bíbélì sọ nípa ọkàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyọkà. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí ni ìtara ènìyàn láti dẹ́ṣẹ̀ (Luku 12:26). Ènìyàn ní ti ara rẹ̀ burú, tí ọkàn sí díbàjẹ́ nípa èyí. A yọ ìlànà ayé ọkàn kúrò nígbà ikú ara (Jẹnẹsisis 35:18; Jẹrimiah 15:2). Ọkàn àti ẹ̀mí jẹ́ ààrin ibi tí ati máa ńní ìrírí ti ẹ̀mí àti ìhùwàsí (Jobu 30:25; Orin Dafidi 43:5; Jẹrimiah13:17). Ìgbàkúùgbà tí a bá lo ọ̀rọ̀ "ọkàn" ó lè túmọ̀ sí odidi ènìyàn, bóyá ó wà láàyè tábi ní ayé tí ńbọ̀.

Ọkàn àti ẹ̀mí ní àsopọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n le pínyà (Heberu 4:12). Ọkàn ni ìdí tí ènìyàn fi wà; òun ni ẹni tí a jẹ́. Ẹ̀mí ni àgbọn ayé ènìyàn tí ó ni ìfarakínra pẹ̀lú Ọlọ́run.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ọkàn àti ẹ̀mí ènìyàn?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries